Akala, Lanlẹhin atawọn to n dupo gomina tako Adelabu lori ọrọ oṣelu Naijiria

Spread the love

Gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan ri, Ọtunba Adebayọ Alao-Akala, to tun n dupo naa bayii lorukọ ẹgbẹ oṣelu Action Democratic oṣelu Party (ADP); Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin to n dupo lorukọ ẹgbẹ African Democratic Congress (ADC), atawọn oludije min-in fun ipo gomina ni wọn ti tako Adebayọ Adelabu, ẹni to n dupo goimna lorukọ ẹggẹ oṣelu APC lori ero wọn nipa eto oṣelu orileede yii.

 

Atako ọhun waye nibi ipade itagbangba ti ileeṣẹ iroyin Yoruba BBC Yoruba ṣe pẹlu awọn oludije dupo gomina to laamilaaka julọ ninu idibo gomina ipinlẹ Ọyọ ọdun 2019 lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja.

 

Ọkan ninu awọn to n beere ibeere lọwọ awọn oloṣelu yii lo da aroye ọhun silẹ nigba to beere lọwọ Adelabu pe iriri wo lo ti i ni nidii oṣelu to fi n dupo gomina, ati pe ṣe aini iriri yii ko ni i yọ silẹ fun un bi awọn eeyan ba dibo yan an sipo gomina.

 

Nigba ti Adelabu, ẹni tawọn eeyan tun mọ si Pẹkẹlẹmẹẹsi yoo dahun ibeere naa, o ni “inu mi dun pe mi o ni iriri ninu oṣelu, nitori iriri idi oṣelu Naijiria ko ṣee mu yangan. Oṣelu ta a mọ ni ka parọ mọra wa, ka baayan lorukọ jẹ, abbl.

 

Ni ipinlẹ Ọyọ, oṣelu jagidijagan, oṣelu ka pawo ilu sapo ara ẹni la ti n ṣe. iyẹn lemi fẹẹ yipada. Mo jade lati dupo gẹgẹ bii ọmọ tuntun, mo si mọ pe pẹlu iriri mi gẹgẹ bii igbakeji gomina banki apapọ ilẹ yii, ipo gomina ipinlẹ kan ko pọ ju fun mi lati ṣe.”

 

Ṣugbọn ọtọ loju ti Akala fi wo ọrọ yii. Ni tiẹ, o ni “oṣelu Naijiria ṣe e mu yangan fun awa ta a ṣe e pẹlu ibẹru Ọlọrun. Awọn to ti goke lagbaaye yẹn ṣaaju tiwa bẹrẹ. A o le ti i yara to wọn kiakia bayii”.

 

Akala, ẹni to ti lo ọdun mẹjọ gẹgẹ bii gomina ati igbakeji gomina ipinlẹ yii sọ pe ipo gomina ipinlẹ Ọyọ tobi kọja ohun ti ẹnikẹni ti ko ba ti i dipo oṣelu mu ri le ṣe, nitori atari ajanaku ni, ki i ṣẹru ọmọde.

 

Bakan naa ni Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin, oludije dupo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu ADC sọ pe, “oṣelu Naijiria ṣe e mu yangan nitori a ko le paarọ ilu wa, a ko si le paarọ awọn eeyan to wa nibẹ, atunto la nilo. A o le lọọ ko awọn eeyan wa lati Amẹrika”.

 

Akala, Lanlẹhin, Adelabu pẹlu Ọṃọọbabinrin Ọmọbọlanle SarumI-Aliyu to n dupo gomina lorukọ ẹgbẹ oṣelu National Interest Party (NIP) nikan ni wọn kopa nibi eto naa nigba ti Ẹnjinia Ṣeyi Makinde (PDP) ati Amofin Sharafadeen Alli (ZLP) ti wọn tun fiwe pe sibi eto naa ko yọju.

 

Opọ awọn ileeṣẹ redio ati tẹlifiṣan lo fọwọsowọpọ pẹlu BBC Yoruba lati gbe eto naa jade lasiko ti wọn n ṣe e lọwọ. Lara wọn ni NTA, Amuludun, Amutajero ati bẹẹ bẹẹ lọ.

 

Awọn oludije dupo gomina mẹrẹẹrin to kopa nibi eto ọhun ni wọn ṣeleri lati san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira gẹgẹ bii owo-oṣu to kere julọ fun oṣiṣẹ ijọba kọọkan.

 

 

(8)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.