Akintọla 31 July 2018 AKINTỌLA BORI AWỌN ỌTA RẸ NILE IGBIMỌ AṢOFIN, IBO DIDI LO FI RẸYIN WỌN

Spread the love

Ọrọ aye yii, bo ti wa ni atete-kọọ-ṣe, bẹẹ naa lo wa nisinyii o, o si ṣee ṣe ko jẹ bẹẹ naa ni yoo wa titi aye. Nigba ti eeyan ko ba ni ẹni ninu igbimọ, koda bo ba rojọ are, ẹbi ni yoo jẹ nibẹ. Ẹni ti a ba si n fẹ ki i larun kan lara. Ohun to ṣẹlẹ lọjọ kẹrinla, oṣu kẹrin, 1964, niyi, nigba tawọn aṣofin ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ, iyẹn Nigerian National Democratic Party ti wọn tun n pe n Ẹgbẹ Ọlọwọ nigba naa fi han awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group (AG) ati NCNC pe awọn pọ ju wọn lọ nile-igbimọ aṣofin Western Region. Aṣofin I.A Ọṣitẹlu ti fẹsun kan Olori ijọba West., Prẹmia Samuel Ladoke Akintọla, ati awọn minisita rẹ pe wọn ko owo jẹ, to si fẹsun kan wọn pe wọn n fi owo ijọba tun Ẹgbẹ Dẹmọ ṣe. Aṣofin Ọla Awopeju naa ti kin ọrọ ọkunrin naa lẹyin, o ni loootọ lawọn eeyan naa kowo-jẹ, ati pe ko si ohun meji to yẹ ki Akintọla ṣe ju ko fi ijọba silẹ lọ.

Awọn mejeeji yii ti sọ tiwọn, nigba ti wọn si jokoo ni aṣofin ti wọn n pe ni Nathaniel Adedamọla Kotoye jade, bo si ti jade ni gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ tiwọn ho gee, ti wọn si morin sẹnu. Ariwo tiwọn ti wọn n pa yii rinlẹ daadaa, nitori awọn ọmọ ẹgbẹ naa pọ ju awọn ọmọ ẹgbẹ Action Group lọ. Ati pẹlu, wọn mọ Kotoye daadaa, oun ni alukoro fun ẹgbẹ Dẹmọ, wọn si mọ pe bo ba n sọrọ, awọn eeyan ti wọn ba n gbọ ọ yoo fẹrẹ le maa pọn ọn lẹnu la, nitori ẹnu rẹ dun, bẹẹ lo gboyinbo, bo si ṣe le sọ ootọ ọrọ ko ye kaluku naa lo le purọ ti yoo da ọrọ ru leti awọn to ba gbọ ọ. Oloṣelu to mọ nipa ipolongo ni. O mọ ọrọ ti yoo sọ tawọn ọta ẹgbẹ wọn yoo fi di ẹni yẹyẹ, o si mọ eyi ti yoo sọ ti yoo jẹ ki awọn eeyan maa sare tẹle ẹgbẹ tiwọn lẹyin. Ọmọ ile-igbimọ aṣofin loun naa, iyẹn lo si jẹ ki ọkan awọn ẹlẹgbẹ rẹ balẹ nigba to dide.

