Alaafin Oyo 5

Spread the love

Ohun ti awọn ijọba Naijiria labẹ Ọgagun Agba Yakubu Gowon sọ fun gbogbo aye ni pe ko si bi Emeka Ojukwu to n ṣe olori ogun awọn ọmọ Biafra ṣe le gbọn to, awọn yoo mu un laarin oṣu diẹ pere ni, ṣugbọn nigba ti ogun naa fẹju tan lo han si wọn pe Ojukwu ko ṣee mu bẹẹ, ati pe ọrọ ogun ki i ṣe nnkan ti eeyan n fẹnu lasan sọ. Ni 1968 ti wahala ọrọ Alaafin Ọyọ bẹrẹ yii, ogun abẹle yii ti di ọdun kan, asiko ti Gomina Adeyinka Adebayọ si paṣẹ lo pe ọdun kan geere ti awọn ṣọja ti n yinbọn sira wọn nilẹ Ibo, iyẹn ni pe ọrọ ogun naa ki i ṣe ohun ti ẹni kan le sọ pe igba bayii ni yoo pari. Nigba ti ijọba Western Region waa paṣẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ sọrọ oye Alaafin Ọyọ mọ titi ti wọn yoo fi jagun naa tan yii, ọrọ to ko gbogbo araalu Ọyọ ati ilẹ Yoruba lapapọ lọkan soke ni. Ki lo kan Alaafin Ọyọ pẹlu ogun abẹle ti wọn n ja nilẹ Ibo, ki lo de ti ijọba West n ṣe bayii, ohun tawọn eeyan n beere niyẹn.
Ṣugbọn ko si ohun ti ẹnikẹni le ṣe si i, ijọba ti paṣẹ, wọn ti paṣẹ naa niyẹn, ẹni ti ko ba dun mọ ko wa nnkan mi-in ṣe ni. Awọn eeyan ti fọkan si i pe o pẹ, o ya ni, ogun abẹle naa yoo fori ti sibi kan. Ṣugbọn ọrọ ija oye Alaafin naa ko sinmi bẹẹ, koda, ko sinmi lọdọ ijọba funra rẹ. Awọn ẹbi funra wọn o sinmi, nitori nigba ti wọn ti ri i pe ọrọ da bayii, ti ọrọ ti fọnka pata, oriṣiiriṣii eeyan lo bẹrẹ si i kọwe, wọn n kọwe sijọba pe awọn naa le du ipo Alaafin Ọyọ, ko si ohun ti o le sọ pe ki awọn ma du ipo naa, nigba ti ija ti de laarin awọn ọmọ Alowolodu ti ọrọ oye naa kan, ti awọn kan ti ni awọn ko fẹ Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi, ti awọn mi-in si ni ki i ṣe loju awọn ni Sanda Ọladepo Ọranlọla Adeyẹmi yoo joye, ti ko si sẹlomi-in to tun yanju, awọn ọmọ ẹbi mi-in bẹrẹ si i jade, wọn ni ki wọn ma jẹ ki wọn fi ọpa pọọlọpọọlọ pa ọpọlọ, ki wọn forukọ awọn naa si i ki awọn joye, ko sẹni ti ko le jẹ Alaafin ninu awọn.
Ọrọ naa le nigba kan debii pe niṣe ni ẹni to jẹ olori ilu Ọyọ nigba naa, Baṣọrun Tijani Eesuọla Akano pariwo sita, to ni ki ẹnikẹni ma kọwe kan si oun mọ, bẹẹ ni oun ko ni i gba enikẹni laaye lati yẹ iwe kankan ti lara awọn ẹbi ọba ni ilu Ọyọ ba tun kọ soun lori ọrọ Alaafin. Ohun to jẹ ko sọrọ yii ni pe ọrọ naa ti su oun atawọn Ọyọmesi paapaa, o si ti su ijọba. Ijọba Western State ti ro pe bi awọn ti ṣe ofin yii, awọn Ọyọmesi ati agbaagba Ọyọ yoo pada waa bẹ awọn pe ki awọn kuku fi Ladepo Ọranlọla ti awọn fẹ lọba jọba, ki wọn si gbagbe ọrọ Lamidi Ọlayiwọla. Wọn ti ro pe ọrọ naa ko le pẹ rara ti yoo fi yanju, wọn ni ohun ti yoo ṣe awọn Ọyọmesi lapapọ lanfaani lawọn ti ṣe yẹn. Wọn ni nigba ti ko ba si Alaafin l’Ọyọọ, ko ni i pẹ ti awọn ọmọ Ọyọ yoo fi bẹrẹ si i ba awọn afọbajẹ naa ja, nigba ti wọn ba si fẹẹ fi wahala pa wọn, wọn yoo wa nnkan ṣe sọrọ naa, wọn yoo fi ẹni ti ijọba fẹ jọba.
Ṣugbọn irọ gbuu ni. Awọn Ọyọmesi ko tori ọrọ yii sinmi, kaka ki eegun wọn si rọ, o tubọ n le koko si i ni. Lamidi Ọlayiwọla ti wọn fẹẹ fi jẹ Alaafin naa ko le pada si Eko mọ, oun naa duro si Ọyọ, gbogbo ohun to n lọ lo si n ṣoju rẹ, bi wọn ti n fa a lọ ti wọn n fa a bọ ko su oun alara. Gbogbo ohun ti ijọba ro pe awọn yoo fi fi tipatipa mu awọn eeyan naa ki wọn le fọwọ si orukọ Ọranlọla yii ni ko ṣee ṣe fun wọn. Nitori ẹ ni wọn ṣe n gbe oriṣiiriṣii ọgbọn dide, lara eyi ti wọn si n lo to buru ju naa ni ti awọn eeyan ti wọn n jade pe oye Alaafin tọ si awọn naa, nitori ọmọ ọba lawọn n ṣe. Ni ọjọ kẹta, oṣu karun-un, ọdun 1969, Akọwe ijọba ibilẹ Ọyọ, T. A. Taiwo, tun sare pe ipade pajawiri kan, o ni oun ri lẹta kan gba loun ṣe pe awọn Ọyọmesi ati gbogbo awọn ọmọọba pata, ki wọn wa sipade ọhun, ki wọn le jọ sọ ọrọ lẹta yii, ki awọn si mọ ohun ti awọn yoo ṣe si i. Ta lo waa kọ lẹta?
