Akintọla kan Okpara labuku, o ni alasọkojẹ eeyan kan lolori ẹgbẹ NCNC naa

Spread the love

Awọn oloṣelu ki i mu iru ọrọ bayii ni kekere rara. Ọrọ irin-ajo ti Michael Okpara, olori ẹgbẹ NCNC, n ṣe si ilẹ Yoruba, iyẹn gbogbo Western Region ni. Ṣe wọn ti ni ko ma wa, o si ti wa, awọn ọrọ to waa n sọ kaakiri yii, agaga awọn ohun to sọ nile Awolọwọ ki i ṣe eyi ti awọn ijọba West labẹ Oloye Ladoke Akintọla le mu mọra pẹẹ, ọrọ naa ṣi n ka gbogbo ọmọ ẹgbẹ Ọlọwọ, NNDP, ẹgbẹ Dẹmọ, lara gan-an ni. Ohun to waa dun wọn ju ni bi awọn ero ti ṣe n tẹle ọkunrin naa kaakiri, o ya wọn lẹnu ju pe awọn ero to to bẹẹ yẹn le wa lẹyin awọn ẹgbẹ mejeeji yii, iyẹn NCNC ati Action Group (AG), nitori wọn mọ pe ohun ti eleyii tumọ si ni pe bi ibo ba ṣẹlẹ, ti wọn ba pe awọn eeyan jade pe ki wọn waa dibo, o ṣee ṣe ki awọn ẹgbẹ yii ni ibo ti yoo pọ ju ti ẹgbẹ Dẹmọ lọ. Inu Akintọla ko dun si Okpara rara, ko fẹ ile awọn Awolọwọ to lọ yẹn.
Iyẹn nikan tun kọ, ni ọjọ naa gan-an, bi Okpara ti n kuro nile awọn Awolọwọ, ilu Ọyọ lo gba lọ taara, iyanu si ni pe awọn ero ti wọn ti duro si Oke-Bọlagun de e ko ṣee ka tan ni, bi awọn mi-in si ti gbọ pe o wọlu bayii ni wọn ti tẹle mọto rẹ, wọn si n ba a rin titi to fi de ibi to n lọ. Awọn ọmọ ẹgbẹ AG ati NCNC ni wọn jọ lọọ pade rẹ, yatọ si awọn ọmọ NCNC ti wọn ti di ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ. Lọtun-un losi, ariwo “Mike Power!” ariwo “Awo!” lawọn eeyan naa n pa. Bẹẹ ni wọn n sare tẹle mọto naa, ti wọn o si sinmi nigba kan. Okpara ti kilọ fun dẹrẹba pe ki oun naa ma sare mọ, mọto naa si n ba irin awọn eeyan dọgba, pẹlu awọn mọto aṣaaju ẹgbẹ NCNC mi-in ti wọn jọ n lọ. Bẹẹ lawọn mọto naa n rọra rin, eyi si fun awọn eeyan lanfaani lati ri Okpara daadaa, bẹẹ lo n juwọ si wọn, to n rẹrin-in si wọn, ti awọn naa si n juwọ si i.
Ohun to kọ sọ gbara nigba to gun ori aga lati sọrọ ni pe, ki gbogbo awọn ero to wa naa lọọ ba awọn ọmọ NCNC ti wọn ti lọ sinu Ẹgbẹ Dẹmọ, ki wọn si sọ pe ki wọn maa dari bọ wale, awọn ti dariji wọn, awọn o si fẹ ki iya kankan jẹ wọn nitori ko sohun ti wọn fẹẹ ri gba ninu ẹgbẹ Dẹmọ ti wọn lọ. O ni awọn ti wọn fẹẹ balu jẹ ni wọn wa ninu Dẹmọ, awọn alainisuuru atawọn afagidijaye, o ni ẹni to ba gbọn bayii ko tete sọ kalẹ ninu mọto wọn ki wọn too fi mọto ẹgbẹ naa ni asidẹnti, ti wọn yoo si ṣe gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ leṣe buruku. Okpara ni kawọn naa wo ero bo ti to ninu ẹgbẹ tiwọn, o lo da oun loju pe bi Dẹmọ ba pepade, wọn ko ni i ri ero, awọn ero to ba lọ sibẹ, nitori ijaya, tabi ki wọn ma yọ wọn niṣẹ, tabi ohun ti wọn fẹẹ gba lọwọ ijọba ni wọn ṣe lọ. Ṣugbọn awọn ti wọn waa pade oun yii, ti oun ri yii, ifẹ ni wọn fi wa.