Kotoye wo ọtun rẹ, o si wo osi, n lo ba kọju si awọn aṣofin. O ni ohun ti oun fẹẹ sọ ni pe ki awọn aṣofin gbogbo ti wọn wa nikalẹ farabalẹ daadaa lati gbọ awọn alaye ti oun fẹẹ ṣe. O ni akọkọ ni pe ki wọn ma ka ọrọ ti Ọṣitẹlu ati ẹni keji rẹ sọ si nnkan kan o, ki wọn yiju kuro nibẹ, ki wọn ṣe bii ẹni ti ko gbọ ohun ti wọn sọ ni. O ni bi awọn naa ba wo o daadaa, wọn yoo ti ri i pe ọrọ ti awọn eeyan naa sọ ko gbeṣẹ, awawi lasan ni. O ni gbogbo iwe ti wọn ni awọn fẹẹ ko kalẹ yii, ko sẹni to raaye lati maa yẹ wọn wo, nitori o ṣee ṣe ko jẹ gbogbo iwe naa, ayederu ni wọn. Ati pe ko sẹni to raaye a n paara ile-ẹjọ, pe boya keeyan pe wọn lẹjọ pe wọn ba orukọ Ọlọla julọ, Samuel Ladoke Akintọla, jẹ, wahala leeyan yoo kan ko ara rẹ si. Ṣugbọn ibi ti awọn wa yii lawọn yoo ti mọ ẹni to n sọ ootọ ati ododo, nitori ibo lawọn yoo fi yanju ọrọ naa.

Kotoye ni ko si iwa ika kan to buru ju eyi ti awọn aṣofin mejeeji yii ṣe yii, nitori wọn kan fẹẹ ba orukọ Akintọla jẹ nile ati lẹyin odi ni. O ni ohun to yẹ ki ile-igbimọ naa yẹwo, yatọ si ọrọ palapala ti awọn yii n sọ, ni iwa ka-footọ-inu ṣejọba, ka-ṣejọba pẹlu akikanju ati imọ nla, ka-ṣejọba lai gba owo ẹyin tabi abẹtẹlẹ nibi kan, eyi ti Akintọla fi n ṣe ijọba rẹ lati igba to ti de ori aleefa. Kotoye ni ọrọ to wa nilẹ yii ko le rara, ohun tawọn eeyan n wi kaakiri aye naa lo ṣẹ mọ awọn lara ni ile-igbimọ naa. O ni ọrọ ti gbogbo eeyan n sọ nipa Yoruba ni pe, “Yoruba naa kuku lọta Yoruba!Yoruba naa lo kuku maa n fọwọ ara wọn ṣe Yoruba ẹgbẹ wọn!” O ni ọrọ naa lo ṣẹlẹ yii, nitori awọn ọmọ Yoruba lo dide ogun si Akintọla yii, bẹẹ Yoruba bii tiwọn ni Akintọla i ṣe. Kotoye pariwo, o ni, “Eleyii o daa!”

Ọkunrin naa tun n ba ọrọ rẹ lọ, o ni, “Ẹ j ka s oot r funra wa, nj a le fi ijba to wa lode yii we ijba awn gb AG nigba ti awn fi ejba. Ijba to j bi awn minisita wn ba ti l si ibi kan kuku bayii, wn yoo ṣi iye maili ti wn ba l, wn yoo waa bu kun maili naa, iyẹn ni wn yoo fi k owo lati gba lw ijba. Ko si ibi ti wn l ti wn ko ni i gbowo, koda ko j ibi ti wn ko gbe mto l ti wn fi s ara wn rin l. Iynikan k ni iwa wn ti ko daa. Abi ta lo wa nibi ninu wa ti yoo s pe oun ko m pe plọpọ owo to j ti awọn araalu lo j apo awn eeyan kan ninu gb AG ni wn n dari owo naa si, ti wn yoo maa pur tan wa j pe owo awn lawn n na, to si j owo ijba to y ki wn lo fun nnkan mi-in ni wn ti dgbn dari sapo tara wn. Bi gb AG e ri niyẹn, awa m airi wn!