Awọn ọmọ idile ọba meji ni ilu Ọyọ ni wọn kọ lẹta naa, wọn kọ ọ si ijọba ibilẹ Ọyọ, wọn kọ ọ si gomina Ọyọ, wọn si kọ ọ si Eesuọla Akano ti i ṣe adele-ọba ilu Ọyọ, wọn ni ọrọ kan n gbe awọn ninu. Awọn meji ti wọn kọwe naa ni awọn ẹbi akọkọ ti Ọmọọba Alimi Adegbitẹ ṣaaju, ati ẹbi keji ti Shittu Adeniran ṣaaju tiwọn. Wọn ni awọn fẹ ki wọn tun ofin kan ti wọn ti ṣe lọdun 1958 nipa oye ifọbajẹ ilu Ọyọ ṣe, ki wọn yi ofin naa pada nitori ko wulo, ko si daa mọ, ati pe bi wọn ba yi ofin yii pada ni idile mejeeji ti awọn ti wa yoo le fa ọmọ oye kalẹ, ti awọn naa yoo si du ipo Alaafin to n lọ lọwọ. Wọn ni ko si ohun to ṣe e ti awọn ko le jẹ Alaafin, nigba to jẹ ọmọ oye ni awọn n ṣe, ati pe lati waa da kinni naa da idile awọn ọmọ Adeyẹmi nikan, ohun ti ko dara ni, ifiyajẹni nla lo si jẹ fun awọn, awọn si fẹ ki ijọba ba awọn da si ọrọ naa, ki wọn ma ṣe jẹ ki ẹnikẹni yan awọn jẹ.
Ohun ti eeyan yoo si fi mọ pe ẹjọ ọrọ naa lọwọ ninu ni pe bi awọn ara ijọba ibilẹ Ọyọ ti gba lẹta ni wọn sare pe ipade, awọn ti wọn ti sọ pe ko si ẹni ti yoo sọrọ Alaafin bi ogun abẹle to n lọ lọwọ ko ba pari, bẹẹ ogun naa ko ti i pari lasiko yii, koda, o ti de oju-ina, nitori gbogbo aye lo ti da si i: Ko sẹni kan to le sọ mọ boya ọwọ yoo tilẹ tẹ Ojukwu tabi ko ni i tẹ ẹ, boya ijọba yoo le gba ilẹ Ibo pada tabi wọn ko ni i le gba a mọ, nitori ibi ti wọn foju si, ọna ko gbabẹ, bi wọn ti ro pe ogun naa yoo ri kọ lo ri rara. Boya iyẹn lo jẹ ki ijọba Brigadier Adeyinka Adebayọ fẹẹ wa ọgbọn da si ọrọ Alaafin ni o, tabi wọn fẹ ki awọn ọmọọba to ku ni Ọyọ ko girigiri ba awọn Ọyọmesi ki wọn le juwọ silẹ, ki awọn si sare fi Ladepo Ọranlọla jọba, awọn nikan ni wọn le sọ.
Ohun to ṣa ṣẹlẹ ni pe Taiwo lo pepade, akọwe ijọba ibilẹ Ọyọ ni, ko si le pe iru ipade bẹẹ lori ọrọ Alaafin yii bi ijọba Western State, n’Ibadan ko ba fọwọ si i.
Ṣugbọn koko lawọn Ọyọmesi wa bii ọta-ibọn, paapaa awọn ti wọn duro lẹyin Lamidi Adeyẹmi, nitori nibi ipade naa, Eesuọla Akano tun ṣe bo ti n ṣe. Nigba ti wọn ti ka awọn lẹta mejeeji ti awọn idile ti wọn pe ara wọn ni ọmọọba yii kọ wa, ti wọn si fẹẹ maa sọ ọrọ naa, ti wọn fẹẹ maa gba a bii ẹni to n gba igba ọti, gbolohun kan pere ni adele-ọba naa fi yanju ẹ. O ni ninu ofin lati yi kinni kan pada nidii ilana fifi-Alaafin-jẹ, afi ki Alaafin wa lori oye, bi ko ba si Alaafin lori oye, ko sẹni to le yi ofin ijọba rẹ pada. O ni bi wọn ba fẹẹ yi ofin 1958 ti awọn ẹbi mejeeji n sọ yii pada, afi igba ti wọn ba fi Alaafin jẹ. Nitori bẹẹ, o ni eyi ti wọn gbe wa yii ko si ọrọ nibẹ, ati pe oun paṣẹ pe gbogbo Ọyọmesi ko tun ni i pe iwe pẹtiṣan, tabi iwe ibinu, tabi ti amọran kan lori ọrọ Ọyọmesi yii mọ, nitori ijọba ti ni ki awọn janu lori rẹ titi digba ti ogun yoo pari, awọn si ti faramọ ọrọ ijọba, nitori ọmọ Naijiria rere lawọn.
Nibẹ ni ipade ba tuka. Ọtọ ni ohun ti awọn ti wọn wa nijọba ibilẹ Ọyọ ba lọ, ọtọ ni ohun ti awọn ọmọọba ti wọn ni oye tọ si awọn naa ba lọ, ṣugbọn ọtọ ni ohun ti gbogbo wọn ba bọ nipade ọhun, ọrọ naa bu wọn lọwọ gbẹyin ni. Nigba ti awọn oniroyin ka Taiwo funra rẹ mọ lati beere pe ki lo de, idi wo lo fi pe iru ipade bẹẹ nigba toun naa mọ ohun ti Gomina Adebayọ wi n’Ibadan lọjọsi, o ni, “Nigba ti ọga mi nijọba ibilẹ Ọyọ South, Ọgbẹni E. O. Bọla, ti fun mi laṣẹ lati ṣe bi mo ba ti ro pe o dara lori ọrọ yii ni mo ṣe pepade pajawiri naa, mo fẹ ka jọ fi ikunlukun, ka gba lẹta awọn ọmọọba yii yẹwo, ka le mọ ohun ti a oo ṣe ti a oo fi yanju ọrọ to wa nilẹ yii ni. Ko si idi kan ti mo fi pepade naa ju bẹẹ lọ!” Nibi yii ni ọrọ naa ti ye awọn eeyan pe ijọba lọwọ si i, nitori alaga ijọba ibilẹ to paṣẹ ko le ṣe bẹẹ, afi to ba jẹ o ti ba wọn sọrọ n’Ibadan, ti kọmiṣanna ileeṣẹ ọrọ oye si ti ni ko ṣe bẹẹ.
