Akintọla 05 June 2018 Ninu oṣu kẹta ọdun 1964, Awọn Yoruba ati Ibo bẹrẹ Ija ninu ẹgbẹ NCNC

Spread the love

Inu awọn ọlọpaa ko dun rara pe ẹnikẹni sọ pe ko si alaafia ni Western Region, nitori ẹ lo ṣe jẹ pe nigba ti awọn NCNC ati AG, Ẹgbẹ Ọlọpẹ, sọ bẹẹ, ibinu ni wọn fi da wọn lohun. Awọn ọlọpaa ni ko si rogbodiyan kankan lọdọ tawọn o, alaafia ni gbogbo ara Western Region wa, kaluku lo si n gbadun aye ara ẹ, ibi tawọn ti wọn n gbe igbekugbee kiri ti ri irọ ti wọn n pa pe ko si alaafia ni West, awọn nikan ni wọn mọ o. Wọn ni loootọ lawọn n ṣa awọn kan, ti awọn n mu wọn, ṣugbọn awọn ọdaran adaluru lasan ni, iya ẹṣẹ wọn ni wọn n jẹ. Awọn ko ṣi le fi wọn silẹ ki wọn maa da ilu ru, iyẹn lo ṣe da bii pe ero pọ ni sẹẹli, iyẹn ki i si i ṣe ohun ti oju ko ri ri, ẹni to ba ti ṣẹ sofin, kijọba mu un ni. Awọn eeyan gbọ ni, wọn o gba, wọn ni irọ ati ojuṣaaju lasan lawọn ọlọpaa n ṣe, wọn o sọrọ sibi tọrọ wa, awọn gan-an si n da kun iṣoro araalu ni.

Imale sọrọ ojo ku, o ni Ọlọrun ṣẹri oun. Bẹẹ lọrọ yii ri fawọn araalu ti wọn ko gba awọn ọlọpaa gbọ, nitori ko ju ọjọ keji ti wọn sọrọ lọ nigba ti TOS Benson, ọkan ninu awọn aṣaaju ẹgbẹ NCNC nilẹ Yoruba fi ariwo bọnu pe awọn kan fẹẹ pa oun. O ni ki gbogbo aye gba oun o, nitori bi wọn ṣe n wo oun yii, bi wọn ko ba mura si ọrọ oun, ko ma da bii pe oku-eeyan lo n sọrọ, nitori oun mọ ohun ti oun n sọ. O ni oun pe ọlọpaa o, oun si pe olori ijọba Naijiria ki gbogbo wọn gbọ. Njẹ ki lo de ti ọrọ naa fi ri bẹẹ, TOS Benson sọ pe oun sọrọ kan ranṣẹ sawọn Ibo ni, bẹẹ alaye lasan loun ṣe, afi bi wọn se bẹrẹ si i dẹ awọn eeyan soun, ọrọ ti wọn si n sọ fawọn eeyan kaakiri, ko si ohun meji to le mu wa foun ju iku lọ bi awọn alaṣẹ ko ba tete ba oun da si i. N lawọn eeyan ti wọn ko gbọ tẹlẹ ba n beere, wọn ni ki lo de gan-an.

