Amọ ẹ ṣọra ṣọra fawọn ọmọ Saraki ṣaa o

Spread the love

Awọn kan mọ, ṣugbọn awọn kan ko mọ. Wọn ko mọ pe Bukọla Saraki ko ni iwa kan to n da hu lọtọ bi ko jẹ ohun ti Baba rẹ n hu niwa loju rẹ. Baba Oloye Abubakar Oluṣọla Saraki naa ko ṣe oṣelu kan to fi bẹẹ yatọ si ti Bukọla yii, ọwọ rẹ ni ọmọ rẹ si ti kọ ọpọlọpọ ohun to ṣe. Ka da irẹsi kongo kan si meji, ka ko o sinu agolo, ka fi aṣọ ankara oni-ẹgbẹrun kan-Naira gba a lẹgbẹẹ, ka si fi ororo ati owo bii ọgọrun-un kan Naira le e, ka waa ṣeto ki gbogbo ero pe siwaju ile, ka maa ya fọto wọn, ka si maa gbe ohun ti wọn fẹẹ gba fun wọn. Iṣẹ ti Saraki agba fi gbayi ni gbogbo Kwara niyẹn. A sọ nigba naa ni bii ọdun 2002, nigba ti Saraki fi dandan le e pe oun yoo le Lawal lọ, ti Lai Muhammed yii naa fẹẹ du ipo gomina, awa sọ nigba naa pe oore kin ni Saraki agba ṣe fun wọn ni Kwara, a beere lọwọ rẹ. A fẹẹ mọ ọsibitu to ni si Kwara nigba to ṣe pe dokita alabẹrẹ ni, a fẹẹ mọ iru iṣe ijọba nla to gbe wa si Kwara nigba to jẹ oun naa lagbara ninu awọn ti wọn ṣejọba apapọ. Ṣugbọn wọn ko ri esi kan mu wa nigba naa, afi eebu ati ibẹru lati ọdọ awọn ti wọn ti ri Saraki agba yii gẹgẹ bii Ọlọrun wọn. Oun naa lo delẹ yii. Baba ku, o fi iṣẹ silẹ fun ọmọ rẹ, ọmọ naa si lo agbara ijọba ati owo ilu lati fi ko ọpọlọpọ ọrọ jọ fun ara rẹ ati fun awọn ọmọ tirẹ nikan. O ṣe bẹẹ fun ọdun mẹrindinlogun ki awọn Kwara too gbọn mọ ọn lọwọ. Bẹẹ baba tirẹ ṣe kinni naa fun odidi ọdun mẹrinlelogun ki Bukọla yii too de rara. Ni bayii ti nnkan fẹẹ yatọ, ki ọmọ Kwara ṣọra wọn lọdọ iran Saraki ni. Bi a ba ni a le Bukọla lọ, ṣebi Gbemi naa ree, afi ka moju lelẹ, ka ri i pe iwa ti Gbemi yii ko jọ ti ẹgbọn rẹ ati ti baba wọn nidii oṣelu, nitori bi iwa wọn ba jọra pẹnrẹn, a jẹ pe olokun-un-run kan lo ku, la ba tun mu olokun-un-run mi-in joye, ta ni ko mọ pe ariwo ṣi ku nile wa lẹẹkan si i!

(37)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.