Akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun fẹgbẹ oṣelu APC silẹ

Spread the love

Ọgbẹni Moshood Ọlalekan Adeoti ti i ṣe akọwe ijọba ipinlẹ Ọṣun ti kọwe fi ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress silẹ. Ninu lẹta kan ti Moshood kọ si alaga wọọdu rẹ, iyẹn wọọdu kejila, to wa ni ijọba ibilẹ Iwo, nipinlẹ Ọṣun, lọjọ kọkanlelogun, oṣu yii, ni ọkunrin naa ti ni oun ti fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, ṣugbọn oun ti pinnu lati ṣiṣẹ sin ipinlẹ oun ni gbogbo ọna ti awọn araalu ba ti ri i pe oun yoo wulo fun wọn. Iwadii wa fidi ẹ mulẹ pe lọjọ Aje, Mọnde, ana ni ọkunrin oloṣelu naa mori le sẹkiteriati ẹgbẹ oṣelu ADP, eyi ti ko jinna si ti ẹgbẹ oṣelu PDP l’Oṣogbo, ti ogunlọgọ awọn ololufẹ rẹ si tẹle e.

Ariwo, ‘Sheu! Sheu!’, ti i ṣe inagijẹ rẹ ni awọn ololufẹ rẹ n pa bo ṣe n wọ inu ọgba sẹkiteriati naa, ireti si wa pe inu ẹgbẹ oṣelu yii ni yoo ti dupo.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja, ni Adeoti yi ipinnu rẹ lati dije-dupo abẹle fun ẹni to maa ṣoju ẹgbẹ APC nibi eto idibo gomina l’Ọṣun pada, o ni oun ko ni i ba wọn kopa ninu rẹ. Ẹsun to fi kan awọn adari ẹgbẹ naa ni pe wọn ṣe magomago lati fi yi agbekalẹ eto idibo naa, eyi ti yoo fi mu un rọrun fun ọkan ninu awọn oludije naa, Ọgbẹni Gboyega Oyetọla lati jawe olubori.

 

 

(41)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.