Ajimọbi ti jẹntu bayii, o ṣa tun fẹẹ di sẹnetọ lẹẹkan si i

Spread the love

Ọna ti ijọba Alaaji Isiaka Ajimọbi fi n sanwo ifẹyinti ati ajẹmọnu to ti wa lọwọ wọn lati ọjọ yii lẹnu ọjọ mẹta yii gba adura, pe ko jẹ iru rẹ la oo maa ri o. Abi ta ni ko ni i bẹ Ọlọrun ko jẹ iru rẹ ni wọn yoo maa ri, Ajimọbi sanwo ajẹmọnu fawọn oṣiṣẹ-fẹyinti mọkanlelọgọrin lọsẹ to kọja. Awon yẹn ti gba a, awọn mi-in si n reti tiwọn. O jọ pe ibo to n bọ yii mu ọkunrin alagbara yii lara gan-an ni, Ajimọbi fẹẹ ṣe sẹnetọ lẹẹkan si i, oun naa ko fẹẹ fi ile-ijọba ati owo ijọba silẹ, bo tilẹ jẹ pe ki i ṣe ọmọde mọ. Ka gba owo ijọba, ka jẹun ijọba, ka gun mọto ijọba, ka paṣẹ faa, ka sọ ohun to wu wa, gbogbo ẹ ti mọ wọn lara debii pe bi wọn ba kuro nipo kan, iṣoro lo maa n jẹ fun wọn lati lọọ jokoo sinmi, ki wọn si maa tọju awọn ọmọ wọn ati awọn ọmọ-ọmọ wọn, tabi ki wọn tilẹ wa iṣẹ mi-in ṣe ti yoo mu apọnle ati iyi ba wọn, ti awọn eeyan yoo fi mọ pe loootọ ni won ni ọgbọn ati laakaye, ti wọn si ti kawe wọn debi kan lati tun ilu ṣe. Ṣugbọn awọn oloṣelu wa ki i ṣe bẹẹ, wọn ko si yatọ si Ajimọbi yii. Lẹyin ti wọn ba ti fiya jẹ awọn eeyan, ti wọn ti paṣẹ onikumọ, aṣẹ onikondo tan, ti wọn ba ri i pe awọn ti n lọ, tabi ti wọn ba fẹẹ dibo lati gba nnkan lọwọ wọn, wọn yoo yiwa pada, wọn yoo maa ṣe bii eeyan daadaa si wọn. Tabi ki i ṣe Ajimọbi to n sọ pe ko sowo toun yoo fi sanwo ajẹmọnu kan, to di ohun ti oun ati awọn to ti fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba n ba ara wọn fa a naa ree. Tabi oun kọ ni! Oun naa kuku ni, igba lo ti yipada. Amọ iru owo ti ọkunrin naa san yii, akọsapo leegun i kọwo ni, kawọn to lowo wọn yaa gba a ki wọn fi ṣe ohun to dara, owo wọn ni. Ni ti Ajimọbi, ẹni ba jẹ ko fowo ajẹmọnu tan oun lọna Ibadan, tọhun o gbọn ni o! Ẹ tiẹ fibo da wọn jokoo sile, kẹ ẹ fibo gba gbogbo agbara iranu ti wọn n ro pe awọn ni, kẹ ẹ sọ awọn naa di korofo o jare. Ọpọlọpọ oloṣelu o jẹ nnkan kan, igba ti wọn ba depo ni wọn n sọ ara wọn di babara, korofo lasan lo pọ ninu wọn.

 

(3)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.