O ni ko si ohun ti awọn n ṣe ju ki awọn tẹle ofin Naijiria lọ, awọn si ti mọ pe bi awọn ba ṣe ohun gbogbo bi ofin ti wi, iya ko ni i jẹ ẹni kan. Ṣugbọn awọn ti wọn wa ninu Dẹmọ yii ko ronu bẹẹ, ironu tiwọn ni bi wọn yoo ṣe maa ko awọn eeyan lẹru, ti wọn yoo si joye kọlọkọlọ laarin awọn ọmọ orilẹ-ede Naijiria gbogbo, ti wọn yoo sọ wọn di ẹran, ti wọn yoo si maa pa wọn jẹ. “Gbogbo ohun ti wọn n sọ yẹn, ẹ ma feti si tiwọn o, ko sẹni kan to le da emi duro, ko sẹni kan to le da ẹyin naa duro, pe ki ẹ ma rin si ibikibi to ba wu yin ni orilẹ-ede Naijiria, nitori ọmọ Naijiria ni gbogbo wa, ofin si sọ fun wa pe a ni ominira lati ṣe ohunkohun ti a ba fẹ nibikibi nilẹ yii ti ko sẹni to le mu wa si i.” Bo ti sọ bẹẹ ni Ọyọ ree, to si lọ si awọn ilu to wa lagbegbe naa, ko too pada wa si Ibadan pada, to si mura fun irin-ajo ọjọ keji.
Iwo lo ti bẹrẹ irin-ajo naa ni ọjọ keji, o si kuro nibẹ, o de Ẹdẹ, Ẹdẹ yii lo si ba de Oṣogbo. Bẹẹ ni ohun to n fa ijaya fun awọn Akinọla ati ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ko kuro nibẹ, nitori ibi gbogbo ti ọkunrin ọmọ Ibo olori ẹgbẹ NCNC yii ba de, oun pẹlu awọn ero rẹpẹtẹ ni. Awọn ero naa yoo ti maa duro, wọn yoo si maa reti rẹ, bo ba si ti de lariwo yoo la gbogbo ilu naa ja. Ko si ohun to fa ọpọlọpọ ariwo yii ju pe awọn ẹgbẹ AG ati NCNC ni wọn jọ n ṣe e, awọn ni wọn jọ n tẹle Okpara kiri, nibi yoowu to ba si ti de, awọn ni wọn yoo rọ jade lati pade rẹ. Awọn aṣaaju ẹgbẹ AG ati NCNC naa ko gbẹyin ninu irin-ajo yii, eleyii si tubọ n ki awọn eeyan laya, bi wọn ba ti ri awọn oloṣelu nla kan ti wọn ti gbọ orukọ wọn tẹlẹ, bẹẹ ni wọn n sọ pe awọn yoo bọ ninu wahala ti ẹgbẹ Dẹmọ ko sawọn lọrun, bi ibo ba de, awọn ti rẹni tawọn yoo dibo awọn fun.