Awọn Ibo ti wọn jọ wa ninu ẹgbẹ NCNC ni wọn jọ bẹrẹ ija, ọrọ naa si ti wa nilẹ to ọjọ meloo kan. Gẹgẹ bi a ṣe ti sọ tẹlẹ, ẹgbẹ NCNC ati NPC ni wọn jọ n ṣejọba apapọ, eleyii si tumọ si pe awọn ẹgbẹ mejeeji yii ni wọn yoo jọ maa yan awọn minisita, ti wọn yoo maa yan awọn alaṣẹ ileeṣẹ ijọba apapọ gbogbo. Ohun to waa ṣẹlẹ ni pe nigba ti awọn ti wọn n ṣejọba ba pin ipo kan si ọdọ awọn NCNC, awọn ọmọ Ibo ti wọn wa ninu ẹgbẹ naa yoo taari kinni naa sọdọ ara wọn, awọn ipo minisita to si la owo gidi lọ ati agbara nla ko to awọn ọmọ Yoruba lọwọ rara. Bo tilẹ jẹ pe iro gbuu ni o, ohun ti Fani-Kayọde ati awọn ti wọn kuro ninu ẹgbẹ naa ti wọn jọ da ẹgbẹ NNDP, Ẹgbẹ Dẹmọ, silẹ sọ ree o, wọn ni awọn ọmọ Ibo inu NCNC n fi Yoruba jẹun lasan ni, awọn ko si le gba ki Yoruba wa lero ẹyin, iyẹn lawọn ṣe kuro, ti awọn di Dẹmọ.

Ṣugbọn kinni kan ni awọn ijọba Akintọla igba naa ṣe, iyẹn naa ni pe wọn tu aṣiri awọn Ibo to n yan Yoruba jẹ yii, wọn si jẹ ki gbogbo aye mọ pe awọn eeyan naa ko ṣe daadaa pẹlu awọn. Awọn mẹta kan ni wọn fẹjọ sun ijọba, awọn mẹtẹẹta naa si ni Fani-Kayọde, Richard Akinjide ati Olowofoyeku. NCNC ni gbogbo wọn wa tẹlẹ ki wọn too dọmọ ẹgbẹ Dẹmọ. Awọn ni wọn sọ pe awọn Ibo n fiya jẹ Yoruba. Ileeṣẹ Reluwee ni wahala naa ti bẹrẹ, iyẹn Nigerian Railway Corporation. Ọkunrin to jẹ alaga ileeṣẹ naa, Ṣiamaanu (Chairman), ọmọ Ibo ni. Ki ọkunrin naa too de, ohun gbogbo n lọ daadaa, ṣugbọn bo ti di alaga ileeṣẹ reluwee yii lo yi awọn eto gbogbo pada, to si bẹrẹ si i ko awọn ọmọ Ibo si ipo gidi kaakiri. Ohun ti awọn Akintọla si ṣe gbe igbimọ kan dide ree, wọn fẹẹ mọ ohun ti ọkunrin alaga naa n ṣe gan-an.

Orukọ ọkunrin yii ni Doctor Chukwuemeka Ikejiani, ọkan ninu awọn ọmọlẹyin Azikiwe ni tẹlẹ ninu ẹgbẹ wọn, nigba ti iyẹn n ṣe oṣelu. Nibi ti wahala ti bẹrẹ ni pe bi ipo kan ba ti ṣi silẹ nibẹ, koda ki awọn ọmọ Yoruba ti wọn kun oju oṣuwọn pọ daadaa, ọkunrin naa yoo mọ ọgbọn ti ipo naa yoo fi bọ si ọwọ awọn ọmọ Ibo bii tirẹ, ti wọn yoo si ko awọn ọmọ Yoruba si abẹ wọn, bo tilẹ jẹ pe awọn Yoruba yii ni ọga awọn ọmọ Ibo naa tẹlẹ. Ohun to n fa wahala niyẹn o, ṣugbọn bi ọrọ naa ba ti de gbangba bayii ni ọkunrin Ibo naa ati awọn ọmọ ilu rẹ ti wọn wa nibi iṣẹ reluwee yii yoo sọ pe irọ ni, ko si ohun to jọ bẹẹ, awọn Yoruba wọnyi kan n sọ ohun ti ko ṣẹlẹ sita ni. Ohun to jẹ ki awọn Akintọla gbe igbimọ kan jade ree, igbimọ naa si wadii, ni wọn ba to gbogbo ohun ti Ikejiani n ṣe nileeṣẹ naa wa.

