Akinlaja to fipa ba ọmọ ayalegbe rẹ lo pọ l’Akurẹ ti nisẹ eṣu ni

Spread the love

Lọsẹ to kọja yii lọwọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo tẹ ọmọkunrin kan, Friday Akinlaja, lori ẹsun pe o fi tipatipa ba ọmọ ọdun mẹsan-an kan, Kayọde Abidemi, lo pọ.

Akinlaja la gbọ pe wọn ka mọ ibi to ti n ṣe kinni fun ọmọdebinrin to jẹ ọmọ ọkan ninu awọn ti wọn jọ n gbele laarin ọsẹ to kọja, lasiko ti iya rẹ sare jade.

Ọmọkunrin ẹni ogun ọdun ọhun la ri to n sunkun yọbọ ninu ọkọ tawọn ọlọpaa fi gbe e wa sile-ẹjọ, to si n bẹbẹ pe ki wọn ṣaanu oun. O ni eṣu lo ti oun toun fi huwa naa, o ṣeleri pe bi ori oun ba fi le ko oun yọ ninu wahala ti kinni abẹ oun ko oun si yii, oun ko tun jẹ dan iru rẹ wo mọ layelaye.

Ọmọkunrin ọhun ko ti i sọrọ tan tawọn ọlọpaa fi wọ ọ wọnu ile-ẹjọ lọ lati lọọ ṣalaye ohun to mọ nipa ẹsun ti wọn fi kan an.

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ lori ẹsun sisọ ọmọ ọlọmọ dobinrin laipe ọjọ, ati fifipa ba ọmọdebinrin naa lo pọ ti wọn fi kan an, Onidaajọ Ọlanipẹkun Mayọmi paṣẹ pe ki Akinlaja ṣi lọọ maa ṣere ninu ọgba ẹwọn Olokuta fun igba diẹ na.

O ni o digba ti imọran ba jade lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran koun too le sọ ni pato igba ti yoo tun fara han nile-ẹjọ.

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.