Ambọde, aṣe bẹ ẹ ṣe n ṣe e ree!

Spread the love

Ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ Eko laarin Aṣiwaju Bọla Tinubu ati Gomina Akinwunmi Ambọde ti fihan daadaa bayii pe ki i ṣe pe ọbọ ni ọgbọn kan taara to fi n dara lori igi ju pe igi sun mọ ara wọn lọ, bi ọbọ ba lọ sibi ti igi ti jinna si ara awọn, ko ni i saaye ara dida kan. Ki i ṣe pe Gomina Ambọde ni ero kankan lẹyin, tabi pe o lagbara kan tabi imọ oṣelu kan ki wọn too ni ko waa ṣe gomina, wọn fa a kalẹ ni, oun naa si gun ori aga ti wọn gbe e le. Igba ti awọn aṣaaju rẹ ti wọn gbe e de ori aga yii ko ri ohun ti wọn ro pe wọn yoo ri lati ara rẹ, boya nipa iwa tabi iṣẹ, ni wọn sọ pe ko kuro nibẹ bayii, iyẹn lo si di ohun to n gbe e sa kiri. Ohun ti eyi fihan ni pe oko ailaju, ilu ailaju ni awọn ọmọ Naijiria wa, paapaa awa eeyan ti a n ro pe a lọgbọn kan lori nilẹ Yoruba nibi. Ẹni kan ni yoo jokoo sibi kan ti yoo paṣẹ ẹni ti yoo ṣejọba le wa lori, bo ba waa ya, a o ni tọhun ko ṣejọba daadaa, tabi pe ko tilẹ mọ bi wọn ti n ṣejọba. Ṣe awa la yan an sipo ni! Ṣebi, “Baba sọ pe” la tẹle, ohun ti wọn ni ka ṣe la ṣe, ẹni ti wọn ni ka dibo fun la dibo fun, bẹẹ ki i ṣe pe a mọ iwa onitọhun, tabi ọgbọn ori rẹ, boya ẹni ti ori rẹ tilẹ pe ni tabi omugọ ati ọmuti paraku kan ni. A ko ni i mọ eeyan, a o maa dibo fun un, bi wọn ba ti fun wa ni tọrọ-kọbọ, owo ti ko ju ka fi jẹun ọjọ kan, ti a oo si tori rẹ padanu ọdun mẹrin to yẹ ka fi ṣoriire.

Ni ilu to ti laju, awọn eeyan ki i dibo nitori pe baba kan jokoo sibi kan o ni ẹni kan ni ki wọn dibo fun. Wọn yoo dibo nitori wọn mọ ẹni ti wọn fẹẹ dibo wọn fun, wọn si mọ pe o le ṣe ohun ti awọn fẹ fun idagbasoke adugbo tabi ipinlẹ wọn ni. Ohun to n pa wa ku niyẹn, awọn eeyan bii Aṣiwaju Tinubu ni wọn si pọ ni Naijiria, awọn ni wọn yoo sọ ẹni ti awọn eeyan yoo dibo fun, bi tọhun ko ba si huwa to tẹ wọn lọrun, awọn naa ni wọn yoo yọ ọ kuro, ko si ohun ti araalu kan le ṣe si i. Bo ba jẹ ọna ti a n tọ niyi, idagbasoke kan ko le to wa lọwọ, nitori kaka ki oloṣelu to ba wa nipo bẹru awọn araalu, ko bẹru pe wọn le fi ibo yọ oun kuro, aṣaaju rẹ to fa a kalẹ ni yoo maa bẹru, koda ko jẹ iwa rẹ yoo maa pa araalu lara. Ọjo ti a ba jawọ ninu iwa omugọ bayii ni nnkan wa yoo bẹrẹ si i dara. Ẹni to ba fẹẹ dibo ko jade, ko si darukọ ara rẹ, ko si sọ ohun to ti gbe ṣe laye rẹ ri, iyẹn lara ilu gbọdọ wo lati dibo fun un, ki i ṣe nitori pe baba kan sọ pe lamọrin ni ki wọn dibo fun. Bi Ambọde ba mọ pe oun to gomina i ṣe, ko yee sare kiri, ko yee dọbalẹ kiri, ko si sinmi a n sunkun, ko jade si gbangba nibi ibo abẹle ẹgbẹ rẹ, bo ba gbajumọ laarin wọn, yoo wọle, bi ko ba si gbajumọ, wọn yoo gbe ẹlomiiran le e lori. Bo ba si ri i pe gbajumọ oun pọ laarin ilu, Aṣiwaju lo fẹẹ ja irawọ oun lulẹ, ọran kọ, ko wọ inu ẹgbẹ mi-in, ko si fihan Aṣiwaju paapaa pe oun lero toun lẹyin, kẹni kan ma halẹ mọ oun. Bi wọn ti n ṣe oṣelu niyẹn, ẹni ti ko ba ti le bọ si gbangba du ipo kan ko yẹ lẹni ti araalu gbọdọ gbe agbara ijọba le lọwọ, nitori bi oun naa ba debẹ, iṣekuṣe ni wọn yoo maa ṣe. Ambọde, yee sare kiri mọ, dojukọ awọn araalu, ko o le mọ bi wọn fẹran rẹ bi wọn o fẹran rẹ.

(80)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.