Nibẹ ni ọrọ naa pari si, awọn eeyan si ti tun ro pe ohun gbogbo yoo sinmi. Ṣugbọn ko tun ri bẹẹ, koda, funra gomina lo sọrọ, iyẹn Adebayọ funra rẹ, oun naa tun sọrọ lori oye Alaafin. Ọkunrin kan to ṣẹṣẹ di olootu agba iwe iroyin Daily Times, Henry Odukomaya, lo lọọ ki Adebayọ lọfiisi rẹ, nibi ti wọn si ti n fọrọ jomitoro ọrọ ni Adebayọ ti sọ pe ninu ohun to n dun oun ju ni ọrọ oye ilu Ọyọ, o ni o ti wu oun ki oun fi Alaafin jẹ, ṣugbọn bi ọrọ naa ti ri n ka oun lara. N ni Odukomaya ba bi i pe ki lo de ti oun naa ko fi Alaafin jẹ, ki lo n da a duro gan-an. Adebayọ ni oun kọ loun da eto naa duro, awọn afọbajẹ ilu Ọyọ ti wọn n pe ni Ọyọmesi ni. O ni ki i ṣe ojuṣe ijọba oun lati fa eeyan kan fun wọn pe oun ni yoo di Alaafin, ẹni ti awọn eeyan yii ba fakalẹ ni ijọba oun yoo fi ọwọ si, ṣugbọn awọn ti bẹ wọn titi pe ki wọn mu eeyan wa wọn ko mu un wa, ohun to n da awọn duro gan-an si niyẹn.
Adebayọ ni bi oun ṣe wa yii, bi awọn Ọyọmesi ba mu eeyan wa loni-in yii, ijọba ti ṣetan lati fọwọ si ẹni ti wọn ba mu wa fun wọn. Adebayọ ni, “Ẹ wo o, ko si ohun to kan ijọba ninu ọrọ ki a yan ọba si ilu kan, iṣẹ ati ojuṣe awọn araalu naa ni. Ijọba tiwa yii ko si ni i fi ipa gbe ẹni kan le ori awọn eeyan ilu kan, ẹni ti wọn ba mu wa la oo fi jọba. Bawọn eeyan Ọyọ ba ti mu Alaafin wa, a oo fọwọ si i fun wọn. Ko ju bẹẹ lọ!” Ọjọ Ẹti, Jimọ, ọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje, ọdun 1969, ni Adebayọ sọ eleyii lọfiisi rẹ, nitori oun naa mọ pe ọrọ ti Odukomaya n beere, pe ki lo de ti oun ko gbe awọn ti wọn yoo ṣeto lati fi Alaafin jẹ dide, oun naa mọ pe ọrọ ti gbogbo ilu n sọ ni. Awọn eeyan ilu ti mọ pe ọwọ ijọba lo wa ninu ọrọ yii, wọn mọ pe ijọba Adeyinka Adebayọ ni ko fẹ ki ẹni ti ilu mu jẹ Alaafin, oun gẹgẹ bii gomina si fẹẹ wẹ ara rẹ mọ lo ṣe sọ ohun to sọ, oun naa mọ pe ki i ṣe bi ọrọ ti ri loun wi.
Ṣebi awọn Ọyọmesi si ti faayan kalẹ, to ba jẹ ijọba ko ba wọn da si i, ki lo de ti wọn ko gba ẹni ti wọn mu wa wọle, tabi ki i ṣe Adebayọ lo paṣẹ pe ki wọn gbe ọrọ Alaafin ti sẹgbẹẹ kan na, oun n jagun lọwọ ni. Gbogbo eleyii lawọn araalu mọ, ọrọ naa si ti de eti Adebayọ funra rẹ laimọye igba pe awon eeyan ko fẹ ohun to n ṣe. Ọjọ keji ti ọrọ gomina yii jade ni awọn ara Ọyọ ranṣẹ si i. Ṣe oun lo sọ pe bi Ọyọ ba ti mu ẹni kan wa, oun yoo fi i jọba, pọnkan ni awọn agbaagba ati awọn ọmọ ilu Ọyọ si wọn ọrọ naa mọ ọn lọwọ, wọn ranṣẹ si i pe ko si ohun to n da awọn duro, oun ni ko jọwọ, ko fun awọn ni ọba. Kọmiṣanna ninu ọfiisi gomina funra rẹ, Ọgbẹni S. A. Yerokun, ni wọn ran si i. Yerokun lo lọ si ilu Ọyọ, nitori ọrọ wahala owo-ori to n ṣẹlẹ nigba naa, to fi di pe awọn ọmọ ogun Agbẹkọya n ba awọn agbowo-ori ja lo jẹ ki ọkunrin naa gba ilu Ọyọ lọ lati lọọ ṣalaye ọrọ owo-ori ijọba tuntun fun wọn.
Amọ bo ti mu ẹnu le ọrọ owo-ori naa fun wọn ni awọn eeyan naa ti sọ pe kekere ni ti owo-ori, awọn ni iṣẹ pataki lati bẹ ẹ. N ni wọn ba fa lẹta kan sagila jade fun un. Wọn ni ko gba lẹta naa ko ba awọn fun ọga rẹ, awọn yoo si tun fi ẹnu sọ ohun to wa ninu lẹta naa fun un. Wọn ni bo ba jẹ ti ọrọ owo-ori ni, ko fi ọkan balẹ pe ko ni i si wahala ọrọ owo-ori ni ilu Ọyọ, awọn yoo san owo-ori ti ijọba fẹ, gbogbo owo-ori ti wọn ba bu fun awọn lawọn yoo san, awọn ko si ni i ba ijọba jiyan lori ẹ, bẹẹ ni ẹnikẹni ko ni i bọ sigboro lati ja nitori ọrọ yii. Ṣugbọn o, oun naa gbọdọ ṣe kinni kan fawọn, iyẹn naa ni pe ko fun awọn ni Alaafin Ọyọ, ko fun awọn ni ọba ilu awọn. Wọn ni awọn ko fẹ lọ-ka-bọ lori ọrọ naa mọ, asiko ti to ti ijọba gbọdọ fun awọn ni Alaafin awọn, awọn ti duro pẹ, iru eyi ko si ṣẹlẹ l’Ọyọọ ri, ọrọ naa n ka gbogbo ilu lara. Wọn ni ko si ẹni to le paṣẹ ti yoo mulẹ kia l’Ọyọọ ju Alaafin lọ, nitori oun lalaṣẹ.
