Ajimọbi, ma fun wọn nilẹ fun abule maaluu o

Spread the love

Bi ẹnikẹni ba wa ninu awọn oloṣelu to n sọ pe alaafia ati ifọkanbalẹ ni abule awọn onimaaluu ti awọn Buhari fẹẹ da silẹ kiri yii yoo mu wa, to n sọ pe ki awọn Fulani o ma le maa ja lawọn ṣe fẹẹ ṣe e, ki gbogbo araalu mọ pe irọ ni o. Eni ibi, eeyankeeyan, ẹlẹtan ati olorikori lẹni to ba n sọ bẹẹ laarin awọn ọmọ Naijiria gbogbo. Iran awọn Fulani onimaaluu yii ki i gbe lalaafia pẹlu awọn oniluu nigba ti wọn ba ti mọ pe awọn ni aṣẹ ati agbara ijọba lọwọ. Bo ba jẹ ko si atilẹyin ijọba ni, wọn le gbe daadaa pẹlu awọn eeyan, iyẹn to ba jẹ ijọba Ọyọ funra rẹ lo ronu pe oun yoo da abule maaluu silẹ, oun yoo ko awọn ti wọn ba n ṣe maaluu soju kan, boya Fulani tabi ẹya mi-in, oun yoo rẹnti ibẹ fun wọn, wọn o si maa san iye kan loṣooṣu tabi lọdọọdun. Ṣugbọn eyi ti awọn Buhari fẹẹ ṣe yatọ si eleyii, awọn fẹẹ ja ilẹ gba lọwọ awọn oniluu ki wọn gbe e le Fulani lọwọ ni. Ilẹ ti wọn ba waa gba yii, ijọba ipinlẹ kan ko ni i lagbara lori rẹ, tabi lagbara lori awọn Fulani ẹlẹran yii, nitori wọn yoo sọ pe awọn ko gba ilẹ lọwọ ijọba ipinlẹ wọn, ijọba apapọ lo fun awọn nilẹ, awọn ko si ni kinni kan i ṣe pẹlu gomina tabi baalẹ kankan. Ija ni yoo pada da silẹ, ija lile paapaa, nibi ti wọn yoo ti waa pa awọn eeyan to ba ni oko tabi abule nitosi wọn, ti wọn yoo si gba ilẹ onilẹ kun eyi ti wọn ba fun wọn. Eleyii ki i ṣe ohun ti a ṣẹṣẹ le maa sọ fun ara wa, o yẹ kawọn ti wọn ṣe ijọba, ati awọn ti wọn mọ itan Naijiria mọ eyi daadaa, ki wọn mọ pe eso airoju, eso wahala, idaamu ati ija ojoojumọ to le pada di ogun ni Buhari fẹẹ gbin kaakiri yii, ogun ti ko si ni i tan bọrọ ni. Ṣugbọn bi wọn ṣe lagbara to bayii, bi gomina kan ba wa ti ko fun wọn ni ilẹ, ko si ohun ti wọn le ṣe si i. Ko si ilẹ ko si ilẹ naa niyẹn. Nitori bẹẹ, gbogbo ẹyin eeyan Ibadan, gbogbo ẹyin eeyan Ọyọ ati ara ilẹ Yoruba gbogbo, ẹ bẹ Gomina Ajimọbi ko ma fun awọn Fulani laaye si ipinlẹ Ọyọ, ohun ti yoo di ogun lọjọ ọla ni.

(35)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.