Gọngọ sọ niluu Oṣogbo. Ibẹ ni Okpara ti kede pe ko si ija kankan laarin awọn ati awọn ẹgbẹ AG mọ, o ni ija to wa laarin awọn ti pari pata, ko si ni i gberi mọ, ẹgbẹ NCNC ati AG ti dọrẹ, ọrẹ naa ni wọn yoo si jọ maa ṣe. O ni ko si ohun ti wọn tori rẹ di ọrẹ ju ki awọn le ba awọn ọta mẹkunnu ti wọn ti pọ nigboro bayii, ti wọn si ti pawọ-pọ lati fiya jẹ araalu nitori imọ-tara-wọn nikan. O ni awọn yii gan-an naa ni wọn da ija to wa laarin awọn silẹ, ṣugbọn ni bayii, ija naa ti pari, nitori awọn adarugudu silẹ naa ti lọ, gbogbo wọn ko si nitosi awọn mọ, awọn ko si le ba ara wọn ja mọ, nitori ọrọ awọn ye ara awọn daadaa. O ni ko sohun ti gbogbo ọmọ ilu Oṣogbo yoo ṣe mọ ju ki wọn gbaruku ti ẹgbẹ AG ati NCNC lọ, bi wọn ba ti ṣe bẹẹ ni awọn yoo ni agbara to lati le awọn ọta ilu yii lọ.
Lati teṣan reluwee ni ilu Oṣogbo lawọn ero ti to lẹyin Okpara, awọn pupọ si to si ẹsẹ titi lati teṣan yii titi de ọna Ikirun, ni ile Kọla Balogun ti i ṣe aṣaaju ẹgbẹ NCNC lagbegbe Ọṣun. Ibẹ lọkunrin naa ti n duro de e, oun ati awọn aṣaaju ẹgbẹ wọn ni gbogbo agbegbe ati awọn ero si ti lọ salalu bii omi, bẹẹ lawọn onijo ati olorin oriṣiiriṣii wa nibẹ, wọn waa ki Okpara kaabọ si ilu Oṣogbo. Ẹnu ya oun naa nigba to ri ero, ori rẹ si wu, o ni ko si ki ẹgbẹ AG ati NCNC ma kan posi Ẹgbẹ Dẹmọ lasiko ibo to n bọ, awọn yoo si sinku wọn ti wọn ko ni i gberi mọ laye. Ohun to si sọ fawọn ero gbogbo ti wọn n gbọ ọrọ lẹnu rẹ naa niyẹn, pe bi wọn ba ti awọn lẹyin, awọn yoo rẹyin Ẹgbẹ Dẹmọ. O ni Dẹmọ ki i ṣe ẹgbẹ kan to lẹsẹ nilẹ, nitori pe Akintọla ṣejọba, wọn si n ri owo ijọba na ni gbogbo ohun ti wọn n ṣe.
Awọn ẹgbẹ Action Group lẹyin oun naa waa sọrọ nibẹ, wọn ni awọn Ẹgbẹ Dẹmọ ti sọ ile Yoruba ti agbegbe naa di nnkan mi-in, nitori jagidijagan ati ipanle ni wọn fi n ṣe aye, ko si si ojumọ kan ti wọn ko ni i ṣe eeyan kan leṣe ninu awọn ọmọ ẹgbẹ awọn. Wọn ni ko si bi awọn ti ṣe le kapa aburu ti wọn n ṣe bi ẹgbẹ AG ati NCNC ko ba ṣiṣẹ pọ, ṣugbọn nigba ti awọn ti dọrẹ, ti awọn si gba lati jọ ṣe iṣẹ, bi wọn ba gbe e wa ni gbigbona, awọn yoo gbe e fun wọn, bi wọn si gbe e wa ni tutu, wọn yoo ba awọn nibẹ, ohun to daju ni pe awọn lawọn yoo rẹyin wọn. Bi aṣaaju awọn AG agbegbe naa ti n sọrọ yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ n fo soke lau lau, inu wọn dun kọja afẹnusọ. Ṣe ohun ti gbogbo eeyan ti ro ni pe ko si bi ẹgbẹ naa yoo ṣe ṣe aṣepọ, nitori Ibo ati Yoruba koriira ara wọn, wọn ni Okpara o fẹran Awolọwọ.