Wọn ni eyi ti ijọba n wa, ti aya wọn n ja pe boya wahala yoo ṣẹlẹ lori ọrọ owo-ori yii, bi awọn naa ba ti fi Alaafin jẹ ni, ki wọn sun ki wọn maa lalaa ni, ko sẹni ti yoo da wahala silẹ, nitori bi Alaafin ba ti sọrọ, abẹ ge e ni. Yerokun gba lẹta wọn, o ni inu oun si dun bi wọn ti ba oun sọrọ ati gbogbo ileri ti wọn ṣe lori ọrọ owo-ori, o ni oun fẹẹ fi da wọn loju pe oun yoo gbe ọrọ wọn de ọdọ ijọba, oun yoo fi lẹta ti wọn kọ si gomina fun un, awọn naa yoo si gbọ esi iwe naa kia. Yerokun ni nibi ti ọrọ oye Alaafin de bayii, ko tun sohun to gbọdọ fa ija mọ, o ni kawọn Ọyọmesi atawọn araalu ba ijọba ṣiṣẹ pọ, ki wọn le fi Alaafin tuntun jẹ. Yerokun ni inu ijọba paapaa ko dun si bi ọrọ yii ti n pẹ yii, awọn naa ko si isinmi lori ẹ. O ni kinni kan lo da oun loju, iyẹn naa ni pe awọn eeyan naa yoo gba esi ayọ lati ọdọ ijọba, lẹta ti wọn kọ yii yoo si mu nnkan rere wa. Ọjọ kọkandinlogun, oṣu keje, 1969, ni gbogbo eleyii ṣẹlẹ.
Amọ lẹta ti awọn ara Ọyọ kọ naa ko mu esi ayọ pada waa ba wọn gẹgẹ bi Yerokun ti ṣeleri, kinni naa tun da wahala silẹ si i ni. Ijọba Adeyinka fẹẹ gba ọna ẹyinkule ṣe ohun ti wọn ko le gba iwaju ile ṣe. Wọn fẹẹ fi Alaafin jẹ loootọ, nitori ọrọ naa ti di ariwo ati itiju fawọn naa, ṣugbọn wọn ko fẹẹ fi ẹlomiran jẹ oye naa ju ẹni to wa lọkan wọn lọ. N ni awọn ba tun da ọgbọn buruku kan. Ni ọjọ kẹfa, oṣu kẹsan-an, 1969, lojiji lawọn eeyan gbọ pe ijọba ti yan awọn afọbajẹ Ọyọ tuntun. Ijọba yan awọn Ọyọmesi tuntun, wọn si fi agbara ijọba ologun yan wọn, wọn ni ko si ojuṣe ti wọn fẹẹ ṣe ju ki wọn yan Alaafin tuntun lọ. Ohun ti wọn sọ ni pe o ti ṣẹlẹ nigba kan ri ti awọn ti ki i ṣe Ọyọmesi di ọmọ igbimọ Ọyọmesi, ti wọn si yan Alaafin tuntun. Kọmiṣanna ọrọ oye nigba naa, Lamuye, lo ṣalaye yii, o ni ko si ohun to buru ninu ohun ti ijọba ṣe lati yan Ọyọmesi tuntun, nitori awọn ti ṣetan lati fi Alaafin jẹ.
Ṣe awọn araalu ko kuku tilẹ mọ, bi ko si jẹ pe ọrọ naa ti di ọrọ ilu, to jẹ bi awo ti n lu lawo n jo, ko sẹni ti i ba mọ pe ijọba Adebayọ ti ṣe iru ohun to le to bẹẹ. Wọn ti fi awọn Ọyọmesi mi-in jẹ, iṣẹ kan ṣoṣo ti wọn si gbe le wọn lọwọ naa ni lati fi orukọ Alaafin tuntun ranṣẹ si awọn. Kinni kan ba Ajao jẹ, apa rẹ gun tayọ itan ṣaa o: bi igbesẹ naa iba ti dara to, tabi ti awọn eeyan iba sọ pe o daa lati fi pari ija to wa nilẹ naa, awọn ijọba yii ṣe nnkan aburu kan, eyi to fihan pe alabosi pata lawọn naa, iwakiwa si kun ọwọ wọn. Ohun ti wọn ṣe ni pe wọn mu awọn ijoye meji ti wọn faramọ Ladepo Ọranlọla lati di Alaafin. Iyẹn ni pe ninu Ọyọmesi tuntun ti wọn gbe dide yii, wọn mu Aṣipa Ọyọ igba naa, Oyekọla, bẹẹ ni wọn si mu Lagunna, Sunmọnu Oyewọ, wọn lo yẹ ki wọn wa ninu igbimọ naa ki wọn le fọna han awọn to ku ti awọn ṣẹṣẹ yan sipo Ọyọmesi. Haa, ni gbogbo eeyan n ṣe.
Idi ni pe ko si ọna ti awọn eeyan naa fẹẹ fi han awọn ti wọn ṣẹṣẹ yan ju pe ki wọn sọ fun wọn pe orukọ Ladepo Ọranlọla lawọn mu lọ. Bi wọn ba si ti jokoo, ohun ti wọn yoo ṣe niyẹn, ijọba yoo si ko ọlọpaa ati ṣọja lati waa duro ti wọn lọjọ ti wọn ba fẹẹ dibo, wọn yoo si ni awọn ti dibo, gbogbo awọn lawọn fọwọ si i ki wọn yan Ladepo si ipo Alaafin. Nibẹ lọrọ naa yoo ti pari, nitori ko ni i si ohun ti ẹnikẹni le ṣe, nigba to jẹ awọn ti wọn n ṣejọba, ti wọn fẹẹ fi ọba jẹ, naa ni wọn funra wọn doju eto naa ru. Bi ko ba waa jẹ bẹẹ, bawo ni wọn yoo ṣe fi orukọ Aṣipa ati ti Lagunna sinu igbimọ Ọyọmesi tuntun, nigba ti gbogbo aye mọ pe awọn meji yii naa ni wọn wa lẹyin Ladepo ninu awọn Ọyọmesi mejeeje ti wọn dibo lati yan Alaafin tuntun. Ati pe awọn ti ijọba ko jọ lati di ọmọ Ọyọmesi yii ki i ṣe lara Ọyọmesi, awọn oloye mi-in ni gbogbo wọn. Ijọba sọ pe eleyii ki i ṣe akọkọ, wọn ni lasiko ti wọn fẹẹ yan Bello Gbadegẹṣin Ladigbolu Keji, awọn ti ki i ṣe Ọyọmesi lọwọ si yiyan ọba naa.
