Akintọla fẹẹ pa Adegbenro lẹnu mọ, ṣugbọn kinni ọhun ko bọ si i

Spread the love

Kinni kan ni o, bi eeyan ba n kọrin ti ko dun, tọhun naa yoo kuku maa fi eti ara rẹ gbọ ọ. Ni ti Oloye Samuel Ladoke Akintọla, olori ijọba Western Region, oun naa mọ pe ootọ ni awọn aṣofin ẹgbẹ Action Group (AG), sọ jade lẹnu. Ṣe oun naa kuku jokoo si ile-igbimọ aṣofin, oju rẹ si ni aṣofin A. O. Ọṣitẹlu ti n to gbogbo ẹṣẹ oun ati awọn minisita rẹ lẹsẹẹsẹ. O gbọ gbogbo ọrọ naa, o si mọ pe bi asọdun diẹdiẹ ba wa nibẹ nikan lo ku, ṣugbọn ni ti ojulowo awọn ọrọ naa, ododo pọnnbele ni. Akintọla si tun mọ pe gbogbo bi Nathaniel Adedamọla Kotoye ti i ṣe alukoro fun ẹgbẹ Dẹmọ ti n jo lọ to n jo bọ, to n sọrọ didun to da bii igba to fi oyin si ete rẹ, oun naa mọ pe irọ lo n pa, ọrọ ti ko mọdi lo n da si, ohun ti ko ṣẹlẹ loju rẹ lo n fẹnu si ni. Ṣugbọn oloṣelu ki i jẹwọ iru ọrọ bẹẹ, ki i tilẹ i ṣe lasiko ti oju ogun le ni West yii.

Nitori bẹẹ, nigba ti Kotoye ti dabaa pe ki wọn dibo, ti awọn aṣofin ẹgbẹ Dẹmọ si fi ibo bori awọn aṣofin AG ati ti NCNC nitori wọn pọ ju wọn lọ, niṣe ni Akintọla naa dide sọrọ, o ni o ya oun lẹnu pe bayii lawọn eeyan oun ṣe fẹran oun to, bayii ni awọn aṣofin Western Region ṣe laiki oun bi oyinbo ti laiki siga mimu. Ṣe awọn aṣofin kuku ti dibo bayii, wọn ni Akintọla lawọn fẹ, Kotoye si ti sọ pe “Ọlọla julọ” ni, iyẹn ni pe oun ni olori alagbara ni West, ko tun si aja ti yoo dubuu ẹkun, afi aja to ba fẹẹ fẹjẹ wẹ nikan ni. O kan jẹ pe nisalẹ idodo, ninu Akintọla lọhun-un, oun mọ pe ejo ti wọn pa ti wọn ko bẹ lori lọrọ ibo ti wọn di naa, awọn kinni kan ṣi wa ti oun gbọdọ ṣe bi oun ko ba fẹ ki ejo naa tun gberi, nitori o mọ pe awọn ọmọ ẹgbẹ AG ko ni i gba, paapaa Dauda Adegbenro ti i ṣe olori wọn.

Nitori bẹẹ, nigba ti ọrọ kan Akintọla funra rẹ lati sọ, ohun to sọ fun awọn aṣofin yatọ si ohun ti awọn mi-in to wa nile-igbimọ naa ro pe yoo sọ. Ẹbẹ l’Akintọla n bẹ, o loun ko japanta rara ni. Olori ijọba Western Region naa sọ bayii pe, “Ẹ wo o, gbogbo ọrọ ti ẹ n sọ lati aarọ wa yii, ti mo ba ni ko toju su mi, irọ ni mo n pa. Ọpọlọpọ igba ni mo ti beere lọkan ara mi pe ki la n ba ara wa ja si, ki lo n faja, ki la n wa iṣubu ara wa si, nigba to jẹ ọmọọya kan naa ni wa, Yoruba kan naa ṣa ni gbogbo wa. Ko dara ko jẹ awa Yoruba ni a oo maa ṣe ara wa bayii, ti a oo maa da yẹyẹ ara wa silẹ fun awọn mi-in ri, nitori bi a ba n ṣe bẹẹ, ko si ki awọn araata ma maa fabuku kan wa, a ko si ni i niyi loju wọn nibikibi. Ko si idi ti a fi gbọdọ maa ba ara wa ja ija ajadiju, ko si idi ti a fi gbọdọ maa lepa ara wa.

