All-Afrika Games: Eyi lawọn mejidinlogun ti yoo ṣoju Naijiria

Spread the love

Kooṣi ikọ Flying Eagles ilẹ Naijiria, Paul Aigbogun, ti kede orukọ awọn ti yoo ṣoju Naijiria nibi idije All-Africa Games ti yoo waye lọjọ kọkandinlogun si ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu yii nilẹ Morocco.

Nibẹ ni Naijiria yoo ti kọkọ figagbaga pẹlu Morocco, South Afrika ati Burkina Faso ni Ipele A. Idije tọdun yii ni ẹlẹẹkejila iru ẹ, ọdun 1965 si lo bẹrẹ.

Awọn ere idaraya to le ni ọgbọn lawọn orilẹ-ede ti n kopa, Naijiria si ni orilẹ-ede keji to gba ami-ẹyẹ ju ninu itan idije naa lẹyin Egypt.

Eyi lawọn ti yoo kopa fun Flying Eagles nibi idije tọdun yii ati kilọọbu ti wọn wa:

Amule: Ogundare Detan (Kogi United), Yakubu Matthew (Clique Sports).

Ẹyin: Sadiq HabibuYakubu (Rara FC), Mike Zaruma (Plateau United), Ogberahwe Solomon Onome (El Kanemi Warriors), Rabiu Zulkifilu Muhammad (Plateau United).

Aarin: Victor Arikpo (Sidos FC), Sanusi Abdulmutallif (KatsinaUnited), Ọladoye Adewale (Water FC), LiameedQuadri (36 Lion FC), Peter Eletu (Prince Kazeem Academy) Samuel Nnoshiri (Heartland FC).

Iwaju: Jibril Saeed (Plateau United), Makanjuọla Success (Water FC), Emeka Chinonso (Club Brook FC/ENG), SorYira Collins (Oasis FC), Abubakar Ibrahim (Plateau United), Ahmad AbubakarGhali (MFM FC).

(1)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.