Awọn Ọyọmesi ko duro o. Wọn ko tilẹ jẹ ki ọrọ naa pẹ rara, nitori wọn mọ ohun aburu ti ijọba le ṣe. Ọjọ Satide ni ijọba gbe ofin buruku lati yan awọn oloye Ọyọmesi tuntun jade, awọn afọbajẹ Ọyọ yii si mọ pe o ṣee ṣe ki ijọba sare sọ pe awọn ti ṣepade ni ọjọ Mọnde, ki wọn si gbe abajade irọ kan kalẹ fun gbogbo ilu. Nitori bẹẹ, ni kutukutu owurọ ni ọjọ Aje Mọnde yii, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹsan-an, 1969, awọn Ọyọmesi mẹrin ti gba ile-ẹjọ lọ, nitori nigba naa, ẹni kan ninu awọn to n ja ija naa si ti dagbere faye. Awọn mẹrin ti wọn sare lọ sile-ẹjọ yii ni Oloye Salami Ọladeji ti i ṣe Samu, Oloye Mọmọdu Aṣamu ti i ṣe Agbaakin, Oloye Salami Adeniyi ti i ṣe Akinniku ati Baṣọrun Eesuọla Akano ti i ṣe olori wọn. Wọn sare lọ si ile-ẹjọ, wọn si pe ijọba Western State lẹjọ, wọn pe gomina Adeyinka Adebayọ lẹjọ, wọn si pe ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye nibẹ ati kọmiṣanna wọn lẹjọ.
Ẹjọ ti wọn pe wọn ni pe ijọba ni o, tabi gomina, tabi ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye, ko si ẹni kan to lẹtọọ lati yọ awọn nipo, ti wọn yoo si fi ẹlomi-in si i, nigba ti awọn ko ku, ti ki i ṣe pe awọn ko si ṣe ojuṣe awọn gẹgẹ bi ofin ti sọ. Wọn ni awọn mọ pe nitori abosi ati aiṣododo ni ijọba ati gomina pẹlu awọn eeyan wọn ṣe fẹẹ ṣe ohun ti wọn ṣe yii, awọn ti bẹ ile-ẹjọ lati ma faaye gba wọn, ki ile-ẹjọ paṣẹ lẹsẹkẹsẹ pe ohun ti wọn fẹẹ ṣe naa ko daa. Ati pe ki ile-ẹjọ tilẹ kọkọ paṣẹ ki wọn da gbogbo igbesẹ yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe lori ọrọ awọn Ọyọmesi tuntun duro, nitori awọn mọ pe ohun to le fa wahala ati itajẹsilẹ l’Ọyọọ ni. Wọn lawọn o fẹ wahala fun gbogbo ilu Ọyọ, awọn ko si fẹ wahala fun ijọba, paapaa ni asiko ti ogun abẹle n lọ lọwọ, pe o ya awọn lẹnu pe ijọba funra rẹ to ni oun ko fẹ wahala tabi idiwọ lo tun lọọ n fa ijangbọn lẹsẹ, wọn ni ki ile-ẹjọ ma gba awọn ijọba West laaye lati sọ awọn ara Ọyọ lẹnu.
Ohun mẹrin pataki ni awọn Ọyọmesi yii n beere lọwọ ile-ẹjọ, ohun mẹrin naa ni wọn si fẹ ki ile-ẹjọ ṣe fawọn. Akọkọ ni pe ki ile-ẹjọ paṣẹ pe ofo ati adanu lasan ni yiyan awọn oloye mẹsan-an kan lati waa ṣe ojuṣe awọn Ọyọmesi niluu Ọyọ, ohun ti ko ṣẹlẹ ri, ti ko si ba ofin mu ni. Ẹẹkeji ni ki ile-ẹjọ tun paṣẹ pe awọn ijoye mẹsẹẹsan ti ijọba West yan yii ko lẹtọọ si ipo Ọyọmesi, nitori wọn ki i ṣe ọmọ ile awọn Ọyọmesi, awọn ti wọn si jẹ ọmọ ile naa, awọn eeyan wọn kọ lo fa wọn kalẹ, wọn ko si yan wọn bii Ọyọmesi nigba kankan. Ẹẹkẹta ni pe ki ile-ẹjọ ka ijọba Western Region ati awọn ileeṣẹ ijọba to n ri si ọrọ oye lọwọ ko pe apapọ gbogbo wọn ko le gba iṣẹ awọn Ọyọmesi ṣe, wọn o si gbọdọ jẹ ki wọn ṣe bẹẹ, nitori ohun to lewu ni. Lọna kẹrin, awọn eeyan naa fẹ ki ile-ẹjọ paṣẹ fun ijọba West ati gomina wọn ki wọn fi aaye gba awọn Ọyọmesi to ti wa nipo tẹlẹ lati ṣe iṣẹ wọn, lai si idaduro kan.
Bayii ni keesi bẹrẹ o, keesi tuntun lori ọrọ oye Alaafin. Keesi naa ko si deede bẹrẹ bi ko ba jẹ ohun ti ijọba funra wọn ṣe, awọn ni wọn fẹẹ gba oye lọwọ awọn Ọyọmesi, wọn fẹẹ ko awọn mi-in wa, ki wọn fi wọn rọpo awọn ti wọn ti wa nibẹ tẹlẹ, ki wọn le tete yan Ladepo Ọranlọla sipo gẹgẹ bii Alaafin tuntun. Eto ti wọn ti ṣe, ti wọn si ti pari, naa ni pe laarin ọsẹ kan yii naa ni wọn yoo jẹ ki awọn Ọyọmesi tuntun yii jokoo, wọn aa si yan Ọranlọla, iwe ti ijọba yoo si maa gbe kiri ree, wọn yoo ni awọn Ọyọmesi lo yan Alaafin wọn, ki i ṣe awọn, wọn o si ni i sọ fẹnikan mọ to ba ya pe awọn lawọn gbe awọn Ọyọmesi tuntun dide. Bi wọn ba ti ṣe bẹẹ, yoo ṣoro lati gba ipo naa pada fun ẹni ti awọn Ọyọmesi akọkọ ti kọkọ yan, iyẹn Lamidi Adeyẹmi. Iyẹn ni ija naa ṣe le lati ibẹrẹ, awọn Ọyọmesi ko mu ọrọ ẹjọ naa ni kekere rara, nitori wọn mọ pe bi ẹjọ naa ba n lọ, ijọba ko le ṣe ohunkohun.
