Amosun ni Ọlọrun wọn ni ipinlẹ Ogun bayii bi?

Spread the love

Ko le ya ẹnikẹni lẹnu pe wọn lawọn ko mọ ọn. Wọn ko mọ ọn naa ni wọn sọ yẹn. Ẹgbẹ APC ipinlẹ Ogun ti ni awọn ko mọ Sẹnetọ kan to ti n kiri lati ọjọ yii pe oun fẹẹ di gomina ipinlẹ Ogun, ọmọ APC si ni o. Sẹnetọ Solomon Adeọla ti wọn n pe ni Yayi ni. O ti le lọdun mẹta to ti n pariwo kiri pe oun yoo ṣe gomina Ogun lọdun to n bọ, ṣugbọn ẹgbẹ APC ni ko kọ lẹta sawọn, bẹẹ ni ko si waa ba awọn ko ṣalaye pe oun fẹẹ di gomina. Bo ba jẹ bẹẹ ni loootọ, eleyii naa ku diẹ kaato, abi nigba ti o fẹẹ ṣe inawo niwaju ile eeyan, ti o ti tẹ infiteṣan, ti o ti pe elere, ṣugbọn ti o ko sọ fun ẹni to ni iwaju-ile ti o fẹẹ lo pe nibẹ lo ti fẹẹ ṣe ayẹyẹ. Amọ bi Yayi tiẹ sọ, nnkan mi-in ti wọ ọ lọsẹ to kọja yii. Gomina Ibikunle Amosun ti kede pe obinrin lẹni ti oun fẹẹ fa kalẹ ti yoo ṣe gomina lẹyin oun. O ni obinrin ọhun ki i ṣe oloṣelu paapaa, ṣugbọn oun mọ pe o le ṣe e. Nibi ti ọrọ oṣelu Naijiria si le si niyi, gbogbo ẹni yoowu to ba ni i lọkan lati ṣe gomina Ogun lọdun to n bọ lati ọdọ awọn APC, kaluku gbọdọ fori pamọ ni, nitori ọga agba ti sọrọ. Nibi ti ọrọ oṣelu ilẹ yii ti buru niyẹn, nitori ko si ẹgbẹ oṣelu, ko si si awọn oloṣelu gidi. Bi oloṣelu gidi ba wa ni, kin ni ti Amosun lati sọ pe oun loun yoo fa eeyan kalẹ, ṣebi ẹgbẹ oṣelu rẹ ni yoo yan ẹni ti wọn ba fẹ, lẹyin ti wọn ba si ti dibo abẹle tan ni. Amọ gbogbo eeyan lo mọ pe ko si ibo kan ti wọn fẹẹ di, ẹni ti gomina yii ba sọ naa ni wọn yoo gbe e fun. Ṣugbọn Amosun ki i ṣe Ọlọrun, ko si yẹ ko maa huwa bii Ọlọrun. Ọrọ ọdun to n bọ la n sọ, kin ni gomina yii mọ ti yoo ṣẹlẹ, ta lo mọ ẹni ti yoo di ọdun to n bọ ati ibi ti kaluku wa yoo wa ninu wa. Ati pe iwa bayii n ba eto dẹmokiresi, ijọba awa-ara-wa, jẹ ni, ki i fi aaye gba awọn araalu lati fi ọwọ ara wọn mu ẹni to ba dara, to tẹ wọn lọrun, lati ṣe ijọba le wọn lori. Bi awọn eeyan ba ti wa nipo, wọn yoo ro pe ipo naa lawọn yoo wa titi laye, wọn yoo ro pe bi agbara awọn ba ti to nigba ti awọn n ṣejọba naa ni yoo to bi awọn ba kuro. Ọpọ eeyan lo ti ṣe gomina Ogun ti wọn ti lọ, njẹ Amosun paapaa le ka iye wọn. Bi awọn ti lọ yii naa loun naa yoo lọ, bo si ti ri fun awọn naa ti wọn ko le deede waa maa paṣẹ le oun Amosun lori ni yoo ri foun naa nigba to ba fi ipo silẹ. Ṣugbọn eyi to ṣe pataki ni pe ẹda ki i ṣe Ọlọrun o, ki Amosun ma sọ ara rẹ di Ọlọrun sawọn ara Ogun lọrun.

(43)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.