Ambọde, ma dan an wo!

Spread the love

Ijọba ipinlẹ Eko gbe ikede kan jade lọsẹ to kọja yii, ikede naa ni pe awọn yoo maa sanwo fun awọn pasitọ ati awọn lemọmu kan, nitori iṣẹ ti wọn fẹẹ maa ba awọn ṣe. Akọkọ ni pe iṣẹ wo ni wọn fẹẹ maa ba wọn ṣe o. Gẹgẹ bi kọmiṣanna fun ọrọ abẹle ṣe sọ, iṣẹ ti wọn fẹẹ gbe fun awọn pasitọ ati lemọmu yii ni lati maa ba awọn ọmọ ijọ wọn sọrọ, ki wọn le mọ ohun to yẹ ki wọn ṣe laarin ilu ati awọn ohun ti ko yẹ ki wọn ṣe. Iṣẹ naa ko ju bẹẹ lọ. Afi to ba ṣe pe iṣẹ mi-in tun wa ti kọmiṣanna yii ko sọ fun wa nikan ni o, to ba jẹ iṣẹ to sọrọ rẹ loke yii ni, pe ki pasitọ abi lemọmu kan ṣe waasi, tabi waasu fun awọn ọmọ ẹyin rẹ lati ṣe ohun ti ijọba ba fẹ, eleyii ki i ṣe ohun ti ijọba kan gbọdọ sanwo ẹ, nitori ojuṣe ẹni to ba pe ara rẹ ni pasitọ tabi to pe ara rẹ ni lemọmu ni. Ohun ti awọn ijọ ti tọhun ba wa n sanwo le lori niyẹn, nitori pasitọ ni owo oṣu to n gba lọwọ ijọ, awọn lemọmu mi-in naa si ni owo oṣu tiwọn. Ati pe ko si ohun meji to mu ẹsin dara ju ki olori ẹsin ma wa labẹ ijọba tabi labẹ oloṣelu kan lọ. Bi ijọba Ambọde ba bẹrẹ si i sanwo fun awọn pasitọ latari pe wọn fẹ ki wọn sọrọ fawọn eeyan wọn, iyẹn ni pe ohun ti ijọba ba fẹ nikan ni wọn yoo maa sọ jade, ọrọ ti ko ba tẹ ijọba lọrun, bo tilẹ jẹ pe ọrọ naa yoo pa araalu lara, awọn pasitọ ati lemọmu ti wọn n gbowo yii o gbọdọ maa sọ ọ niyẹn. Bi ijọba ba n huwa ibajẹ, awọn pasitọ ti wọn n gbowo yii ko ni i le sọ ọ mọ, bẹẹ ni awọn lemọmu yoo maa ṣe ẹnu kọlọkọlọ lati ba ijọba sọ ododo. Ki ijọba fi wọn silẹ ki wọn ma fun wọn lowo kan o, ki wọn jẹ ki wọn ṣe iṣẹ wọn. Lọna keji, nigba ti Ambọde ba fi eleyii bẹrẹ ni kekere bayii, ko le mọ igba ti awọn ijọba mi-in yoo sọ kinni naa di iṣẹ, ti wọn yoo maa sanwo fun gbogbo ẹni to ba pe ara rẹ ni lemọmu ati pasitọ, ti eyi yoo si tun di inawo ọran mi-in fun ijọba. Ọrọ yoo tilẹ le nigba to ba ya, kinni ọhun si le di ija ẹsin, nigba ti awọn kan ba ni lemọmu lo pọ ju pasitọ lọ to n gbowo lọwọ ijọba, tabi pe pasitọ lo pọ ju lemọmu lọ. Naijiria ati eto oṣelu wa nibi ko faaye gba ohun ti Akinwumi Ambọde fẹẹ ṣe yii rara, ko yaa ma dan an wo, ohun to lewu ni.

(119)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.