Alaafin pẹlu awọn ọmọ rẹ

Spread the love

Awọn ọmọ Alaafin Ọyọ meji ni wọn yoo du ipo kan naa lasiko ibo to n bọ yii o. Ọkan yoo du ipo naa lati inu ẹgbẹ APC, ekeji yoo si du u lati inu ẹgbẹ PDP. Hakeem Adeyẹmi to fẹẹ du ipo naa lati inu APC ti wa nile-igbimọ aṣofin tẹlẹ, ibẹ naa lo si wa titi di bi a ṣe n sọrọ yii. Oun ni aṣoju ijọba ibilẹ Afijio/Ọyọ East/Ọyọ West, agbegbe to ko gbogbo ilu Ọyọ patapata. Ohun ti eleyii tumọ si ni pe bo ba jẹ APC lo wọle, bo si jẹ PDP naa ni, ọmọ Alaafin naa ni. Loootọ ko si ohun to buru ninu eyi bẹẹ ni ofin ko si sọ pe ọmọ baba kan naa ko le du ipo kan naa. Ṣugbọn ọba ni Alaafin, baba gbogbo Ọyọ ni, bi ọmọ rẹ kan ko du ipo oṣelu, agbara to wa lọwọ wọn to lọtọ.
Ṣugbọn bi ọmọ kan ba du ipo naa lati inu ẹgbẹ oṣelu kan, ohun to dara ju ni ki awọn idile Alaafin gba ẹlomiiran laaye lati idile mi-in ni ilu Ọyọ ki wọn du ipo naa lati koju ọmọ Alaafin. Fun pe ọmọ Alaafin ni yoo ṣoju ẹgbẹ nla mejeeji ta a ni nilẹ yii lati du ipo ẹni ti yoo ṣe aṣoju Ọyọ ati agbegbe rẹ nile-igbimọ ijọba apapọ ki i ṣe ohun to ṣee maa mu yangan ninu ọrọ sisọ nipa ọba wa. Bawo ni Alaafin paapaa ṣe fẹ ki inu awọn ọmọ Ọyọ dun to, ṣe wọn yoo sọ pe daadaa lo n ṣe fawọn ni abi aburu, nigba ti oun ko awọn ọmọ tirẹ meji siwaju pe ki wọn lọọ maa du ipo oṣelu, ti awọn ọmọ ọmọwe ati araalu mi-in si wa nibẹ ti wọn ko jẹ ki wọn gbiyanju laaye ara wọn, gbogbo eeyan lo si mọ pe owo ni wọn n ko jẹ nile-igbimọ naa, ki i ṣe iṣẹ gidi kan lawọn oloṣelu ilẹ yii n ṣe fun wa. Nibi ti ounjẹ ba ti waa wa bẹẹ, ẹtọ ni fun ọba nla yii lati fun awọn araalu rẹ naa laaye lati kopa, ko si ẹni ti yoo gba pe ko lọwọ si eleyii, tabi pe awọn ọmọ ti wọn n du ipo naa ti dagba lati ṣe eyi to ba wu wọn, bi Alaafin ba sọ pe ki ọmọ rẹ kan jokoo ko ma koju ekeji, ọmọ naa ko ni i gbo baba rẹ lẹnu. Ṣugbọn o ti dohun bayii, ọmọ Alaafin meji ni yoo koju ara wọn, ọkan ni PDP, ekeji ni APC, ohun ti ko daa ko daa o jare.

(46)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.