Akala binu kuro ni APC, o fẹ dupo gomina ninu ADP

Spread the love

Okun ibaṣepọ to wa laarin gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ati Ọtunba Adebayọ Alao-Akala to wa nipo ọhun ṣaaju ti rẹ ja patapata pẹlu bi gomina atijọ naa ti kuro ninu ẹgbẹ oṣelu APC, to si gba inu ẹgbẹ ADP lọ.

Lati ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kejila, ọdun to kọja (2017), ti Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu atawọn adari ẹgbẹ APC mi-in ti tẹwọ gba Akala wọnu ẹgbẹ naa ni gbọngan Mapo, n’Ibadan, lawọn amoye kan ti n sọ asọtẹlẹ pe ibaṣepọ Ajimọbi ati Akala ninu ẹgbẹ APC ko le pẹẹ fori ṣanpọn. Wọn ni ọrọ ipo ni yoo fa ipinya laarin wọn lasiko idibo ọdun 2019.

Akala fifẹ han lati ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ lẹẹkan si i, o dupo gomina ninu idibo abẹle ẹgbẹ APC, ṣugbọn ko ba wọn kopa ninu idibo naa mọ nitori o ti mọ pe Ajimọbi ti ni ẹlomin-in lọkan to fẹ ki ẹgbẹ APC fa kalẹ lati dupo gomina lorukọ wọn. Eyi ni ko ṣe ba ọpọ eeyan lojiji rara nigba ti Akala tun fi ẹgbẹ naa silẹ.

Ṣugbọn ṣaaju asiko yii, Gomina Ajimọbi ti ṣe kinni kan lati dọgbọn de Akala mọle ninu ẹgbẹ oṣelu Onigbaalẹ, to jẹ pe bo ba tiẹ papa fi ẹgbẹ yii silẹ, ko ni i ṣoro fun wọn lati ri ibo adugbo naa mu. Ọgbọn ti Ajimọbi da ni pe, o fi ọmọkunrin Akala, Ọlamiju Akala, ṣe alaga ijọba ibilẹ Guusu Ogbomọṣọ. Iyẹn ni pe bi Akala ba tilẹ darapọ mọ ẹgbẹ mi-in, oun ati ọmọ ẹ to n jẹun ninu ẹgbẹ APC ni wọn yoo jọ pin ibo Ogbomoṣọ to gbojule mọ ara wọn lọwọ nitori awọn ara Ogbomoṣọ fẹran Akala, ṣugbọn Ajimọbi mọ pe Ọlamiju naa ko ni i fẹẹ da bii ẹni to joye awodi ti ko le gbe adiẹ.

Iroyin to tun n lọ bayii ni pe Ọlamiju yii paapaa ni Ajimọbi fẹẹ fi ṣe igbakeji ondupo gomina labẹ ẹgbẹ APC, eyi ti yoo mu ki ọpọ ara Ogbomọṣọ fẹ lati dibo fun egbẹ naa. Ṣugbọn Akala ti sọ pe ọmọ oun ko jẹ gba lati ṣe igbakeji gomina ẹgbẹ alatako oun nigba ti ki i ṣe ọmọ ale.

Nigba ti gomina atijọ yii paapaa yoo si jẹwọ fun awọn Ajimọbi pe oun gan-an ki i ṣe ọmọde nidii oṣelu, niṣe lo gba inu ẹgbẹ oṣelu Action Democratic Party (ADP) lọ.Ki i si i ṣe pe o kan ọ sibẹ lasan, o ti gba tikẹẹti gomina ẹgbẹ naa. iyẹn ni pe oun ni ẹgbẹ ADP yo fa kalẹ lati figa gbaga pẹlu awọn oludije ti ẹgbẹ oṣelu mi-in ba fa kalẹ lati dupo gomina ninu idibo ọdun 2019.

ALAROYE gbọ pe ọpọ ninu awọn ti inu wọn ko dun si ọna ti idibo abẹle APC gba waye lo ti pinnu lati ba Akala lọ sinu ẹgbẹ ọhun.

Ṣugbọn pẹlu bo ṣe jẹ pe ẹnikan ki i ba Akala fori gbari ko rọwọ mu ninu idibo niluu Ogbomọṣọ ati awọn apa ibi kan lagbegbe ilu nla naa tẹlẹ, ko jọ pe eyi yoo ri bẹẹ ninu idibo ọdun 2019 to n bọ yii pẹlu ipo alaga kansu ti Ajimọbi ti fi Ọlamiju si, agaga ti iroyin ipo igbakeji gomina ta a gbo pe wọn fẹẹ fi da ọmọkunrin naa lọla ba tun lọọ dootọ. Amọ ṣa, Akala naa ko dakẹ, o ti ni ọmọ oun ko ṣe igbakeji gomina kankan, ki Ajimọbi atawọn APC fọwọ mu ipo wọn.

 

(26)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.