Akojọpọ Ẹgbẹ Ọmọ Naijiria (CNM) ti Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ jẹ adari fun ni kawọn ọmọ Naijiria bẹru ijọba Buhari tori awọn onijẹkujẹ oṣiṣẹ aabo lo wa ninu ijọba ẹ.

Spread the love

Agbẹnusọ CNM, Ọgbẹni Akin Ọṣuntokun, sọrọ yii lati fi fesi si ọrọ awọn ọga oṣiṣẹ alaabo ti wọn ni awọn ẹgbẹ kan n pete ati da ibo ọdun 2019 ru. Ọṣuntokun ni wọn kan n fẹẹ fi ọrọ yii ko ọkan awọn araalu soke lasan ni, bo ba jẹ ootọ ni wọn ri nnkan to jọ bẹẹ ti wọn si ni ẹri daju lọwọ, ṣebi o yẹ ki wọn o lọọ gbe awọn ti wọn n gbimọ ati huwa ibajẹ yii ni amọ nigba to jẹ pe ko si ootọ ninu ọrọ wọn, oun ti wọn o maa sọ naa niyẹn.

Ọṣuntokun tẹsiwaju pe ijọba Buhari gan-an lo yẹ ka bẹru pe ki wọn ma da nnkan ru lọdun 2019 tori awọn funra wọn mọ pe awọn ti kuna lati mu adehun ti wọn ṣe fun araalu ṣẹ. O ni bi ọrọ ti Ajagunfẹyinti Danjuma sọ ba jẹ ootọ pe awọn to yẹ ki wọn jẹ oludaabo fun wa gan-an ni wọn sọra wọn di apaayn le wa lori, awọn gan-an lo yẹ karaalu bẹru.

 

(12)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.