Akọkọ ohun ti wọn sọ ni pe, ni gẹrẹ ti wọn yan Ikejiani gẹgẹ bii Alaga ileeṣẹ Reluwee yii, aaye ṣi silẹ lati yan ẹlomiiran si ipo igbakeji ọga agba (Deputy General Manager) lọdun 1960.  Awọn eeyan mẹta lo wa nibẹ ti ipo ọga naa tọ si. Ẹni to ṣaaju, to si ju gbogbo awọn to ku lọ ni N.A Kuforiji, Assistant General Manager loun. Ẹni to tẹle e ni ipo ọga ni F.A.O Phillips, ọmọ Yoruba loun naa, ẹni to si tẹle oun yii ni J.C. Egbuna, ọmọ Ibo kan lati ilu Onitsha, nibi ti Ikejiani funra ẹ ti wa, ẹni ti ipo rẹ si kere ju tawọn meji to ku lọ. Ṣugbọn nigbẹyin, Egbuna ni Ikejiani ni ki wọn mu, o si gbe e le awọn ọga rẹ mejeeji ti wọn ti wa ṣaaju rẹ tẹlẹ lori, wọn ni oun ni General Manager tuntun. Eleyii bi awọn oṣiṣẹ reluwee yii funra wọn ninu, nitori wọn ni ohun ti ko yẹ ko ṣẹlẹ rara lọkunrin naa ṣe, lati sọ ọga di ọmọọṣẹ.

Ẹẹkeji to tun ṣẹlẹ ni pe ileeṣẹ naa fẹẹ yan ọga kekere mi-in, Principal Officer ni oye naa ti wọn fẹẹ fi awọn eeyan si, awọn ti wọn si ti wa ni ileeṣẹ naa ni wọn fẹẹ gba. Awọn ti ipo naa tọ si ni D. A. Adebiyi, ẹni ti ipo rẹ ga julọ ninu gbogbo wọn, D.A.O. Roggers lo tẹle e, lẹyin oun lo kan E.E. Ekpe, S.O. Oke ati F.M. Alade. Bi wọn ṣe tẹle ara wọn nipo awọn ọga niyẹn. Ikejiani ko tun jẹ ki wọn mu Adebiyi ati Roggers ti awọn mejeeji jẹ Yoruba, kaka bẹẹ, Ekpe to jẹ ọmọ Ibo bii tirẹ lo ni ki wọn mu, o si sọ ọ di ọga fun awọn to ku. Ọrọ yii tun dun awọn eeyan, nitori wọn mọ pe ko si ohun to de ti ko fi yẹ ki wọn gbe ipo naa fun Adebiyi, nitori oun lo kan, bẹẹ lo si kawe, to tun mọ iṣẹ naa daadaa ju ẹni ti wọn pada waa gbe e fun yii lọ. Awọn oṣiṣẹ ni bi wọn ko ba tilẹ waa gbe e fun Adebiyi, ṣebi Roggers lo yẹ ki wọn gbe e fun, ko ti i kan Ekpe yii rara.

Enu iyẹn ni wọn wa lọwọ ti ipo ọga mi-in si tun ṣi silẹ, Deputy Assisstant General Manager fun ileeṣẹ Reluwee yii kan naa. Adebiyi to du ipo laipẹ yii ati F. M. Alade tun fi orukọ wọn ranṣẹ, wọn ni bi iyẹn ko ba bọ si i, o yẹ ki eleyii bọ si i, ṣe Yoruba si lawọn mejeeji, ẹni yoowu ko ja mọ lọwọ ninu wọn, ọmọ Yoruba naa ni. Ṣugbọn wọn tun gbe ọmọ Ibo mi-in wa pe ko waa ba wọn du u, E.A. Imoukhuede, oun si jinna si wọn nipo pata, nitori ọga kekere gbaa ni. Ṣugbọn si iyalẹnu gbogbo awọn eeyan, nigba ti wọn yoo fun eeyan ni ipo naa, Imoukhuede yii lawọn Ikejiani tun mu, ṣe ọmọ Ibo bii tiwọn ni, nigba to si jẹ Ibo ni wọn fẹ ko wa nipo naa, deede ara wọn lo ṣe, agaga nigba ti wọn ti ko awọn Yoruba si i labẹ.