“Ṣe ri orukọ awn ti wn da ti wn ni wn gba owo yn, wn o gbowo kankan. Awn eeyan nla nla il Yoruba lawn aofin lgb mi fẹẹ maa ba oruk wn j nitori r oelu. Iyn ko daa, ki la n ba oruk ara wa j fun, ki la fẹẹ ri gba ninu . e nitori r oṣelu yii naa ni. Bẹẹ, ta a ba ti yw r gan kuro, ijọba Ọlla Akintọla ti e daadaa fun il Yoruba ju gbogbo eyi ti awn ijọba to kọja l ti e. Meloo ni mo fẹẹ ka, meloo ni mo fẹẹ i ninu iṣẹ ribiribi ti akanda kunrin yii ti e fun wa. gbagbe pella wa loeto iuna-owo (bjẹẹti) to dara jul, to j gbogbo igba to ba e bjẹẹti tir, oju ni i b si, owo ko ni i le, bẹẹ ni ko ni i din, bẹẹ ni ko si ni i j gbese. Bẹẹ ba m awn mi-in to j gbogbo bjẹẹti tiwn, gbese ni wn fi n j, wn o le e ki wn e bjẹẹti ko ma pada di gbese, igba ti lla Akintla ti gbajba ni gbogbo iyẹn ti dopin.  

Tabi ti awn ba ni ki n maa s ni. lla, Oloye Akintla lo da agbara ati apnle nla pada fun awn ba wa, to j bi a ti n sr yii, ogo ati iyi awn ba il Yoruba ti pada de, nitori Akintọla ti fun wn ni t wn ati apnle to t si wn, ko si snikan to j ri wn fin m. Bẹẹ, mi o fẹẹ sr ju ni o, ilu yii naa la wa, a kuku m ohun ti ijọba gb oṣelu to l, gb AG, a m ohun ti ijba wn e fun awn ba wa, ati ohun ti wn foju wn ri nikọọkan. ebi awa naa wa nibi, oju wa lo kuku e ti wn n le awn ba mi-in danu, ti wn n gba oye lw awn mi-in, ti wn n gba agbara lw awn mi-in, ti wn si n fi iwsi ati abuku kan awn ba wa kaakiri. ugbn oloye il Yoruba nla ni Akintla, oun si m pe ni kan ki i ri ba fin, nitori arbafin lba i pa. O ti yi gbogbo eleyii pada, o ti s awn ba wa dni apnle.

“Ṣe m pe meji pere ni mo i ka ninu aeyri oloṣelu nla yii. ti gbagbe ni, ti gbagbe pe oun lo mu ki awn araalu br si i m ohun gbogbo to n l. Tltl, awn ijba wa ta a ni ko ni i j ki awn araalu m ohun to n l, wn yoo maa bo gbogbo hh ni, wn ko j s oot r fun wn, wn aa maa fi ir bo oot ml, ko sni ti yoo m bi wn ti n nawo tabi bi wn ti n ejba wn, afi bii gb awo! ugbn yin naa jade l si aarin ilu bayii, kin ni mo ti n wi! ebi yin naa n ri awn eeyan bayii, to j gbogbo wn lo n da si r to n l laarin ilu, gbogbo ohun ti ijba n e lo ye wn, ko si si owo tabi eto kan ti ijba fẹẹ e ti ko j awn araalu ni wn yoo kk gb, ti awn paapaa yoo si da si i. Ohun ti eyi mu wa ni pe ijba yii fkan araalu bal, awn araalu si ni igbkle ninu , lla Akintọla lo j ko ee e.

“Ẹyin naa m, eleyii ki i e pe mo n pur m ni kan, pe ijba ta a ni tl, eto idagbasoke gbogbo ti awn n e, awn ilu nla nikan ni wọn n e tiwn si, wn ko j de awn igberiko. Ara igberiko, awn ara abule, ko gbadun ijba wn, ijba olowo nikan lawn n e, wn ko e ti mkunnu m n. Ohun gbogbo ti wn ba fẹẹ e, bi wn ko ba ti i gbe e de ilu nla, wn ko ni i sinmi, wn ki i ranti awn ara igberiko ninu eto tiwn. Ṣugbn laye ijba lla wa, Oloye Ladoke Akintla, ẹyin ti gb iru r ri na! ebi bo e n eto idagbasoke laarin awn ilu nla yii, bẹẹ naa lo n e e laarin awn igberiko, ko si si abule kan ni Western Region yii to le s pe oun ko gbadun ijba yii, gbogbo ohun tawn ara ilu nla n gbadun lawn ara abule naa n gbadun, ko si si ohun ti lla Akintọlae si Ibadan tabi Ogbomọṣọ ti ko e si abule kereje.

