Ambọde naa ti ri i pe ko lọ titi, ọrọ ile aye yii ni

Spread the love

Bi eeyan ba ri Gomina Eko yii, Akinwumi Ambọde, bo ṣe so mọ Minisita eto iṣẹ ode ati ọrọ ile gbigbe, Babatunde Raji Faṣọla, nigba ti wọn pade ni Abuja nibi ipade ẹgbẹ oloṣelu APC, oluwa-rẹ yoo mọ pe ibi ti ọbẹ ti ba gomina yii lara le gan-an ni. Niṣe lo so mọ Faṣọla, bo si ṣe so mọ ọn naa da bii igba ti eeyan ba ni, “mo ti ṣẹ, ẹ ṣa foriji mi!” Bo ba jẹ nigba ti aye wa lọwọ ọkunrin gomina yii ni, tabi to ba jẹ bi wọn ti dibo yii ni wọn ti tun fa a kalẹ, to si ri i pe ko sẹnikan to tun le da oun duro mọ, bi yoo ba tilẹ ki Faṣọla, yoo kan bọ ọ lọwọ lasan ni, nitori gbogbo ọna ni gomina yii ti wa lati ọjọ yii lati fihan Faṣọla pe ko ju oun lọ, oun ko si bẹru rẹ tabi ni ọwọ kan fun un, bo ba jẹ gomina ri, tabi to ba jẹ minisita, iyẹn si apo ara ẹ ni, ko si eyi to kan oun. Tabi ẹni meloo ni yoo ti sare gbagbe ohun ti Ambọde yii ṣe fun Faṣọla, to jẹ nigba to di gomina, gbogbo ohun ti iyẹn ṣe kalẹ lo kọkọ mura lati da ṣubu, to si n yọ awọn eeyan ti Faṣọla gba siṣẹ danu bii ẹni pe ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa lawọn mejeeji. Awọn yẹn kọkọ ro pe nitori Tinubu lo ṣe n ṣe bẹẹ ni, wọn ko mọ pe iwa ẹ ni, ipo to wa naa jọ ọ loju debii pe ko ni ọwọ tabi apọnle fawọn to ba niwaju rara. Boya ohun to ṣe dara, tabi ko dara, oun naa ti foju ara rẹ ri i bayii, gbogbo iwa rẹ yoo si ti maa ja a ninu jẹ. Nigba to ri Faṣọla to so mọ ọn yii, bii ẹni to n bẹ ẹ pe ‘Faṣọla gba mi ni.’ Oun naa ti ri i pe aye yii ko lọ titi. Ko si ipo ti ẹda wa to lọ titi, bi a ba gungi, dandan ni ki a sọ kale, ko sẹni ti yoo maa gbe ori igi. Bi ọrọ aye ti ri ree, ẹni to ba ni oni kọ ni yoo ni ọla, awọn mi-in ni wọn yoo si ni ọtunla. Ọrọ ile aye yii niyẹn o, igba kan ko lọ titi!

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.