Lọọya ti awọn Ọyọmesi ni to ti n ba wọn ro ẹjọ yii lati ibẹrẹ, ti oun naa si jẹ ọmọ Ọyọ nibẹ, Abiọdun Akerele, naa lo jade to bẹrẹ ẹjọ yii, ṣugbọn nigba yii, awọn lọọya mi-in bii Rotimi Williams, ti wa lẹyin rẹ, wọn n ba a da si. Emmanuel Aṣamu, ẹni to ni Ashamu Farms, n gbe owo kalẹ, bẹẹ si ni awọn ọrẹ Alaafin Adeniran Adeyẹmi ti wọn wa l’Ekoo bẹrẹ si i gbe owo kalẹ, wọn ni nibi ti ẹjọ naa ba fẹẹ lọ awọn ṣetan lati tẹle wọn lọ. Bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọrọ naa sita, ija naa ti di ti awọn oloṣelu pata. O ti di ijọba awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group ati awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC ati awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ. Awọn agbaagba ẹgbẹ wọn ti wọn ja ija ajaku-akata nijọsi, awọn naa ni wọn wa nidii ọrọ yii, wọn kan n paṣẹ fun awọn ti wọn wa l’Ọyọọ lori ohun ti wọn yoo ṣe ni. Ṣugbọn awọn eeyan mọ pe yoo ṣoro fun ijọba West lati ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe, nitori ko si awọn araalu lẹyin wọn, ẹyin Lamidi Adeyẹmi ni wọn wa.
Akerele sọ fawọn oniroyin lọjọ kejila, oṣu kẹsan-an, 1969 yii, pe ẹbẹ kan loun fẹẹ bẹ ijọba West, ki wọn sọ fun Lamuye ti i ṣe kọmiṣanna ọrọ ijọba ibilẹ fun wọn ko mu ẹri jade, oun ati awọn araalu fẹẹ ri ẹri ọwọ rẹ. O ni ẹri ti awọn fẹẹ ri naa ni pe ko waa darukọ awọn ijoye ti ki i ṣe lara Ọyọmesi ti wọn kopa ninu eto lati yan Alaafin Bello Gbadegẹṣin Ladigbolu sipo Alaafin lọjọsi. Lamuye lo kuku ti fẹnu ara rẹ sọ fawọn oniroyin tẹlẹ pe nigba ti wọn fẹẹ yan Alaafin Ladigbolu Keji yii, ijọba awọn Oloye Western Region igba naa pe awọn ti ki i ṣe lara Ọyọmesi lati waa ba awọn kopa ninu eto naa, nigba ti awọn Ọyọmesi kan taku laarin wọn. Lọrọ kan, ohun ti Lamuye n sọ ni pe ohun ti ijọba Western Region igba naa ṣe laye Action Group lawọn naa fẹẹ ṣe bayii laye ijọba ologun, Ladepo lawọn fẹ, awọn si lagbara lati yan awọn Ọyọmesi tawọn naa, ki i ṣe akọkọ rara.
Iyẹn ni Akerele ṣe pe e pe ko jade si gbangba, awọn araalu fẹẹ gbọrọ si i lẹnu rẹ, ko waa darukọ ẹni ti awọn Action Group lo nigba naa ti ki i ṣe lara Ọyọmesi, to ba ti le sọ ọ sita, awọn yoo mọ pe ootọ lo n sọ. Bi ko ba si le sọrọ naa sita, ko kọ ọ siwee, ko ṣa ti darukọ awọn ijoye ti wọn lo lọjọ naa fawọn ni. Nigba ti Akerele fẹnu sọrọ naa ti ko tete mu esi wa, o tun kọ lẹta si Lamuye bayii pe: “Ẹ jọwọ, njẹ mo le fi tọwọtọwọ ṣalaye fun yin pe mo wa ninu ijọba ti ẹ n sọrọ rẹ yii, iyẹn ijọba Action Group to fi Bello Gbadegẹṣin Ladigbolu jẹ Alaafin. Mo mọ gbogbo ohun to ṣẹlẹ nigba naa pata, nitori ẹyin ti ẹ n sọrọ bayii ko si ninu ẹgbẹ wa tabi ninu ijọba wa, inu ẹgbẹ Alatako (NCNC), lẹ wa, ko si si bi ẹ ti ṣe le mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an ju iru awa ti a jẹ ọmọ ẹgbẹ yii lọ. Ṣugbọn bi ẹ ṣe waa sọ pe ẹ mọ ọn ju wa lọ, ko buru rara o, nitori nigba mi-in, araata le riran ju araale lọ.
“Ṣugbọn ẹbẹ kan ni mo fẹẹ bẹ yin o, ẹbẹ naa ni pe ki ẹ jọwọ, ki ẹ darukọ awọn ijoye Ọyọ ti wọn ki i ṣe lara Ọyọmesi ti wọn wa ninu awọn afọbajẹ ti wọn yan Ladigbolu bii Alaafin. Gẹgẹ bi ẹ ti ṣe sọ nigba ti ẹ n ba awọn oniroyin sọrọ, ohun ti ẹ mọ ti o da yin loju ni, ṣugbọn ẹ ko darukọ ẹnikẹni. Mo fẹ ki ẹ darukọ awọn Ọyọmesi tuntun ti wọn yan nigba naa, ki gbogbo wa le ri nnkan fi ṣiṣẹ, ka si mọ awọn eeyan naa, boya wọn ti ku ni tabi wọn wa laye. Bi wọn ba wa laye, yoo wulo fun gbogbo wa, nitori wọn yoo le waa sọ bi ọrọ naa ti ri gan-an ni gbangba. O ṣee ṣe ko jẹ ninu akọsilẹ awọn ijọba kan lẹ ti ri ọrọ yii, tabi ko jẹ akọsilẹ ti awọn ọmọ ẹgbẹ yin, NCNC, igba naa ṣe lẹ ti ri i, eleyii yoo mu anfaani wa lati le mọ pe ẹ mọ ohun ti ẹ n sọ daadaa. Bi a ba ti le mọ orukọ awọn ti wọn kopa nibẹ ti wọn ki i ṣe lara awọn Ọyọmesi, ọrọ ti a n fa lati ọjọ yii ṣee ṣe ko niyanju, boya a ko si ni i tori rẹ gba ile-ẹjọ lọ.