Bi mo ba s gbogbo ti mi o mnuba r awn ijba ibil wa, yin naa ko ni i m oore ti lla Akintọla n e fawn eeyan yii. Ijba ibil wo lo wa ni West yii ti ko gbadun m bayii o, ko si! lla Akintọla ti ko igbadun ba gbogbo wn. Owo ti ijọba lla yii ti san fun awn ijọba ibil laarin dun yii nikan j gbta Pn-un. Owo yii ki i ṣe owo wn, bẹẹ ni ko t si wn, owo ijba West ni, lla Akintla lo si le nawo naa bo ba e f, nitori apo ijba West lo wa, awn ni wn ni in, ki ie owo awn ijba ibil yii rara. ugbọn Akintla wo wn sunsun, o fun wọn lowo yii, o ni ki wọn le fi tun gbogbo agbegbe ijọba ibil wn e, ko ma si ibi kan ti w idagbasoke ko ni i de ni gbogbo Western Region, ko si j gbogbo eeyan pata ni yoo maa jgbadun oun, ati awn ti wn dibo fun gb oun, atawn ti ko dibo fawn.

Di kekere ni mo mnu kan ninu awn iṣẹ nla nla ti lọla Samuel Ladoke Akintla ti gbe ṣe o. Bawo waa ni eniyan kan yoo e jokoo sibi kan, tabi ti yoo duro niwaju ileigbimọ yii ti yoo maa fnu abuku pe lla Akintla ati ijọba r. Bawo ni eniyan yoo e s pe lla Akintla ko e daadaa, ko sni to le s bẹẹ, afi awn abatnij, tabi awn onibaj lasan. Emi woye lla Akintọla, mo si m riri iṣẹ r, mo si m pe plọpọ awọn aofin nibi yii lo m iṣẹ rere ti lla Akintọla n e. Nitori bẹẹ ni mo e dabaa pe kaka ki a tle aba ti awn kan gbe dide pe ki a s pe ki lla Akintọla gbejba sil, emi dabaa pe ki gbogbo wa s pe, Agbdo! lla Akintla la f ko maae ijba Western Region l! Eyi ti mo s yii, aba ni, mo si f ki yin lgb mi to ku ba mi gba a wle, ka le fi pa awn ti wn fẹẹ ba ijba yii j lnu m!

Bi NAB Kotoye ti sọ bẹẹ, awọn ara rẹ ninu ẹgbẹ oloṣelu wọn ko jẹ ko jokoo ti wọn fi n pariwo pe, “O wi i re! O wi i re!” ọkunrin naa si n jupakọ luke, nitori inu oun naa dun pe awọn ẹlẹgbẹ oun gba toun. Bo tilẹ ti n jokoo ni Aṣofin Saka Layọnu ti dide, ọkan ninu awọn minisita ni, bẹẹ lo si jẹ aṣofin to nile-igbimọ, ọmọ ẹgbẹ awọn Akintọla naa ni: Ẹgbẹ Dẹmọ. Saka Layọnu ni idide ti oun dide yii, lati gbe ọrọ ti Aṣofin Kotoye sọ lẹsẹ ni. O ni koda ki eeyan jẹ ọmọ alaa-bii-di, ọrọ ti Kotoye sọ yoo ti ye e daadaa, bẹẹ ni gbogbo alaye to ṣe lo nitumọ, gbogbo ohun to si sọ leeyan le ri tọka si nipa iṣẹ rere ti ijọba to wa lode naa ti ṣe. O ni Ladoke Akintọla n ṣe bẹbẹ, ti ẹlẹgan lo ku, awọn ko si ni i jẹ ki awọn aṣofin kan jokoo lati waa fi ẹnu tẹmbẹlu iṣẹ rere ti ọkunrin naa ti ṣe, nitori bẹẹ loun ṣe dide.