“Ẹ wo o, ẹbẹ lemi waa bẹ yin o, paapaa awa ta a wa nile-igbimọ aṣofin yii, pe ka mọ pe aṣofin gbogbo Western Region ni wa, aṣoju gbogbo Yoruba ni wa, a ko si gbọdọ huwa ti yoo ta abuku fun Yoruba nibi kan. Ile-igbimọ aṣofin ti a wa yii, ọna ti a le fi maa jiroro nibẹ ti yoo ṣe anfaani fun awọn eeyan wa la gbọdọ maa ṣe, a ko gbọdọ maa ṣe ohun kan ti yoo mu iyapa wa laarin wa, tabi laarin awọn eeyan wa nibikibi. Ohun ti a n sọ nibi yii, ọrọ owo ti a fẹẹ na ni, idagbasoke ilu ati ti awọn eeyan wa ni a fẹẹ tori rẹ na an, n ko si ni i fẹ ka fi ọrọ ija ṣaaju tabi gbẹyin ẹ, ko sẹni to jare, tabi to jẹbi ninu wa, gbogbo wa ni ọga nla laaye ara wa, gbogbo wa si ni eeyan pataki ni adugbo wa. Ẹ jẹ ka lo ipo wa gẹgẹ bo ti tọ fun ilọsiwaju awọn eeyan, ẹbẹ ti mo n bẹ gbogbo wa niyẹn o. Ẹ jọwọ, ẹ ma binu mọ!”

Ṣugbọn oku ọdun mẹta kuro ni alejo saare, araata ki i ṣeeyan araale ẹni, tabi ẹni mọ ni ni i ṣe ni ni. Ninu awọn to jokoo sile-igbimọ naa, boya ni ẹni kan wa laarin wọn to tun mọ Ladoke Akintọla daadaa ju Dauda Adegbenro lọ. O mọ ọn gan-an ni. Adegbenro naa si ree, oun naa ki i ṣe eeyan rirọ, eyi ti oun ko ni ni ti ẹnu didun, tabi ka mọ bi a oo ṣe fọrọ gbeeyan jokoo bii ti Akintọla, oun naa ni kinni kan ninu agidi. Ṣe ara Owu ni, a-wi-i-mẹnu-kuro si ni ti Owu. Bi Adegbenro ba ti sọ pe, “N o gba un!”, titi ti Bela yoo fi fọn fere rẹ, ọkunrin naa ko ni i gba lo wi yẹn. Bo ti wu ki wọn sọ ọrọ didun fun un to, bo ti wu ki wọn gbe oriṣiiriṣii ẹbun kalẹ fun un to, ọrọ kan naa ti yoo maa tẹnu mọ ni “N o gba un!” ko si ni i gba titi, afi bi ọrọ naa ba fori sọ ibi to yẹ ko fori sọ, tabi ti wọn ba wa ọgbọn mi-in fi da a jokoo ti ko le sọrọ mọ.