Ohun ti Akintọla si fi sọrọ nigba to n fesi sawọn ohun ti ọkunrin Okpara yii n sọ kaakiri awọn ibi to n lọ niyẹn. O ni ki lo n ṣe maanu naa to n fapajanu, pe ẹni kan to ba gbọn daadaa nilẹ Yoruba ko ni i tẹle Okpara tabi ko gbọ ọrọ ẹnu rẹ. O ni gbogbo ohun to n ṣe yii, bii igba ti aja rẹ pada sidii eebi rẹ ni, nitori ni gbogbo aye rẹ, lati igba to ti n ṣe oṣelu, awọn to fi gbogbo ọjọ aye rẹ ba ja ni awọn aṣaaju Action Group, ohun to si n sọ ni pe ọsan ati oru lawọn, awọn ko ni i jọ ṣe layelaye. Akintọla ni ni ọpọlọpọ igba lo jẹ niṣe ni ọkunrin yii n ba awọn ja pe awọn ko gbọdọ de ilẹ Ibo o, pe bi awọn ba de Ilẹ Ibo, oro ni yoo gbe awọn, bẹẹ naa lo n sọ pe oun ko ni i de ilẹ Yoruba lati ba awọn oloṣelu ibẹ ṣe, nitori ko si anfaani kan lara wọn. O ni njẹ ko ni i yaayan lẹnu pe ọkunrin naa lo tun n kiri ilẹ Yoruba yii.
Akintọla ni alagabagebe kan ni Okpara, alasọkojẹ eeyan kan bayii ni. O ni awọn ọmọ Yoruba ti wọn n sare tẹle e ko mọ kinni kan, awọn ti wọn fẹẹ sọ ara wọn di ẹru Ibo nitori ti wọn n wa ipo ati agbara ni. Akintọla ni ohun to si fa ija naa niyẹn, ohun to fa ija ni pe oun ko le ṣe ẹru Ibo ni toun, ojulowo ọmọ Yoruba loun. O ni nigba ti Okpara mọ pe oun fẹran Awolọwọ, ki lo de ti ko ba Awolọwọ ṣe nigba ti tọhun wa laye, to waa jẹ nigba ti o ku tan lo n kaakiri, to n sọ pe oun fẹran Awolọwọ, to waa n lọ sile rẹ lọọ muti. O ni ẹni to jẹ bo ṣe wa yẹn, o le mu ọti lori omi, bo ba si mu kinni naa yo tan, kantankantan ni yoo maa sọ. Akintọla ni Okpara n pariwo pe oun wa silẹ Yoruba, ero n tẹle oun kaakiri, o ni ṣe awọn ero niyẹn abi awọn alaimọkan, o ni ọmọ Yoruba to ba mọkan ko ni i tẹle Okpara.
O ni eyi to n ṣe yii ki i ṣe abẹwo, awọn Yoruba gidi ko si fẹran rẹ. O ni bo ba jẹ Yoruba fẹran rẹ ni, ko yẹ ko maa bẹru, ko yẹ ko maa sa kijokijo pe ẹni kan yoo ṣe oun leṣe. O ni ẹni to loun waa ṣe abẹwo, ti ọlọpaa bii ogun bii ọgbọn n tẹle e kaakiri, ẹni to n bẹru laarin awọn eeyan to ni wọn fẹran oun, o ni ṣe abẹwo niyẹn abi Ọlọrun-jẹ-a-gbadun. O ni ṣebi Sardauna naa ti wa sibi nigba kan, ti oun naa bẹ ilẹ Yoruba wo, ki lo ṣẹlẹ si i, ṣebi ko mu ọlọpaa kan dani, ko si si ibi to de ti awọn eeyan ko ti waa ki i kaabọ, nitori loootọ loootọ ni wọn fẹran Sardauna, ki i ṣe ifẹ pakaleke ti Okpara n ṣe yii jare. O ni ki lo de ti Okpara o ṣe bii Sardauna, koun naa rin ko yan bi olori ijọba ilẹ Hausa naa ti ṣe nigba to wa silẹ Yoruba lọjọsi, ki lo de to n ko ọlọpaa kiri. O ni oun gba fun Sardauna ni toun, ṣugbọn ni ti Okpara yii, alasee kan ni.