“Bi ẹ ba le ṣe eleyii. yoo dara gan-an, nitori ọrọ ti ẹ sọ yii, ọrọ abuku ati ibanilorukọ jẹ gidi ni fun Ọba Gbadegẹṣin Ladigbolu to ti doloogbe, nitori ohun ti ẹ n sọ ni pe wọn ko yan an bo ṣe yẹ ki wọn yan an sipo Alaafin. Ṣugbọn bo ba jẹ bẹẹ naa ni, ootọ ni i gbe ni leke, bi ootọ ọrọ naa ba jade, awọn ti wọn ṣe iru nnkan bẹẹ, ninu eyi ti emi naa wa lara wọn, yoo le ṣalaye idi ti wọn ṣe ṣe e, wọn yoo si tọrọ aforijin, iyẹn to ba jẹ bẹẹ ni wọn ṣe. N oo maa reti esi yin ni gbangba, gẹgẹ bi ẹ ti ṣe sọ o!” Bayii ni Abiọdun Akerele, lọọya awọn Ọyọmesi, ṣe kọwe ranṣẹ si Lamuye ti i ṣe kọmiṣanna fun ọrọ oye ni Western State lọjọ naa lọhun-un, o ni oun fẹ alaye lori ohun ti ọkunrin naa sọ fawọn oniroyin. Lamuye ko dahun o, koda, ko wi kinni kan, boya ijọba lo si sọ pe ko gbọdọ sọrọ ni, ẹnikan ko mọ, ṣugbọn gbogbo ibeere ti Akerele bi i, esi kankan ko jade lati ọdọ Lamuye tabi ileeṣẹ rẹ to n ri si ọrọ oye jijẹ.
A kan n wi naa ni, Lamuye ko le sọrọ. Tabi ọrọ wo ni yoo sọ? Akerele ni alaga ijọba ibilẹ Ọyọ keji, lasiko ti ija Bọde Thomas ati Alaafin Adeniran Adeyẹmi bẹrẹ, oun naa wa lara awọn ti wọn ri i pe wọn yọ Alaafin naa kuro nipo lẹyin ti Bọde Thomas ku, awọn ohun ti wọn ṣe ti ko dara nigba naa pẹlu idi to fi fẹẹ ri i pe oun ja fun ọmọ rẹ lati di Alaafin. Lẹyin ti Bọde Thomas ti ku, gbogbo iwe ti wọn fi yọ Alaafin Adeyẹmi ati awọn iwe ti wọn fi mu Alaafin tuntun igba naa, iyẹn Ladigbolu, awọn Akerele ni wọn wa nidii rẹ, ko si si ohun to lọ, tabi ohun ti wọn ṣe nigba naa ti ko mọ, ko sẹni to le sọ itan ọrọ naa fun un, nitori oun gan-an lo ṣe e, oun ni awọn ara Ibadan lo lati pari eto gbogbo, nigba to jẹ oun ati Bọde Thomas ni wọn ti jọ wa nibẹ nibẹrẹ ọjọ, bii ọmọ ni Alaafin Adeniran ṣe mu awọn mejeeji, wọn si mọ Bello Ladigbolu paapaa ko too di Alaafin rara, awọn ni wọn fi i jẹ.
Iyẹn ni ko ṣe si esi kankan to jade lati ẹnu Lamuye tabi ileeṣẹ rẹ, tabi ọga rẹ, wọn mọ pe ẹni ti awọn n ba ta ayo yii, bi awọn ta a nigba igba, awọn ko le jẹ. Ni wọn ba yaa sinmi ni tiwọn. Awọn eeyan ko mọ ibi ti ọrọ naa waa n lọ mọ bayii, wọn ko mọ awọn ti wọn yan si ipo Ọyọmesi ti ijọba n wi yii, wọn ko gbọ nipa wọn to bẹẹ ju bẹẹ lọ, ijọba ko si ti i fi orukọ wọn han sẹnikan, nitori awọn naa n bẹru, wọn mọ pe bi awọn ba darukọ wọn ti aye gbọ, afaimọ ki wahala gidi ma bẹ silẹ l’Ọyọọ, afaimọ ki awọn ọmọ ilu naa ma lọọ ya ba wọn nile wọn ki wọn si ṣe wọn jatijati. Ki ọrọ naa ma di rogbodiyan ti apa ọlọpaa tabi ṣọja paapaa ko ni i tete ka ni ijọba ṣe pa orukọ awọn Ọyọmesi ti wọn ni awọn yan yii mọ, wọn ko sọ orukọ wọn sita fẹnikan. Ko sẹni to mọ igba ti wọn mu wọn tabi ibi ti wọn ti mu wọn, ijọba funra rẹ lo n da gbogbo rẹ ṣe. Ṣugbọn ọkan awọn eeyan balẹ diẹ pe awọn Ọyọmesi ti gba ile-ẹjọ lọ, ohun ti yoo tibẹ jade ni wọn ko ti i mọ.
Ile-ẹjọ ti awọn Ọyọmesi lọ yii bi ijọba West ninu, o dun wọn gan-an. Wọn ko mọ pe kinni naa yoo ya to bẹẹ, wọn ko mọ pe awọn eeyan naa yoo tete gba ile-ẹjọ lọ. “Bawo ni wọn ṣe ṣe e? Ṣe wọn ti mọ tẹlẹ ni? Awọn wo lo n ti awọn Ọyọmesi yii lẹyin paapaa? Abi ta lo tete ni ki wọn lọ sile-ẹjọ yii na?” Awọn ibeere ti awọn eeyan naa n bi ara wọn niyẹn, nitori ọrọ naa toju su ijọba West funra wọn. Wọn mọ pe yoo ṣoro fun awọn gidi lati yan Alaafin ti awọn fẹ bi ẹjọ naa ba ti bẹrẹ, wọn mọ pe bi adajọ ba da a pe ki awọn sinmi, ko si ohun tawọn le ṣe, ati pe bi ẹjọ ba si ti bẹrẹ, gbogbo ọrọ naa yoo sinmi titi di igba ti ẹjọ yoo pari ni. Nibi to ka wọn lara de, niṣe lawọn naa sare jade, ijọba si ni awọn ti paṣẹ fun awọn Ọyọmesi tuntun ki wọn maa ba iṣẹ wọn lọ, ko si ayipada ninu ẹ mọ, awọn ti ṣetan ti awọn yoo yan Alaafin tuntun, ọrọ ti wa lọwọ awọn Ọyọmesi.