Nitori pe oun mọ Akintọla daadaa bayii, oun naa lo dide nile-igbimọ lẹyin ti Akintọla ti wi gbogbo ohun ti yoo wi tan. “Ọrẹ mi ni Họnọrebu SLA, mo mọ ọn daadaa.”  Bi Adegbenro ṣe bẹrẹ ọrọ rẹ niwaju awọn aṣofin to ku niyi, lẹyin to ti tọrọ aaye lati sọrọ lọwọ alaga ile-igbimọ ọhun, Ọmọọba Adeleke Adedoyin. O sọrọ siwaju bayii pe, “Loootọ Ogbomọṣọ ni Akintọla, ṣugbọn Ọyọ ni, Ọyọ Ayọmọọlẹ! Tabi ki n ni Ọyọ loṣoo, inu ẹ dide. Ọtọ ni ohun to wa ninu SLA, ṣugbọn ọtọ ni ohun ti ẹ maa maa gbọ lẹnu rẹ, bẹẹ ni oju rẹ ko ni i tori ẹ yipada. SLA lo duro to n bẹ gbogbo wa yii, ṣugbọn njẹ ẹyin aṣofin ti ẹ wa nibi gba ọrọ ti Họnọrebu Akintọla n sọ gbọ bayii bi?”

Niṣe ni awọn aṣofin ẹgbẹ Dẹmọ pariwo pe, “Yes! Yes! Yes!” awọn gba a gbọ, ṣugbọn awọn aṣofin ti ẹgbẹ AG, ati awọn ti NCNC, pariwo lohun rara, koda, wọn tun fọwọ gba teburu, wọn n sọ pe, “No! No! No!” awọn ko gba a gbọ rara. Adegbenro waa ṣalaye fun wọn pe ẹni to ba gbọn daadaa, ti ọrọ to wa nilẹ yii ba si ye, ko ma gba Akintọla gbọ o. O ni idi ni pe ẹbẹ to n bẹ yẹn ki i ṣe ohun to wa ninu rẹ, ere lo ka ẹdun mọlẹ to di ọbọ ni, bi ọwọ Akintọla ba tẹ ohun to n wa, ọtọ ni orin ti yoo maa kọ lẹnu. O ni ko sohun meji ti olori ijọba West naa n wa ju ki awọn fi ọwọ si iwe isanwo to gbe wa lọ, bi ọwọ rẹ ba ti ba iwe isanwo naa, ti awọn aṣofin ti fọwọ si i ko maa nawo lọ, ika kan ko ni i wọ ọ nidii mọ, ko si si apa aṣofin ti yoo ka a mọ ninu gbogbo awọn. Adegbenro ni gbogbo ọrọ ti awọn sọ lo wa nilẹ yii, Akintọla ko fesi si i, ẹbẹ lo n bẹ.

Adegbenro fẹ ki Akintọla fẹnu ara rẹ sọ ọ pe ṣe loootọ lo fun awọn lọọya ati adajọ ti wọn ṣe bi wọn ti da Ọbafẹmi Awolọwọ ti i ṣe olori ẹgbẹ AG lẹbi, ti wọn si pada sọ ọ sẹwọn, lowo. Adegbenro ni ki Akintọla fẹnu ara ẹ sọ boya ootọ loun atawọn minisita ẹ n lo owo, irinṣẹ ati awọn oṣiṣẹ ijọba lati fi ṣe iṣẹ tara wọn. O ni gbogbo ọrọ bantabanta yii lo wa nilẹ, ṣugbọn kaka ki Akintọla wi kinni kan, ẹbẹ lo ni oun n bẹ. Bi eeyan ba ṣa n bẹbẹ, yoo jẹ pe o mọ idi ẹṣẹ to ṣẹ, o si jẹwọ, lẹyin naa o tuuba, igba yẹn ni yoo ṣẹṣẹ maa bẹbẹ, kawọn eeyan le mọ boya wọn aa foriji i tabi wọn ko ni i foriji i. Ṣugbọn wọn fẹsun kan eeyan, wọn ni o jale, o dide, o ni ki wọn ma binu, o ni ẹbẹ loun waa bẹ. Ṣe o jale ni tabi ko jale, ṣebi yoo kọkọ sọ bẹẹ naa, awọn eeyan yoo si le mọ eyi to jẹ ododo, Adegbenro ni iyẹn ni ẹbẹ ti Akintọla n bẹ ṣe n ṣe oun ni kayeefi.