Wọn tun ni wọn yoo mu ẹni kan fun ipo ọga kekere, Training and Education Officer, awọn marun-un ti ipo naa si tọ si fi orukọ wọn silẹ ni bi wọn ti dagba lẹnu iṣẹ naa si ju ara wọn lọ. R.A.A Junaid lo ṣaaju awọn yii, lẹyin naa lo kan T.O. Grillo, ko too waa kan S.M.O. Denloye, A. O. Adewoyin ati A. N. Inoma. Awọn mẹrẹẹrin to ṣaaju yii, ọmọ Yoruba ni gbogbo wọn, bẹẹ naa lo jẹ pe gbogbo wọn pata yii lo ju Inoma lọ lẹnu iṣẹ, ti wọn jẹ ọga rẹ nitori awọn mọ iṣẹ naa ju u lọ, wọn si ti ṣaaju rẹ debẹ. Ṣugbọn Ikejiani tun ni ko sẹni ti wọn le mu ninu awọn mẹrẹẹrin yii, o ni Inoma ọmọ Ibo to kere julọ laarin wọn ni ki wọn mu, oun ni ki wọn si fi ṣe ọga le awọn to ku lori. Bẹẹ naa ni wọn si ṣe e, Inoma ni wọn kọwe fun gẹgẹ bii ẹni ti wọn mu fun ipo naa, wọn si gbe e lori awọn ọmọ Yoruba to wa nibẹ.

Apa kan niyẹn o. Ni apa keji to jẹ ọdọ awọn akọwe ileeṣẹ Reluwee yii, wọn tun fẹẹ gbe awọn kan nibẹ ga si ipo to ṣofo. Ipo ti wọn n wa eeyan si ni Deputy Secretary (Legal), iyẹn igbakeji akọwe ti yoo maa ri si ọrọ ofin. Ọkunrin kan to ti wa nibẹ lati ọjọ to pẹ, lọọya to mọ ofin ni, o si ti wa nipo amugbalẹgbẹẹ fun akọwe (Assistant Secretary) lati ọdun 1960. Ogeni Megwa ni. Ṣugbọn ni 1962 ni Ikejiani mu aburo tirẹ kan de, oun naa si n jẹ Ikejiani, o si jẹ akọwe kekere lọdọ ẹgbọn rẹ. Bi ipo yii ti ṣi silẹ ni Ikejiani ni aburo oun ni yoo di ipo naa mu, o si gba a kuro lọwọ ẹni to ti wa nibẹ ki aburo rẹ too de rara, ẹni to jẹ lọọya amofin, to si ti mọ ohun ti wọn n ṣe nibi iṣẹ naa lati ọjọ to pẹ wa. Gbogbo awọn eeyan lo tun kọ haa, wọn ni ki lọkunrin Ibo yii n ṣe yii, to si ko gbogbo ipo ileeṣẹ Reluwee fun awọn Ibo ẹlẹgbẹ re.

Bayii ni Ikejiani di meji ni ileeṣẹ Reluwee, ọkan ni ọga, ekeji si ni akọwe rẹ, ọmọ baba kan naa ni wọn n ṣe. Bakan naa ni aaye tun ṣi silẹ ni ileeṣẹ awọn Reluwee yii, wọn ni wọn n wa ẹni ti yoo jẹ olori ọsibitu wọn nibẹ. Dokita S.E.A. Ewa ti wa nibẹ lati ọdun 1958, oun si ni Medical Officer fun ileeṣẹ naa, ohun ti awọn eeyan si n ro ni pe wọn yoo kan fi oun ṣe ọga ni, nigba to jẹ oun naa lo ti n ṣe bii olori lati ọjọ yii wa. Dokita S. O. Ejiwunmi naa ti wa nibẹ tipẹ o, lati inu oṣu karun-un, ọdun 1960, loun ti jẹ oniṣegun eebo nibẹ, ọfisa loun naa, ọga ni. Bẹẹ naa ni Dokita Ofomata waa darapọ mọ ileeṣẹ naa ninu oṣu keje, ọdun 1960, o si ba awọn agbaagba meji tibi nibẹ ni. Ṣugbọn iyanu to wa nibẹ ni pe Ikejiani, alaga Reluwee ko jẹ ki wọn mu Dokita Ewa to jẹ Efik, tabi Ejiwumi to jẹ Yoruba, o ni Ofomata, ọmọ Ibo, ni ki wọn mu.

