Alaga ijọba ibilẹ Atisbo pada sinu ẹgbẹ APC

Spread the love

Alaga ijọba ibilẹ Atisbo, nipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Onarebu Jacob Ogunmọla, ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu APC lọsẹ to kọja.
Nibi ipolongo ita gbangba ẹgbẹ naa to waye niluu Agunrege, nijọba ibilẹ Atisbo, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja lo ti kede pe oun ko ti i kuro ninu ẹgbẹ APC, ọmọ ẹgbẹ naa ṣi loun. O ni ẹsẹ oun ko yẹ ninu ẹgbẹ naa, paapaa lasiko eto idibo to n bọ lọna yii, erongba oun si ni ki ẹgbẹ yii jawe olubori ni gbogbo ẹka. Lara awọn ọmọ ẹgbẹ alatako to darapọ mọ ẹgbẹ APC lọjọ naa ni ọnarebu to n ṣoju ijọba ibilẹ ATISBO ati Ila-Oorun Ṣaki nileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ayọbami Ojo, atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu ADC ati ZLP.

Lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ, Ayọbami Ojo sọ pe ẹgbẹ oṣelu APC lọna abayọ si iṣoro awọn eeyan, nitori oun ti dan ile ọkọ meji ninu oṣelu wo.

O waa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ti wọn ti yanjẹ, ti inu ṣi n bi latari nnkan to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ naa lati waa darapọ mọ APC.

 

(4)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.