Ambọde gba fun ọga ẹ: O ni ki loun fẹẹ sọ loju Jagaban

Spread the love

Lanaa, ọjọ Mọnde, ni Gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambọde, sọrọ nipa bi agbara Aṣiwaju ẹgbẹ APC, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ti to ninu ọrọ oṣelu nilẹ yii. Nibi ikojade iwe “Africa Arise and Shine” ti alaga ile-ifowopamọ Zenith Bank Plc, Jim Ovia, kọ lo ti sọrọ yii.
Bi ẹyin eeyan ba n fi ọkan ba ọrọ gomina Eko lọ, laipẹ yii ni wọn kede pe ikunsinu wa laarin oun ati baba isalẹ rẹ nidii oṣelu yii, ọjọ Mọnde si ni yoo jẹ igba akọkọ ti awọn mejeeji yoo tun pade loju gbogbo aye latigba ti iroyin naa ti jade.
Nigba ti wọn pe gomina naa pe ko waa sọrọ lẹyin ti Tinubu ti sọrọ, o ni “Kin ni mo ni lẹnu lati sọ lẹyin ti Jagaban funra rẹ ti sọrọ.”
Eyi to tun pa awọn eeyan lẹrin ni bi Ambọde ṣe dide lori aga ti wọn ṣe fun un gẹgẹ bii Gomina, to si lọọ jokoo ti Tinubu laaye ti wọn ṣe lọjọ fun un. Ọpọ lo ka ọrọ naa sẹrin amọ awọn ti wọn mọ bi nnkan ṣe n lọ lagbo oṣelu ipinlẹ Eko mọ pe ki i ṣe ọrọ awada, Ambọde dọgbọn gba fun ọga ẹ ni.

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.