Ajọ INEC sun ọjọ ominira wa siwaju ni- Adagunodo

Spread the love

Alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Ọnọrebu Sọji Adagunodo, ti sọ pe irẹjẹ ojukoju ati fifi ọwọ ọla gba ni loju ni ohun ti ajọ INEC sọ nipa esi idibo gomina ọhun.

Adagunodo ni Ọlọrun funra rẹ lo pinnu lati gba awọn eeyan ipinlẹ Oṣun loko ẹru ati lọwọ imunisin ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn ajọ eleto idibo mọ-ọn-mọ sọ ara rẹ di ohun eelo lọwọ awọn jẹgudujẹra ti wọn ko fẹ ki ipinlẹ Ọṣun bọ ninu gbese.

Adagunodo ni ajọ INEC ko ti i ṣamulo ofin idibo ti wọn fẹẹ lo nipinlẹ Ọṣun nibikibi ri lorilẹ-ede yii, eleyii lo si jẹ kawọn araalu ri i gbangba pe awọn kan n gbiyanju lati dabaru eto ijọba tiwa-n-tiwa.

O waa dupẹ lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun fun aduroti wọn pẹlu ẹgbẹ oṣelu PDP, o si ṣeleri pe ẹgbẹ naa yoo tun jawe olubori nibi atundi ibo Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii.

Awọn eleto aabo naa ti sọ pe digbi lawọn wa lati ri i pe ko si wahala kankan lasiko eto atundi ibo ti yoo waye ọhun, bẹẹ ni awọn ajọ eleto idibo ṣeleri pe ju bi ti opin ọsẹ to kọja ṣe lọ nirọwọrọsẹ, ohun gbogbo yoo tun ṣe deede lasiko yii.

(10)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.