Amosun kilọ fawọn agunbanirọ nitori idibo ọdun to n bọ

Spread the love

Nitori eto idibo ọdun to n bọ, Gomina ipinlẹ Ogun, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, ti kilọ fawọn agunbanirọ to n sinru ilu nipinlẹ naa lati ma ṣe jẹ kawọn oloṣelu lo wọn fun magomago lasiko idibo naa.

Amosun ti kọmiṣanna fun ọrọ awọn ọdọ ati ere idaraya nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Afọlabi Afuapẹ, ṣoju fun, sọrọ yii nibi eto idanilẹkọọ ọlọsẹ mẹta ti wọn maa n ṣe fawọn agunbanirọ tuntun. Ọjọbọ, ọgbọnjọ, oṣu kẹjọ, lamọran yii waye fawọn iṣi keji akẹkọọ-gboye naa ti wọn ṣẹṣẹ de si agọ awọn agunbanirọ to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun.

Nigba to fi n da wọn loju pe awọn agunbanirọ lẹtọọ lati ṣatilẹyin fun ondije dupo to ba wu wọn, gomina gba wọn nimọran lati ṣiṣẹ pẹlu otitọ lawọn ibudo idibo ti wọn ba pin wọn si, nitori ṣiṣe bẹẹ lo dara fun dẹmokiresi, ijọba tiwa-n-tiwa.

Ninu ọrọ alaabojuto eto isinru ilu naa nipinlẹ Ogun, Abilekọ Josephine Bakare, o rọ awọn ọdọ to ṣẹṣẹ kẹkọọ gboye naa pe ki wọn maa ranti pe oju lalakan fi n ṣọri.

O ni loootọ leto aabo to peye wa fun wọn, to si jẹ pe ajọṣepọ INEC pẹlu ajọ NYSC gunrege, ṣugbọn awọn agunbanirọ naa gbọdọ maa ranti pe aabo ara wọn ṣe pataki, iyẹn ni wọn ko ṣe gbọdo faaye silẹ ki oloṣelu kan lo wọn fun jagidijagan tabi madaru lasiko ibo.

Abilekọ Bakare ni kawọn obi awọn ọmọ naa ma ṣe bẹru bi wọn ba pin wọn sibudo idibo, nitori aabo to peye wa fun wọn. Ni gbogbo ibi ti wọn ba n lọ lawọn ẹṣọ alaabo yoo maa ṣọ wọn lasiko ibo ati lẹyin ẹ pẹlu.

O ni kawọn obi fọkanbalẹ, adura ni ki wọn maa se fawọn ọmọ naa ati fun orilẹ-ede Naijiria lapapọ.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.