Ileeṣẹ to n ri si ọrọ oye lo sọrọ lasiko yii, iyẹn ileeṣẹ Lamuye. Wọn ni nigba ti awọn ba yan Alaafin, ẹni ti ọrọ naa ko ba tẹ lọrun yoo gba ile-ẹjọ lọ, nitori awọn yoo mọ pe awọn ti ṣe tawọn ninu ọrọ naa, ojuṣe tawọn ko ṣa ju ki awọn yan Alaafin sipo lọ, bi awọn ọmọ oye ba si ti ni irọ ni, ki wọn lọọ maa ba ara wọn fa a ni ile-ẹjọ. Ṣugbọn awọn eeyan ti wọn wa nidii ẹjọ awọn Ọyọmesi fi ọkan awọn baba naa balẹ pe ko si ohun ti ijọba yoo ṣe pẹlu ọrọ naa to ti de ile-ẹjọ, wọn ni wọn kan n halẹ lasan ni, ohun yoowu ti ijọba ba fẹẹ ṣe, wọn yoo duro de ọrọ ẹjọ to wa nile-ẹjọ yii na, wọn ni ki wọn ma da wọn lohun gbogbo ariwo ti wọn n pa. Akerele tilẹ ti sọ pe bi wọn lọọ ro ẹjo naa ni Sokoto, bo si jẹ Kafanchan ni, tabi ko jẹ ilẹ Kusangba, ẹbi lewurẹ i jẹ bọ nisọ eree ni, wọn yoo jẹbi bọ wa sile ni. Iyẹn lọkan awọn Ọyọmesi yii ṣe balẹ, wọn mọ pe ko sewu loko, afi giiri aparo.
Ati pe iroyin to n de etiigbọ ijọba ko dara. Ohun ti wọn n gbọ ni pe ko si ibi ti awọn Ọyọmesi yoo ti jokoo ju ile Baṣọrun lọ, nitori ko si ẹlomiiran ti yoo gba ipo Baṣọrun ṣe, afi ti wọn ba yan Baṣọrun mi-in, bẹẹ Baṣọrun ko ṣee deede yan bẹẹ lasan. Gbogbo awọn oye yii, bi wọn ba fẹẹ yan wọn, laarin ilu Ọyọ ni wọn yoo ti yan wọn, gbogbo ilu ni yoo si fọwọ si i. Yatọ si pe gbogbo ilu fọwọ si i, o ni etutu ti wọn yoo ṣe fun oloye kọọkan ni idile rẹ ko too di oloye naa, ati ko too di ọmọ igbimọ Ọyọmesi yii. Gbogbo eleyii ko ṣẹlẹ nibi kan laarin Ọyọ, koda awọn eeyan ko mọ awọn Ọyọmesi tuntun ti wọn n sọ. Imura ti waa wa pe ti ẹnikẹni ba yọju to ba ni oun Ọyọmesi, tabi to ba lọọ jokoo si ibikan to ni awọn fẹẹ lo ibẹ bii aafin Baṣọfun, afaimọ ko ma jẹ wọn yoo dana sun ile naa ti awọn eeyan ibẹ lọwọ kan ni. Ijọba ti gbọ pe wahala yoo bẹ bi wọn ba ṣe iru ẹ, iyẹn lawọn naa ṣe n wa ọna ti wọn yoo ba wọle.
Amọ nibi ti wọn ti n sọ eleyii ni wahala mi-in ti de. Ọrọ bẹyin yọ lojiji, ohun ti awọn ara Ọyọ ko reti rara ni wọn gbọ. Iwe iroyin Daily Times ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹsan-an, ọdun 1969, lo gbe e jade, oju iwe kin-in-ni gan-an ni iroyin naa wa, oun si ni akọkọ loju iwe naa, o ri gadagba gadagba. “THE NEW ALAAFIN OYO IS PICKED” ni akọle iroyin naa, iyẹn ni pe “WỌN TI MU ALAAFIN ỌYỌ TUNTUN O” Iroyin naa lọ bayii pe: “Wọn ti mu Alaafin ilu Ọyọ tuntun o, eleyii wa ninu afidafiiti (iwe-ibura) ti ileeṣẹ to n ṣeto ọrọ oye ni Western State ṣe ni kootu, ile-ẹjọ giga ilẹ Ibadan, lanaa ode. Ṣugbọn ọpọ awọn oṣiṣẹ naa ko darukọ Alaafin tuntun ti wọn mu yii, wọn fi orukọ rẹ pamọ. Awọn oṣiṣẹ ijọba yii ni lọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, 1969, lawọn ti gbe awọn Ọyọmesi tuntun dide, wọn si ti ṣepade wọn niluu Ọyọ, wọn si ti yan ẹni ti wọn fẹ bii Alaafin, orukọ ẹni naa si ti wa lọwọ Ijọba.”
Iroyin naa tẹsiwaju bayii pe: “ Oniroyin Daily Times woye pe awọn meji naa pere lo n du ipo yii, awọn naa si ni Ọgbẹni Ọladepo Adeyẹmi ati Ọgbẹni Lamidi Adeyẹmi, o si daju pe ninu awọn mejeeji ni wọn yoo ti mu ẹni kan ti wọn mu yii. Ana ni ileeṣẹ ọrọ oye gbe afidafiiti yii si iwaju adajọ nigba ti ẹjọ ti awọn Ọyọmesi pe ijọba Western State, ti wọn sọ pe ijọba ko lẹtọọ lati yan ẹlomi-in rọpo awọn, ki ile-ẹjọ si fagile igbesẹ ijọba yii kiakia. Ati pe lati ma daamu ile-ẹjọ ni afidafiiti yii ṣe jade, eyi ti ijọba ipinlẹ West fi n ṣalaye pe ki ile-ẹjọ ma wulẹ yọ ara wọn lẹnu, awọn ti yan Alaafin tuntun, ko si si awuyewuye kan lori ẹ mọ, ki ile-ẹjọ da ẹjọ ti awọn afọbajẹ Ọyọ ti wọn n pe ni Ọyọmesi yii pe nu, ki kaluku pada sile wọn, ki wọn maa reti ọjọ ti Alaafin Ọyọ yoo jẹ!”
Bi iroyin yii ti jade ni ọrọ di wahala, rogbodiyan bẹ niluu Ọyọ o!

(34)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.