Layọnu ni Akintọla ti wọn n wo yii, bii ẹni to n fiya jẹ ara rẹ lo ṣe maa n ṣiṣẹ ilu, nitori ki awọn eeyan si le gbadun ijọba rẹ ni. O ni nigba mi-in, o le ma jẹun ti yoo kan maa ba iṣẹ ilu lọ ni pẹrẹu, igba mi-in si wa ti ko ni i jade rara, to jẹ iṣẹ ni yoo maa ṣe lati aarọ titi di oru pata. O ni igba mi-in si tun wa to jẹ Akintọla le lọ si ilu bii mẹwaa papọ nijọ kan ṣoṣo, nitori o fẹẹ fi oju ara rẹ ri awọn eeyan rẹ ati bi idagbasoke ti n de adugbo wọn si ni. O ni bẹẹ ni ki i ṣe pe o ko owo kan jẹ, tabi pe o n gba owo kan lẹyin, tabi pe o n fi awọn eeyan kan gbowo bi awọn ti wọn ṣejọba ki oun too de ṣe ṣe. Layọnu naa ni oun ko le tori awijare kitọ tan lẹnu oun, oun kin aba yii lẹyin, bẹẹ ni ki i ṣe pe oun kin in lẹyin nikan, oun rọ gbogbo awọn aṣofin to ku ki wọn dibo, ki wọn fi ibo sọ pe Akintọla ni gbogbo awọn aṣofin West fẹ nile ijọba.

Bayii ni wọn dibo o. Ṣe ko si bi ọrọ yoo ti lagbara to, ibo lawọn aṣofin yoo di, ẹni ti ibo ba si gbe ṣubu, gbogbo ohun to wa ninu rẹ parẹ naa niyẹn. Nigba ti Kotoye ti ni ki wọn dibo, bi wọn ba dibo ti awọn ti wọn sọ pe awọn ko fẹ ki Akintọla maa ṣejọba lo ba pọ ju awọn ti wọn ni ko maa ṣejọba lọ, ohun kan naa lo ku si yẹn, bii igba pe aba Ọṣitẹlu ati ti Awopeju ti wọn ni ki wọn yọ Akintọla di ofin niyẹn, bo ba si ri bẹẹ, Akintọla yoo lọ dandan. Ṣugbọn bo ba jẹ ti Kotoye to fi sọ pe ki awọn dibo pe Akintọla lawọn fẹ gẹgẹ bii olori ijọba West lo wọle, Akintọla yoo maa ṣe ijọba rẹ lọ ni. N ni wọn ba dibo, ibo ti wọn si di naa ko gba ibi ti awọn ọta Akintọla fẹ lọ rara. Ṣebi awọn ọmọ ẹgbẹ Dẹmọ lo ni ero to pọ ju nile igbimọ naa, nigba ti wọn si dibo yii, mẹtalelaaadọta (53), lawọn to ni ki Akintọla maa ṣe ijọba rẹ lọ, awọn mẹtalelogun (23), pere ni wọn ni ko le ṣejọba.

Bayii ni Akintọla rẹyin ọta to rẹyin odi nile-igbimọ aṣofin. Ṣugbọn ọrọ naa ko ti i tan o, awọn aṣofin AG ati ti NCNC lawọn ko le gba, awọn yoo wa ọna mi-in lati fi mu un. Igba naa ni Akintọla funra rẹ si fi ariwo bọnu, o ni, “Ẹyin ọmọ ẹgbẹ AG, ki lẹ n ṣeyi fun!”

Ẹ maa ka a lọ lọsẹ to n bọ.

 

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.