Amarachukwu to lu aṣofin ni jibiti ti dero kootu

Spread the love

Nitori bo ṣe lu ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin to n ṣoju Idah, ipinlẹ Kogi, Emmanuel Egwu, ni jibiti, awọn ọlọpaa ti wọ ọmọbinrin kan, Amarachukwu Chineke, ẹni ọdun mẹtadinlogoji, lọ si kootu majisreeti to wa ni Igboṣere, niluu Eko.

Ajọ Akoroyinjọ Naijiria (NAN) , jabọ pe ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni wọn foju Amarachukwu ba kootu, ẹsun mẹta to ni i ṣe pẹlu igbimọ-pọ huwa ọdaran, pipurọ gbowo ati ole jija ni wọn fi kan an.

Sajẹnti Friday Mameh to ṣoju ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe olujẹjọ naa ati awọn mẹta mi-in ti wọn ti sa lọ bayii huwa naa lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, laduugbo Abraham Adesanya, to wa ni Lekki, niluu Eko.

O ni ṣe ni ọmọbinrin naa ni oun le ṣẹ ẹgbẹrun mọkandinlaaadọta owo Dọla (49,800), si Naira, eyi ti iye rẹ yoo fi jẹ miliọnu mẹẹẹdogun o le diẹ Naira (N15, 438,000), ṣugbọn ṣe ni wọn ko mu ileri naa ṣẹ, ti wọn si lu ọkunrin yii ni jibiti. Ẹsun naa lo ni o tako abala meji ninu awọn iwe ofin to de iwa ọdaran ti ipinlẹ Eko n ṣamulo rẹ.

Olujẹjọ ni oun ko jẹbi ẹsun naa. Adajọ Fọlashade Botoku, faaye beeli silẹ fun un pẹlu miliọnu meji Naira ati oniduuro meji niye kan naa. O ni awọn oniduuro mejeeji gbọdọ ṣafihan iwe-ẹri owo-ori ti wọn n san si apo ijọba ipinlẹ Eko.

Ọjọ kẹwaa, oṣu to n bọ lo sun igbẹjọ mi-in si.

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.