Olori awọn aṣofin ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ AG nile-igbimọ yii sọ pe bo ba jẹ ti pe wọn n lo nnkan ijọba lati fi ṣe iṣẹ tara wọn, oun mọ daadaa pe loootọ niyẹn. Lo ba ni oun fẹẹ tu aṣiri kan bayii, ki gbogbo awọn aṣofin to wa nibẹ waa gbọ. Adegbenro ni iwa kan wa lọwọ Akintọla, iwa naa si ni pe lati ọjọ to ti gori oye, igbakigba to ba n lọ sibi kampeeni, mọto ijọba, owo ijọba, ati awọn oṣiṣẹ ijọba ni yoo ko lọ. O ni eleyii lodi sofin, ko si si oloṣelu to ba ṣe iru rẹ ti wọn ko ni i fi ofin de, nitori ofin ti awọn n lo ṣalaye rẹ pe ẹnikẹni ko gbọdọ lo owo tabi mọto tabi irinṣẹ tabi oṣiṣẹ ijọba kan lati fi ṣeto kampeeni fun ibo tirẹ, owo tirẹ tabi ti ẹgbẹ oṣelu rẹ lo gbọdọ na lati fi ṣe ohunkohun to ba fẹẹ ṣe. Adegbenro ni oloṣelu ti wọn ba gba mu to n ṣe bẹẹ, yoo padanu ipo to ba n wa ati awọn nnkan mi-in gbogbo.

Ṣugbọn ọgbọn ni Akintọla n da, Adegbenro si ni ọgbọn ti ọkunrin oloṣelu olori ijọba West naa n da loun fẹẹ sọ fun wọn. O ni bi Akintọla yoo ba lọ sibi ipolongo rẹ ni ilu kan, ko jẹ sọ pe ipolongo loun n lọọ ṣe, yoo ni gẹgẹ bii olori ijọba, oun n lọọ ṣe abẹwo si Ileṣa, tabi Ijẹbu, tabi Ọwọ, tabi Akurẹ, bo si ṣe Ondo tabi Abẹokuta ni. Yoo ni oun fẹẹ lọọ ki awọn ọba nibẹ, oun si fẹẹ wo bi iṣẹ idagbasoke ṣe n lọ si. Ohun ti yoo kọ sinu iwe ijọba niyẹn, bo tilẹ jẹ pe awọn eeyan rẹ yoo ti sọ yika pe ọga awọn n bọ waa ṣe kampeeni lọdọ awọn, ti kaluku ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ yoo si ti mura silẹ de e, ti awọn mi-in le da ankara lati lọọ fi pade rẹ. Adegbenro ni lati ọjọ ti oun ti mọ Akintọla, owo ilu lo n na, mọto ijọba lo n gun, awọn oṣiṣẹ ijọba lo n lo lati fi ṣe eto idibo ati iplongo rẹ, bẹẹ irọ ni yoo pa sinu iwe fawọn to ba fẹẹ yẹwe wo.

Ẹrin lawọn aṣofin gbogbo bu si, nitori wọn mọ pe ẹsun ti Adegbenro fi kan Akintọla yii, ootọ pọnnbele ni. Ṣugbọn ki i ṣe Akintọla nikan lo n ṣe bẹẹ, ọpọlọpọ oloṣelu to ba wa nipo agbara ni, iyẹn ni wọn ko ṣe le fi gbogbo ẹnu bu u, bo tilẹ jẹ pe iwa arufin ni. Adegbenro ni awọn ko le gba ẹbẹ ti Akintọla n bẹ awọn yii, nitori ko sọ ootọ fawọn, bo ba kọkọ jẹwọ awọn ẹsun ti wọn fi kan an, to si sọ bi ọrọ ti ri, awọn yoo gba ẹbẹ rẹ wọle, nigba naa ni alaafia to si wi yoo wa laarin awọn aṣofin. Ṣugbọn ki awọn ọmọ ijọ maa ru, ki alufaa maa sanra; ki lemọọmu maa yọkun, ki awọn ọmọ kewu gbẹ toritori, ki awọn si sọ gbogbo eleyii sita ko jẹ ẹbẹ lasan ni yoo ti idi rẹ yọ, iyẹn ko le bọ si i. Ṣugbọn nitori ki nnkan ma bajẹ, awọn aṣofin yoo fọwọ si iwe owo to fẹẹ na, ko maa nawo ẹ lọ, ṣugbọn ko mura lati ṣalaye lọjọ iwaju.

