Akọwe SDP kowe fipo silẹ nitori ibo to gbe Paṣẹda wọle

Spread the love

Akọwe eto gbogbo ninu ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party (SDP), nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Suleiman Abiọdun-Alli, ti kọwe fipo naa silẹ bayii, to si tun loun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa mọ, nitori ibo abẹle to gbe Ọmọba Rotimi Paṣẹda wọle gẹgẹ bii oludije sipo gomina kun fun magomago.
Opin ọsẹ to kọja yii ni Abiọdun-Alli sọ ero ọkan rẹ di mimọ nigba to kọwe fipo akọwe ẹgbẹ naa silẹ. Alaye to ṣe ni pe gẹgẹ bii alaabojuto idibo abẹle Aarin-Gbungbun ipinlẹ Ogun, oun ri i pe eru pọ ju ninu eto idibo naa.
Ọkunrin yii ni oun pe akiyesi awọn eleto naa atawọn to yẹ ko gbọ si eyi, oun si duro ọsẹ kan pe boya wọn yoo tun gbogbo ibi ti eru naa ti waye ṣe, nipa kikede ẹni to jawe olubori gan-an.
O ni ṣugbọn ẹgbẹ SDP ko ṣe atunṣe kankan, niṣe ni wọn pepade awọn akọroyin, ti wọn si ni ki wọn kede Ọmọba Rotimi Paṣẹda gẹgẹ bii ẹni to gbegba oroke ninu idibo sipo gomina lọdun to n bọ, bẹẹ, ki i ṣe oun lo wọle.
Gẹgẹ bii ẹni to ni ẹri ọkan, Abiọdun loun ko le tẹsiwaju pẹlu ẹgbẹ yii, idi niyẹn toun fi fipo oun silẹ bii akọwe, toun si ti kuro ninu SDP naa.
Lati mọ iha ti ẹgbẹ SDP kọ si igbesẹ ti Suleiman Alli-Abiọdun gbe yii, ati ohun to sọ nipa ibo to gbe Paṣẹda wọle, ALAROYE pe akọwe ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Ọgbẹni Fẹmi Fọlalu, ṣugbọn ko gbe ipe naa, niṣe lo ni ka fi atẹjiṣẹ ranṣẹ.
Akọroyin wa fi atẹjiṣẹ ọhun ranṣẹ, ṣugbọn Ọgbẹni Fọlalu ko fesi pada titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.