Akeredolu, tete yaa doju ija gidi kọ wọn

Spread the love

Ọkunrin lọọya kan lọ si ipinlẹ Ondo lọsẹ to kọja yii, Kayọde Ajulọ lorukọ rẹ. Ipinlẹ rẹ ni Ondo, bo tilẹ jẹ Abuja ni oun n gbe. Amọ bo ti ṣe ohun to fẹẹ ṣe tan to n pada lọ si ilu Abuja, bẹẹ lo pade awọn Fulani kan lọna, ti wọn ko ibọn ati ọfa lọwọ, ti wọn si da mọto rẹ duro. Njẹ ẹyin wo ree, wọn ni awọn ki i ṣe Fulani ajọmọgbe, Fulani fijilante lawọn. Fijilante Fulani nilẹ Yoruba! Ajulọ pariwo. Ṣugbọn wọn sọ fun un pe ko le gba awọn gbọ, ko ya fọto awọn, ko si tun jẹ ki awọn pe kọmiṣanna ọlọpaa foun. Wọn pe kọmiṣanna ọlọpaa loootọ, nitori wọn ni nọmba rẹ lọwọ, eyi ti fi han pe kọmiṣanna ọlọpaa fun wọn laṣẹ, o si mọ nipa ohun ti wọn n ṣe yii. Ṣe ẹ ri i pe tiwa ti ba wa nilẹ Yoruba. Abi nigba ti awọn igiripa ati ọmọkunrin tiwa ko ba le ṣe fijilante nilẹ wa, to ba jẹ awọn Fulani lo ku to n ṣe fijilante fun wa. Iru aṣa palapala wo ree, ati pe kin ni ọga ọlọpaa agbegbe naa yoo fun wọn ni iru aṣẹ bayii si. Lara ohun ta a n sọ niyẹn o. Lara iwa ika ati irẹjẹ to wa nilẹ wa ree o. Bo ba jẹ awọn ọmọ tiwa lo ko ara wọn jọ, koda ko jẹ OPC to lorukọ tabi ẹgbẹ agbẹkọya, ti awọn ọlọpaa ba fi le ri wọn, agaga ti wọn ba ti ri ibọn lọwọ wọn tabi ada, wọn yoo rọ wọn da si atimọle ni. Bẹẹ bi wọn lọ si ọdọ wọn lati gba aṣẹ, wọn o ni i fun wọn laṣẹ, wọn yoo ni ko si aṣẹ lọdọ awọn, Abuja nikan ni awọn ti le gba iru aṣẹ bẹẹ. Ṣugbọn igba to ba ti jẹ awọn Fulani ni, wọn yoo fun wọn laṣẹ, ṣe awọn ni alagbara, awọn ni wọn ni ilu, ara to ba si wu wọn ni wọn le da. Ṣe awọn ọga ọlọpaa yii fẹẹ sọ pe awọn ko mọ pe ohun ti wọn n ṣe yii lewu ni. O lewu nitori pe bawo lawọn funra wọn ṣe fẹẹ da Fulani ajinigbe mọ yatọ si ti fijilante. Ti Fulani ajinigbe ba da mọto duro, ṣe ki awọn eeyan duro fun un ni abi ki wọn maa sa lọ, nigba ti ko si aṣọ ọlọpaa lọwọ rẹ, ti wọn ko si sọ faraalu pe awọn ti ko fijilante Fulani da sigboro. Awọn naa mọ pe epe ni gbogbo Yoruba yoo maa gbe awọn ṣẹ bi wọn ba kede iru ọrọ raurau bẹẹ, ti wọn ba kede pe ẹgbẹ Fulani fijilante lo ku ti wọn fẹẹ maa lo nilẹ wa. Ṣe Fulani fẹẹ mọ ilẹ wa ju wa lọ ni, tabi Fulani yoo mọ ọna oko ilu kan ju awọn agbẹ ati ọdẹ to jẹ ibẹ ni wọn bi wọn si, ibẹ ni wọn si ti n ṣe iṣẹ wọn lọ. Iwa ika leleyii, bii igba ti wọn si fẹẹ fi wa fun Fulani mu ni, awọn ọlọpaa adugbo wa ati ijọba si jọ n ṣe aburu yii ni. O daa bi Akeredolu ti paṣẹ yii o, to ni ki wọn mu Fulani yoowu ti wọn ba ri to n ṣe fijilante, awọn ọmọ ofo to jẹ Miyetti Allah, ẹgbẹ agbẹnusọ awọn apaayan yii lo fun wọn ni iwe idanimọ. Ki ọlọpaa maa ṣa wọn nikọọkan, bẹẹ naa si ni ni ki awọn gomina ilẹ Yoruba to ku tete ṣe bẹẹ, kawọn naa maa sọ awọn Fulani to ba n pe ara wọn ni fijilante, nibikibi ti wọn ba si ti ri wọn, ki wọn fi ọlọpaa ijọba ko wọn, yatọ si awọn ọlọpaa to ti gbabọdi, ki wọn si tete pariwo wọn sita ki ijọba apapọ ma tẹ ọrọ naa mọlẹ, nitori awọn gan-an ni wọn n ṣe wa o.

(0)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.