Ọrọ to sọ yii lawọn eeyan fi kọlu oun naa ṣaa o, wọn ni oun naa to n leri, to n sọrọ pe oun ko le ṣe ẹru Ibo, ninu Ibo ati Hausa, ewo lo waa daa. Wọn ni ṣebi oun naa ti sọ ara rẹ di ẹru Sardauna, to n tẹle e gọọgọọgọọ kiri, ti ọkunrin naa si ti lo o lati ba ilẹ Yoruba jẹ. Wọn ni ki Akintọla lọọ wabi kan jokoo si jare ko jẹ ki Okpara ṣe tirẹ to waa ṣe. Okpara naa ko kuku tilẹ dahun, nitori ko too kuro ni ilu Oṣogbo, awọn ara ibẹ fihan pe awọn fẹran rẹ loootọ loootọ. Odidi aṣọ-oke kan ni wọn gbe fun un, ninu eyi ti yoo ti da agbada nla, ti yoo si da danṣiki ati kẹmbẹ si i. Oun paapaa ri aṣọ-oke naa, o kan saara, o ni oun nifẹẹ si i gidigidi. Ọkunrin ayaworan agbẹgilere kan wa, Sammy Ẹdun, oun tilẹ peregede, o fi gbọọrọ jẹka, o peregede. Laarin ọjọ kan naa lo fi ya aworan Okpara, to si gbe kinni ọhun le e lọwọ niluu Oṣogbo.
Bo ti kuro ni Oṣogbo lo di Ileṣa, Ileṣa yii si ni ija ti de laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu NCNC ati awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, wọn ni awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ fẹẹ da kinni naa ru, ṣugbọn awọn ọlọpaa to tẹle Okpara lati Eko tete pana ija naa, wọn mu awọn ti wọn fẹẹ sọ irin-ajo naa di yanma-yanma. Ohun to ṣẹlẹ ni pe ọpọlọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC tẹlẹ ni wọn ti wa ninu ẹgbẹ Dẹmọ ni Ileṣa. Ko sohun to fa a ju pe aṣaaju ẹgbẹ NCNC tẹlẹ ni gomina Western Region, Oloye Ọdẹlẹyẹ Fadahunsi. Loootọ ofin sọ pe Fadahunsi ko gbọdọ ṣoṣelu, ṣugbọn bi ko tilẹ ṣe oṣelu mọ, ko ṣa ni i gbagbe ibi to ti ṣe e, nitori iyẹn lo ṣe jẹ nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ NCNC to wa ninu ijọba Akintọla di Dẹmọ, awọn ọmọ ẹyin Fadahunsi ni Ileṣa naa di Dẹmọ ni. Awọn kan ko lọ ṣaa o, awọn yii si n pe ara wọn ni ojulowo NCNC.
O ku bii maili mẹfa nijọ naa lọhun-un ti Okpara yoo wọ ilu Ileṣa ni awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ ti lọọ pade rẹ, awọn ati awọn ọmọ ẹgbẹ AG, wọn si n lu ilu ati orin loriṣiiriṣii lati ki i kaabọ si ilu wọn. Wọn ti wọ Ileṣa, wọn si ti n jo kaakiri ni tiwọn. Ṣugbọn awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ kan, iyẹn awọn ọmọ NCNC, ti wọn jo ijo ayọ tiwọn lọtọ ni agbegbe Ereguru, ni Ileṣa, ko ro ohun to ṣẹlẹ si wọn, nitori lojiji lawọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ ya bo wọn, wọn da mọto to n gbe wọn lọ duro, wọn ko ifọti olooyi bo dẹrẹba rẹ, wọn si bẹrẹ si i lu awọn to ku ni ilukulu pẹlu awọn ohun ija oloro, nija ba dija igboro. Kia lawọn mẹta ti farapa yannayanna, ti ẹnikan ṣubu ti ko le dide. Nigba naa lawọn ọlọpaa gbọ nipa ẹ, wọn si sare lọ sibi ti awọn eeyan naa wa, n ni wọn ba bẹrẹ si ṣa wọn nikọọkan, awọn meje ni wọn ri ṣa lẹsẹkẹsẹ, tọọgi ẹgbẹ Dẹmọ ni wọn n ṣe.
