Akanni ṣe ayederu iwe INEC, o laṣofin loun, lo ba fi gba awọn eeyan rẹpẹtẹ

Spread the love

Adefunkẹ Adebiyi

Awọn ẹsun nla bii pipe ara ẹni lohun ti a ko jẹ, ṣiṣe ayederu iwe ajọ eleto idibo ilẹ wa (INEC), titan araalu jẹ ati ẹsun mẹrin mi-in ni Akanni Toluwalọpẹ n rojọ le lori bayii nipinlẹ Eko, lẹyin ti wọn mu un pe o ṣẹ sofin ijọba.

Adugbo kan ti wọn n pe ni Madogun, nipinlẹ Ogun, ni Akannni, ẹni ọgbọn ọdun n gbe, ṣugbọn Ijaye Ojokoro, nipinlẹ Eko, lo ti lu awọn eeyan ni jibiti owo nla gẹgẹ bi Agbefọba, Augustine Nwabuisi, ṣe  ṣalaye ni kootu Majisireeti to wa ni Yaba, l’Ọjọbọ to kọja yii.

 O ṣalaye pe Akanni purọ fawọn eeyan ninu oṣu kẹfa, ọdun yii, pe oun ti wọle gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣoju-ṣofin (House of Representatives). Koda, ki wọn le baa gba a gbọ, iwe kan ti ibuwọlu alaga INEC wa, ti wọn si ki i ku oriire pe o wọle gẹgẹ bii ọmọ ile igbimọ aṣofin naa lo fi n han awọn eeyan kiri. Bẹẹ ayederu niwee naa, ọkunrin yii lo ṣe e funra ẹ, ki i ṣe INEC rara.

Ohun to tori ẹ n gbe iwe naa kiri fawọn eeyan ni pe o loun fẹẹ ṣe ajọyọ iwọle oun naa, ṣugbọn owo to wa lọwọ oun ko le to, ki awọn eeyan ran oun lọwọ pẹlu owo diẹdiẹ. Boun ba wọle tan toun bẹrẹ iṣẹ nile igbimọ aṣoju-ṣofin, oun yoo ba wọn waṣẹ sọdọ ijọba apapọ, oun yoo si tun da owo wọn pada fun wọn.

Agbefọba tẹsiwaju pe nibi ti kinni ọhun ka olujẹjọ yii lara de, to si fẹ kawọn eeyan gba oun gbọ, o ko awọn kan lọ s’Abuja, o ni ki wọn waa lọọ wo bi wọn yoo ṣe bura foun wọle sile igbimọ naa, ṣugbọn opin gbogbo ẹ naa, irọ ni.

‘’Oluwa mi, olujejọ yii gba ẹgbẹrun lọna irinwo ati ọgbọn Naira (430,000) lọwọ obinrin kan, Abilekọ Dọlapọ Tunner. O gba ẹgbẹrun lọna aadoje din marun-un (125,000) lọwọ Ọgbẹni Ọdunlami, owo to gba lọwọ Omidan Jessica Eyimofe ku diẹ ko wọ miliọnu kan ni (665,000). Lẹyin naa lo tun gba foonu tuntun Samsung S9 ti wọn n ta lẹgbẹrun lọna igba ati ọgọta Naira(260,000) lọwọ ọmọbinrin naa, o loun yoo ba a waṣẹ s’Abuja. O gbowo lọwọ awọn ara ṣọọṣi ẹ kan naa, bẹẹ lo tun pe ara ẹ ni lọọya fun wọn. Gbogbo eyi lodi sofin ipinlẹ yii.’’ Bẹẹ ni agbefọba Nwabuisi sọ nipa Akanni Toluwalọpẹ.

Gbogbo ẹsun yii ni Akanni loun ko jẹbi ẹ pẹlu alaye. Eyi ni Adajọ S.O Ọbasa ṣe faaye beeli silẹ fun un pẹlu idaji miliọnu Naira ati oniduuro meji jiye kan naa.

O paṣẹ pe awọn oniduuro naa gbọdọ ti ju ẹni ogoji ọdun lọ, wọn si gbọdọ maa gbe lagbegbe kootu. O ni wọn gbọdọ le ṣafihan iwe owo-ori sisan wọn fọdun mẹta gbako funjọba ipinlẹ Eko, ọkan ninu wọn si gbodọ jẹ mọlẹbi olujẹjọ.

Igbẹjo mi-in di ogunjo oṣu yii.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.