Ẹni ti ko ba ni i jẹ ka jẹun yo, oluwarẹ yoo kọ tirẹ mọ ọka ni, eyi yoo jẹ pe bi oluwarẹ ba n jẹun tirẹ lọ, tọhun naa yoo maa jẹun tirẹ, ko si ni i le di ni lọwọ. Ohun ti Akintọla ṣe fun Adegbenro niyẹn. O pe awọn ara rẹ jọ pe bi awọn yoo ba gbadun aye awọn, ti awọn yoo si gbadun ijọba yii, afi ki awọn gbe ohun to tọ si Adegbenro fun un, bi bẹẹ kọ, ko ni i jẹ ki awọn sinmi. Kia lawọn eeyan Akintọla ati awọn ti wọn jọ n ṣejọba pẹlu awọn aṣaaju ẹgbẹ rẹ gba si i lẹnu, ṣe awọn naa mọ ohun to tọ si Adegbenro ti wọn ko fun un, wọn si sọ fun olori ijọba West naa pe ki wọn tete fun Adegbenro ni ohun to tọ si i yii, ko ma di pe wahala naa yoo maa pọ si i o. Ṣe ọwọ Akintọla si ni iṣu wa, ọwọ rẹ naa tun ni ọbẹ wa, oun ni olori ijọba, oun naa si ni olori ẹgbẹ Dẹmọ, ẹgbẹ naa lo si ni awọn aṣofin to pọ julọ nile-igbimọ, nitori rẹ lo si ṣe rọrun lati fun Adegbenro ni ohun to tọ si i.

Ki lo tọ si Adegbenro? Ipo olori ẹgbẹ alatako lo tọ si Adegbenro, nitori lẹyin ẹgbẹ Dẹmọ to n ṣejọba, ẹgbẹ rẹ lo tun pọ julọ, iyẹn AG, ninu ile-igbimọ aṣofin yii. Tẹlẹtẹlẹ, nigba ti ẹgbẹ AG n ṣejọba, awọn ni wọn ni awọn ọmọ ile-igbimọ to pọ ju, ẹgbẹ NCNC si lo ni ọmọ ẹgbẹ to tun pọ tẹle wọn. Eyi ni Rẹmi Fani-Kayode ṣe jẹ olori ẹgbẹ alatako, ipo naa lo si lo lati fi ba Akintọla ṣe adehun lẹyin to kuro ninu ẹgbẹ AG, to si da ẹgbẹ oṣelu tirẹ silẹ, iyẹn ẹgbẹ UPP. Nigba ti ẹgbẹ UPP ati NCNC n ṣejọba, ẹgbẹ NCNC ni awọn aṣofin tirẹ pọ ju, nitori awọn aṣofin ti AG ti pin si meji, awọn kan ti lọ si Dẹmọ, awọn kan si wa ni AG. Eyi ko jẹ ki Akintọla to n ṣejọba le gba pe AG ni ẹgbẹ alatako, wọn ni awọn ni awọn tẹle NCNC, awọn ọmọ ẹgbẹ awọn ṣi n bọ waa pọ ju ti AG lọ to ba ya. Eyi ni wọn ko ṣe gbe ipo olori ẹgbẹ alatako fun Adegbenro.