Ko ti i pari o. Ileeṣẹ Reluwee yii tun ni awọn yoo yan ọga kan, Acting District Superitendent, wọn si ni ki awọn ti wọn ba mọ pe ipo naa tọ si awọn kọwe wa. Ọkunrin Yoruba kan to ti dagba sidi ipo keji si ipo naa tẹlẹ, A.M. Omiṣore, kowe, nitori lati inu oṣu kejila, 1960, lo ti wa nipo ọga yii. Bakan naa ni Agbabiaka ti oun naa ti jẹ ọga to tẹle Omiṣore lati inu oṣu kejila, ọdun 1960, naa kọwe, E. O Agusiobo toun naa jẹ ọga to tẹle Agbabiaka lati oṣu karun-un, ọdun 1962, kọwe, o ni ki wọn mu oun. Amọ awọn eeyan ti ro pe ko si ohun to tun jọ ẹja lori iyan mọ, wọn ti n sọ laarin ara wọn pe ko sẹlomiiran ti ipo naa tọ si ju Omiṣore lọ, nigba to jẹ oun ni ọga to ti wa nibẹ lati ọjọ to ti pẹ wa. Ṣugbọn Ikejiani ko tun jẹ ki wọn ṣe bẹẹ, ọmọ Ibo to de ni ọdun 1962 lo ni ki wọn mu, ẹni to jẹ oun lo kere julọ laarin wọn.

Bẹẹ naa ni wọn ṣe nigba ti wọn n wa ẹni ti yoo di ipo ọga wọn gẹgẹ bii Works Superintendent. Awọn meji kan ti wa nibẹ ti iṣẹ injinnia n ho lori wọn. Ki i ṣe pe wọn ti pẹ lẹnu iṣẹ naa ni Reluwee yii nikan kọ, wọn kawe rẹpẹtẹ debẹ ni, oga inijinia si ni wọn ni gbogbo ibi ti wọn ba de. H.A.A Junaid to kawe rẹpẹtẹ ju, to si jẹ ọga, T.C. Grillo lo tẹle e, oun naa si gba oye rẹpẹtẹ, ṣugbọn ọmọlẹyin lo jẹ fun Junaid. Lẹyin iyẹn lo ṣẹṣẹ waa kan S.N.C. Ogbo, oun ko si kawe to awọn meji to ṣaaju yii rara, bẹẹ ni ko ti i de ipo ọga bii tiwọn. Lẹyin tirẹ lo kan ọmọ Ibo mi-in, N.N. Obinwa, oun ko si gba oye kan ninu iṣẹ injinnia rara, bẹẹ ni ko ti i pẹ lẹnu iṣẹ naa bii ti awọn to ku. Ṣugbọn nigba ti wọn fa ọrọ naa lọ ti wọn fa a bọ, awọn Ikejiani ni ẹni ti awọn fẹ ko di ipo naa mu ni Obinwa, ọmọ Ibo bii tiwọn, oun naa ni wọn si gbe e fun.

