Alukoro ẹgbẹ APC tẹlẹ, Bọlaji Abdullahi, fẹẹ dupo gomina ni Kwara

Spread the love

Labẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP ni Alukoro apapọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), tẹlẹ, Mallam Bọlaji Abdullahi, ti loun yoo dije dupo gomina ipinlẹ Kwara ninu eto idibo ọdun 2019.

Bo tilẹ jẹ pe ko tii kede erongba rẹ sita, ṣugbọn a ri i gbọ pe Abdullahi wa lara awọn to maa dije. Igbagbọ awọn eeyan si ni pe o ṣeeṣe ki tikẹẹti ẹgbẹ PDP naa ja mọ ọn lọwọ nitori bo ṣe sunmọ Bukọla Saraki to jẹ adari ẹgbẹ oṣelu naa nipinlẹ Kwara.

Ṣe lọsẹ to kọja ni Saraki sọ pe oun ko ni oludije kankan lọkan lati fa silẹ. Ṣugbọn iroyin to gba ilu naa kan nipe o ṣeeṣe ko jẹ pe Abdullahi lo maa rọpo Gomina Abdulfatah Ahmed lọdun 2019.

Ọkunrin naa ti figba kan jẹ minisita feto idaraya labẹ ijọba aarẹ ana, Goodluck Jonathan, laipẹ yii lo si tun pada lọọ darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, lẹyin to kọwe fi ipo alukoro to di mu ninu ẹgbẹ oṣelu APC silẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu kẹjọ, ọdun yii.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.