Igba ti ọrọ waa ri bo ti ri yii, ti Akintọla ati Fani-Kayọde fi ọrọ didun, owo ati ipo oriṣiiriṣii tan ọpọ awọn aṣofin NCNC, gbogbo wọn si rọ kuro lọ sinu ẹgbẹ oṣelu tuntun ti wọn pe ni NNDP, ẹgbẹ Ọlọwọ, iyẹn Ẹgbẹ Dẹmọ, awọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ NCNC to ku ko to nnkan rara, ẹgbẹ AG si ni aṣofin to ju wọn lọ. Ṣugbọn kaka ki ijọba fọwọ si i, ki wọn si kede Adegbenro gẹgẹ bii olori ẹgbẹ alatako, awọn Akintọla ni eebu to n bu ijọba ti pọ ju, wọn ni ọta ijọba ni, ko wa nipo ẹ, awọn ko ni i fọwọ si i fun un. Bẹẹ bi eeyan ba jẹ olori ẹgbẹ alatako nigba naa, ọpọ awọn nnkan lo tọ soun naa bii ile ọfẹ, mọto ọfẹ, owo oṣu ati awọn nnkan mi-in bẹẹ bẹẹ lọ. Bo tilẹ jẹ pe Adegbenro ko jampata ọrọ naa, sibẹ, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu rẹ n binu, awọn ti wọn si mọ idi ọrọ n sọ pe ohun ti Akintọla n ṣe ko dara. Ṣugbọn ko dahun, o kọyin si Adegbenro.

Aṣiri buruku ti ẹgbẹ AG tu nile-igbimọ aṣofin yii, ati awọn ohun ti wọn fi oju Akintọla ri ki wọn too fi ọwọ si iwe inawo rẹ lo jẹ ko tete ronu piwada, lo ba kede ni ogunjọ, oṣu kẹrin, ọdun 1964, o ni ijọba ti fọwọ si i bayii pe Alaaji Dauda Adegbenro ni olori ẹgbẹ oṣelu alatako nile-igbimọ aṣofin Western Region. Owo oṣu rẹ yoo jẹ ẹgbẹrun kan ataabọ owo Pọn-un (£1500) lọdun, bẹẹ ni yoo si maa gba gbogbo ẹtọ to ba tọ si i. Akintọla sọrọ, o ni, “Ni bayii ti ijọba mi ti foju daadaa wo olori ẹgbẹ alatako, ti a si ti fun un ni ẹtọ rẹ to tọ si i, asiko niyi fun awọn ọmọ ẹgbẹ alatako yii naa lati ṣọrẹ ijọba, ki wọn yee fi gbogbo ọjọ aye wọn ba ijọba mi ṣọta. Ki i ṣe pe mo ni ki wọn ma tako mi, tabi ijọba mi, ṣugbọn ki atako wọn da lori ootọ ati ohun to le mu ki ijọba mi ṣe daadaa si i ni, ki i ṣe atako ti yoo ba nnkan jẹ fun wa!”

Kia ni Adegbenro ti fesi, o ni ohun ko mọ nnkan kan nipa ohun ti Akintọla n sọ. O ni ko fun oun ni kinni kankan ni toun o, ẹtọ to tọ si oun lati ọdọ ijọba ni ijọba gbe le oun lọwọ, bẹẹ ni oun ko ṣe oṣelu toun nitori owo oṣu tabi owo ọdun, oun n ṣe e nitori anfaani awọn eeyan ni. Adegbenro ni bi Akintọla ba n ro pe nitori pe oun fẹẹ maa sanwo oṣu foun gẹgẹ bii olori ẹgbẹ alatako ni yoo waa fi iyẹn pa oun lẹnu mọ, ara rẹ lo tan jẹ, nitori oun ko le ṣe ki oun ma sọ bi oun ba ri, bẹẹ ni oun ko ni i ri ibi ti ijọba yii ba ti ṣebajẹ ki oun ma pariwo wọn sita. Ko si pẹ loootọ ti ija mi-in fi de o. Ija de nitori iwe iroyin tuntun ti Akintọla tun da silẹ ni, o ni iwe ti yoo maa polongo ohun ti ijọba oun ba ṣe niyẹn.

(27)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.