Akala ni egbe ADP fa kale

Spread the love

Leyin to binu kuro ninu egbe oselu APC, Gomina ipinle Oyo tele, Otunba Adebayo Alao Akala ni egbe oselu APD to sese darapo mo fa kale lati dije dupo loruko egbe naa nipinle Oyo ninu ibo gomina odun to n bo.
Leyin ipade ti won se, nibi ti ajo eleto idibo ati awon oloye egbe naa wa ni won ti fimo sokan lori eleyii.
Akala ni won fun ni tikeeti egbe yii lai ni alatako, ti okunrin omo bibi ilu Ogbomoso naa si ti ke si awon alatileyin re lati darapo mo on ninu egbe tuntun yii.
Te o ba gbagbe, inu egbe oselu PDP ni Akala ti loo darapo mo APC, leyin idibo abele won to waye lose to lo lohun-un ni okunrin naa binu fi egbe osely yi sile lo egbe tuntun yii. Oro esi idibo abele APC ti ko dun mo on ninu lo tori e fi egbe yii sile.

(30)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.