Amosun kilọ fun Oshiomhole lori igbimọ APC tuntun to yan nipinlẹ Ogun

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ti kilọ fun igbimọ amuṣẹṣe (National Working Committee), labẹ Adams Oshiomhole ti i ṣe alaga apapọ ẹgbẹ naa, pe ko ṣọra ẹ nipa bo ṣe n tu ẹgbẹ ka nipinlẹ naa.

Ọjọ Ẹti to kọja yii ni Amosun kilọ ọhun, nigba ti igbimọ NWC kede Oloye Yẹmi Sanusi gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣaaju ninu riri si ọrọ ẹgbẹ APC nipinlẹ Ogun, ti wọn yan Abayọmi Olubori bii akọwe, ti wọn si fi Tunde Ọladunjoye jẹ akọwe ipolongo. Awọn ọmọ ẹgbẹ tuntun yooku ni wọn ni awọn yoo maa fi wọn han laipẹ.

Igbimọ ti Oshiomhole yan yii ni yoo maa jẹ abọ bi nnkan ba ṣe n lọ si nipinlẹ Ogun fun APC, nitori alaga apapọ ẹgbe yii ti kede lọjọ Iṣẹgun ọsẹ to kọja pe ẹgbẹ Onigbaalẹ ko nigbagbọ ninu awọn eeyan Amosun ti wọn wa nibẹ, to jẹ oju ni wọn fi jẹ ọmọ ẹgbẹ APC, ero ọkan wọn ko ba ti ẹgbẹ naa mu.

Bi Amosun ṣe wa ninu ẹgbẹ APC, ṣugbọn to n tẹle Adekunle Akinlade to fẹẹ ko di gomina Ogun, to si jẹ inu ẹgbẹ APM niyẹn wa bayii, wa lara ohun ti igbimọ NWC n tori ẹ fẹsun kan Amosun. Gomina yii funra ẹ si ti sọ pe oun ko ni i ṣatilẹyin fun ondije dupo gomina ninu APC nipinlẹ yii rara, Amosun ni oun yoo tako ẹni ti wọn fa kalẹ ni.

Nigba to n ba awọn ọmọ ẹyin ẹ tinu n bi lori igbesẹ yii sọrọ nile ẹgbẹ APC l’Abẹokuta, lọjọ Ẹti yii kan naa,  Amosun ni ko si kinni kan ti yoo ṣẹlẹ si igbimọ awọn. O fi da awọn eeyan naa ti Oloye Derin Adebiyi jẹ olori wọn loju pe wọn yoo lo ọdun mẹrin wọn pe nipo alaṣe ati alaabojuto ti wọn wa. O ni apo ara Oshiomhole ati NWC ni wọn yan awọn mẹta ti wọn ṣẹṣẹ yan naa si.

Gomina Amosun sọ pe,‘Ọlọrun ni mo bẹru, ati Aarẹ Muhammadu Buhari. Bi ko ba jẹ ti Buhari ni, mo mọ awọn ohun ti mo le ṣe lori ohun to n ṣẹlẹ yii. Ṣugbọn mo fẹẹ fi da yin loju pe ko sẹni to le tu yin ka, Ọlọrun lo gbe wa kalẹ. Bi wọn ba n wa ibi ti wọn yoo bajẹ, ki wọn kọja sibomi-in, ki i ṣe ipinlẹ Ogun rara. A ti ṣetan lati koju wọn o, ibo wa la dẹ maa fi ṣe bẹẹ’’

Amosun ni gbọin-gbọin loun wa lẹyin Aarẹ Buhari, bẹẹ si ni ipinlẹ APC ni ipinlẹ Ogun, gbogbo atilẹyin lawọn n ṣe fun Buhari.

Ṣe l’Ọjọbọ to kọja yii ni ẹgbẹ APM gbe asia ẹgbẹ naa fun Akinlade ni papa iṣere MKO Abiọla to wa ni Kutọ, niluu Abẹokuta.

Bo si tilẹ jẹ pe Amosun ko wa sibẹ loootọ, ẹnikan wa nibẹ to mura bii gomina yii, to tun n sọrọ bii Amosun, to si n fontẹ lu Buhari ati Akinlade, to fi da gbogbo aye loju pe tiwọn loun n ṣe.

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.