Alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro wọ wahala nla, ẹsun ikowojẹ ni wọn fi kan an

Spread the love

Ajọ to n gbogun ti iwa ibajẹ nidii owo nina (EFCC), ti wọ Alaga ẹgbẹ awọn agbẹjọro lorileede yii, Paul Usoro (SAN), lọ si kootu lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja.

Atẹjade ti ajọ naa fi sita fidi ẹ mulẹ pe iwaju Onidaajọ M.S Hassan, ti ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa ni Ikoyi, niluu Eko, ni wọn wọ Paul lọ. Ẹsun mẹwaa ọtọọtọ ni wọn fi kan agba lọọya naa, eyi to da lori ṣiṣe biliọnu kan o le diẹ Naira (N1,410,000,000,000.00), mọku-mọku.

Bo tilẹ jẹ pe ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹwaa, oṣu yii, lo ti yẹ ki Paul  farahan niwaju adajọ, ṣugbọn eyi ko ṣee ṣe nitori ajọ naa ko ri i fun niwee ipẹjọ.

Agbẹjọro EFCC, Rotimi Oyedepo, sọ fun adajọ pe awọn oluwadii ajọ ọhun ko ri iwe ipẹjọ fun olujẹjọ naa, nitori ọkunrin naa sọ pe ilu oyinbo loun wa lọjọ ti awọn oṣiṣẹ ajọ naa wa a lọ.

Ẹni to n gbẹnusọ fun Paul, Wọle Ọlanipẹkun (SAN), sọ pe ojuṣe EFCC ni lati fun onibaara oun niwee ipẹjọ, o fi kun un pe aarẹ ẹgbẹ awọn agbẹjọro lonibaara oun, ko si raaye lati maa paara ọfiisi ajọ naa lojoojumọ. O waa rọ kootu lati paṣẹ fun agbẹnusọ ajọ yii lati fun onibaara oun niwee ipẹjọ lọna to tọ, ati lọna to yẹ.

Onidaajọ Hassan faaye beeli silẹ fun Paul pẹlu miliọnu lọna igba o le aadọta Naira ati oniduuro kan niye kan naa lẹyin to gbọ awijare awọn igun mejeeji.

O ni oniduuro naa gbọdọ wa nipo dirẹkitọ nileeṣẹ ijọba apapọ tabi ti ijọba ipinlẹ Eko. Bakan naa lo ni ki ọkunrin naa yoo fi iwe-irinna rẹ silẹ nile-ẹjọ. Ọjọ karun-un, oṣu keji, lo sun igbẹjọ rẹ si.

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.