Akọwe PDP yege, Wahab Isa gba tikẹẹti lati dije fun ile-igbimọ aṣoju-ṣofin lọwọ Kannike

Spread the love

Ọnarebu Abubakar Kannike, to n ṣoju Ẹkun Ila-Oorun ati Guusu Ilọrin, ni ile-igbimọ aṣoju-ṣofin l’Abuja, ti padanu tikẹẹti lati pada sile aṣofin nitori Ọnarebu Wahab Isa, ni wọn sọ pe o jawe olubori nibi eto idibo abẹle ẹgbẹ PDP to waye l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ to kọja.

Bakan naa ni Alhaji Rasaq Lawal gba tikẹẹti mọ Alhaji Toyin Sanusi ati Onimọ-Ẹrọ Sulaiman Warah, lọwọ nibi eto idibo abẹle lati mọ ẹni to maa ṣoju Asa ati ijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ilọrin

Awọn oloṣelu to gbajumọ lati ijọba ibilẹ Ekiti nipinlẹ Kwara bii Ọnarebu Ẹbun Owolabi, Ọtunba Taiye Joseph ati Oloye C. T Ayẹni ko rọwọ mu lati rọpo Funkẹ Adedoyin to jade laye laipẹ yii. Onimọ-Ẹrọ Dare Bankọle to wa lati Oke-Ẹrọ ni tikẹẹti naa ja mọ lọwọ.

Ọnarebu Tọpẹ Ọlayọọnu to n ṣoju ẹkun Ọffa/Ọtun/Ifẹlodun nile igbimọ aṣoju-ṣofin nikan lo ri tikẹẹti pada sile igbimọ aṣoju-ṣofin laarin awọn aṣoju mẹfẹẹfa to wa lati Kwara.

Ahman Patigi, to n ṣoju Moro/Patigi/Ẹdu to n ṣe saa kẹta bayii ati Ọnarebu Zakari Mohammed ti oun ṣoju ẹkun Baruten ati Kaiama wa lara awọn to dije fun tikẹẹti ipo gomina.

Ọnarebu Razaq Atunwa toun n ṣoju Ilọrin West ati Asa ni wọn yan gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.