Ajo eleto idibo fofin de lilo foonu ati kamera lasiko ti won ba n idibo l’Osun

Spread the love

Alaga eleto idibo lorileede yii, Ọjọgbọn Momood Yakubu, ti sọ pe ajọ naa ko ni i gba awọn oludibo laaye lati mu ẹrọ ibanisọrọ wọn wa sibi idibo lasiko ti eto idibo ba n lọ lọwọ. Bakan naa ni wọn ko ni i gba ẹrọ ayaworan kankan ni ibudo idibo bo ṣe wu ko ri. O sọrọ yii ni Mọnde, ọjọ Aje, ọsẹ yii, niluu Oṣogbo.

O sọrọ yii nibi ipade awọn oniroyin ti wọn ṣe pẹlu awọn alẹnulọrọ ni imurasilẹ fun eto idibo ti yoo waye nipinlẹ Ọṣun ni Satide ọsẹ yii. O ni igbesẹ yii waye lati dena bi awọn oloṣelu ṣe n lo ọna naa lati ra ibo lọwọ awọn oludibo, leyii to jẹ ọna tuntun ti wọn n gba ṣeru idibo. Ohun ti wọn maa n ṣe ni pe awọn oludibo yoo ya aworan ẹni ti wọn ba tẹka fun lasiko ti wọn dibo, aworan yii ni wọn yoo fi han aṣoju ẹgbẹ oṣelu yii lati fi han pe awọn ni awọn dibo fun, ti wọn yoo si gbowo lọwọ wọn.

Mamood ni awọn ko ni ki awọn eeyan naa ma mu foonu wọn wa sibi idibo, wọn ni ni kete ti wọn ba ti gba iwe lati dibo, wọn ko ni i mu foonu kankan wọ ibi ti wọn yoo ti dibo, afi ti wọn ba dibo tan.

Igbese yii ni ọpọ awọn oludije ti n pe fun pe ki ajọ eleto idibo gbe lati ri i pe awọn oloṣelu ko ṣi awọn oludibo to ba fẹẹ dibo fun ẹgbẹ oṣelu mi-in lọna nitori owo ti wọn fẹẹ fun wọn.

 

 

(17)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.