Alaga SUBEB tẹlẹ fẹẹ dupo gomina lẹgbẹ PDP

Spread the love

Alaga eto ẹkọ jale-jako, SUBEB, nipinlẹ Kwara tẹlẹ, Alhaji Ladi Hassan, ti darapọ mọ awọn to fifẹ han lati dupo gomina ipinlẹ Kwara ninu eto idibo ọdun 2019.

Hassan rọ awọn araalu lati lọọ gba kaadi idibo alalopẹ wọn nitori pe eleyii nikan lo le mu wọn ṣe ojuṣe wọn gẹgẹ bii ọmọ orileede yii lasiko idibo.

Hassan to jẹ olori awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina lasiko iṣejọba Dokita Bukọla Saraki sọ pe abẹ asia ẹgbẹ oṣelu PDP loun yoo ti dije-dupo.

O ni kaadi idibo nikan lo le mu ki awọn araalu yan awọn adari rere ti wọn nifẹẹ si.

O ni erongba oun ni lati mu idari rere ati awọn eto ti yoo ṣe awọn araalu lanfaani wọ ipinlẹ Kwara.

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.