Iyẹn ko di ọkunrin naa lọwọ ṣaa, o ba awọn ara Ileṣa sọrọ, awọn ero ko si wọn lẹyin rẹ nigba kan. Lẹyin naa lo kọja lọ si Ileefẹ, oun funra rẹ si sọrọ iyanu ni niluu naa. O ni o ya oun lẹnu pe awọn ero rọ jade to bẹẹ yẹn lati pade oun, nigba ti oun funra rẹ gbọ ti wọn n kilọ fawọn ọmọ Ileefẹ pe wọn ko gbọdọ jade sita lati waa ba oun o, nitori oun ko ro rere ro wọn, ọta gbogbo Yoruba loun. Ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, ọmọ Ileefẹ ni Oloye Rẹmi Fani-Kayọde ti i ṣe igbakeji Akintọla, oun o si faaye awada silẹ ninu oṣelu tirẹ, ẹni ti o ba ti ba wọn ṣe ki wọn ṣe e bii ọṣẹ ti i ṣoju ni. Nitori bẹẹ lo ṣe funra ẹ kilọ fawọn ọmọ Ifẹ pe kẹnikẹni ma jade lọọ pade Okpara, pe ṣe wọn mọ pe NCNC loun naa tẹlẹ, ṣugbọn oun ko ba wọn ṣe mọ.
Awọn eeyan pupọ ko da a lohun, ṣe bi ọrọ oṣelu ti ri niyẹn. Wọn jade, wọn waa pade Okpara, o si ba wọn sọrọ ko too maa gba ibẹ lọ si Ondo. Ni Ondo naa, ero rẹpẹtẹ ni, nitori ni gbogbo adugbo yii, AG lo fẹsẹ mulẹ ju ninu awọn ẹgbẹ oṣelu gbogbo, awọn aṣaaju wọn si ti ni ki wọn jade lati waa pade Okpara. Okpara kuro l’Ondo, o pada s’Ibadan, nigba to si di ọjọ Satide, o gba Abẹokuta lọ, nibi ti wọn ti ṣe faaji nile Alaaji Dauda Adegbenro. Lọjọ naa ni awọn aṣaaju NCNC ati ti AG jọ jokoo jẹun papọ ni Abẹokuta, ti wọn si ṣe faaji laarin ara wọn. Nile Adegbenro ni o, l’Abẹokuta. Faaji ti wọn ṣe lọdọ Adegbenro yii ni wọn fi kasẹ irin-ajo naa nilẹ, ti Okpara si pada wa si Eko, to wọ baalu lọ si Enugu.
Ọrọ naa dun awọn Akintọla gan-an, wọn ko si yee bu u pe ki lọmọ alugijo n wa lọdọ awọn Yoruba, ko jokoo si ilu rẹ ko yee fori ara ẹ wewu kiri. Wọn tilẹ ni bo pẹ bo ya, yoo jiya gbogbo ohun to ṣe yii, awọn yoo wa ibi kan tawọn yoo ti mu un fun un, nigba naa ni yoo too mọ pe oun ti daran lọwọ awọn ọmọ Dẹmọ. Ṣugbọn wọn ko ti i ri aaye lati ṣe bẹẹ, nitori wahala ti bẹ silẹ ni gbogbo Naijiria, awọn oṣiṣẹ ijọba ti daṣẹ silẹ, gbogbo ọrọ-aje dẹnukọlẹ, rogbodiyan pọ niluu, ijọba Balewa si rogo lọwọ awọn oniṣẹ-ọba gbogbo. Ọrọ naa le diẹ o, ẹ maa ka bo ṣe jẹ lọsẹ to n bọ

(33)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.