Nigba ti Junaid ati Grillo ri i pe ipo tuntun naa ko bọ si awọn lọwọ, o ti bọ si ọmọọṣẹ awọn lọwọ, wọn sare lọ si ibi ti wọn ti tun ni wọn tun n wa eeyan nibi iṣẹ yii kan naa, wọn fẹẹ mu ẹni ti yoo jẹ Production Engineer wọn. Ipo nla naa tun leleyii, awọn eeyan si ti ro pe nigba ti wọn ko fun Junaid ni ipo to tọ si i, wọn yoo fi eleyii fun un, bi wọn ko ba si mu Junaid, wọn yoo mu Grillo. Sugbọn si iyalẹnu mi-in, Ogbo to tun jẹ ọmọ Ibo mi-in, to si jẹ ọmọọṣẹ Junaid ati Grillo lawọn Ikejiani tun mu. Wọn ni ẹni ti ọkan awọn mu niyẹn, oun lo le ṣe ileeṣẹ naa. Ọrọ naa waa su gbogbo eeyan pata, nitori wọn ko mọ idi ti ọkunrin Ibo naa ṣe n ṣe eleyii, o si jọ pe o fẹẹ sọ gbogbo awọn Yoruba ti wọn jẹ ọga ni ileeṣẹ naa ko too de di ọmọọṣẹ ati ọmọ ẹyin patapata. Ojoojumọ lo lo si n ṣe kinni naa, ko ti i jawọ rara.

Bẹẹ lo jẹ laarin ọdun kan pere ti Ikejiani di alaga ileeṣẹ Reluwee, awọn eeyan mẹtadinlọgọta (57) ni Ikejiani ti gba siṣẹ. Ninu awọn mẹtadinlọgọta yii, awọn mẹtadinlọgbọn (27) lo jẹ Ibo, awọn mejilelogun (22) jẹ oyinbo, awọn mẹjọ pere ni wọn si jẹ ẹya mi-in lati Naijiria kaakiri. Bẹẹ ni kinni naa ko ti i tan o. Ọkunrin kan wa ti wọn n pe ni Njoku, Njoku yii, aburo minisita fun eto igbokegbodo ni, minisita yii si ni ileeṣẹ Reluwee wa labẹ rẹ, oun ni ọga Alaga Ikejiani, ibo si ni awọn mejeeji. Njoku ni aburo kan, aburo naa ti ṣiṣẹ ni Reluwee, iṣẹ mesenja lo si ṣe titi to fi ritaya. Njoku loun naa n jẹ, Ibo ni gbogbo wọn. Igba ti Ikejiani de lo pe Njoku yii pada, wọn si sọ ọ di ọkan ninu awọn ọmọ igbimọ apaṣẹ ileeṣẹ Reluwee yii, owo gọbọi ni wọn n san fun un, wọn si fi i ṣe alaga igbimọ awọn ti wọn n gbaayan siṣẹ ni Reluwee.

Ọmọ Ibo kan wa ti ko ka iwe mẹwaa jade, Okereke lorukọ ẹ, ṣugbọn ọmọ ẹgbọn Ikejiani ni. Sabukeeti awọn oniwee mẹrin lo ni, ṣugbọn nigba ti wọn yoo gbe e paa, ilu oyinbo ni wọn gbe e lọ, o si di ọkan ninu awọn aṣoju ileeṣẹ Reluwee ni London. Awọn mẹrin ni awọn aṣoju ti wọn yan lati lọọ ṣoju ileeṣẹ yii ni ilu oyinbo kaakiri, awọn mẹrẹẹrin si jẹ ọmọ Ibo. Awọn yii ni Ọgbẹni Egbuna, Ọgbẹni Egwatu, Ọgbẹni Nmegwa ati Ọgbẹni Okereke.

Awọn aṣiri yii ni ijọba Akintọla tu jade lẹẹkan naa lati fi ṣalaye aburu to wa ninu ẹgbẹ NCNC, bi kinni naa si ti jade sita ni wahala rẹpẹtẹ de. Ija awọn ọmọ Ibo ati Yoruba bẹrẹ ninu ẹgbẹ NCNC.

(60)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.