Ajimọbi lo ranṣẹ pe mi, ki i ṣe pe mo lọọ bẹbẹ nile ijọba o- Ayefẹlẹ

Spread the love

Lẹyin ipade ti gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ṣe pẹlu gbajugbaja olorin Juju nni, Yinka Ayefẹlẹ, lori ileeṣẹ ẹ (Music House), ti ijọba wo lulẹ, ni iroyin ti lu igboro pa pe Ajimọbi ti gba lati san owo gbà-má-bìínú fun Ayefẹlẹ, ṣugbọn ALAROYE le fidi ẹ mulẹ pe ko si ohun to jọ ọ, ati pe ipade ọhun ko ti i fopin si awuyewuye lori dukia ọkunrin olorin naa ti ijọba bajẹ rara.

 

Agbẹnusọ Ayefẹlẹ, Ọgbẹni David Ajiboye to tun jẹ alarina laarin ileeṣẹ ọhun atawọn araalu lo sọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu akọroyin wa lori foonu lọjọ Aiku, Sọnde, ijẹta.

Ajiboye fidi ẹ mulẹ pe ẹjọ ti Ayefẹlẹ pe tako Gomina Ajimọbi ati ijọba rẹ lori ọrọ yii ṣi wa nibẹ, afi ti ijọba ba tun ile ti wọn wo ọhun kọ ko too di ọjọ kejila, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ti igbẹjọ mi-in yoo tun waye nikan lawọn le sinmi ija ofin.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ajimọbi ko ṣeleri nibi ipade ta a ṣe pẹlu ẹ pe oun maa dùn wa ninu lori ọrọ yii. Oun lo ranṣẹ pe wa, a si lọ nitori òǹpeni ni i ṣọla. A ò lọ sibẹ lati bẹbẹ, ipade ni wọn ni ka waa ṣe. Ṣe ẹbẹ ti a ko bẹ ki wọn too wo ileeṣẹ wa la maa wa maa bẹ lasiko yii?”

“A ti jọ gba pe ipade ìdákóńkọ́ nipade yẹn maa jẹ, a ko ni i pe awọn oniroyin, a ko si ni i ya fọto kankan. A ti wa lori ijokoo ki Ajimọbi too de, afi bi Ajimọbi ṣe de ti gbogbo wa dọbalẹ ki i, ta a ri i ti wọn bẹrẹ si i ya wa ni fọto. Ṣe ẹ mọ pe gomina ko le de ba wa lori ijokoo ka ma dọbalẹ fun un. Fọto idọbalẹ yẹn lawọn oniroyin waa gbe jade pe niṣe la lọọ bẹ gomina.”

Lori ohun ti wọn fẹnu kò le lori nibi ipade ọhun, eyi ti Alaafin Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyẹmi, atawọn ọba mẹsan-an mi-in lati apa Oke-Ogun ni ipinlẹ Ọyọ wa, Ayefẹlẹ ni, “ko si ohun to jọ pe gomina ṣeleri owo gbà-má-bìínu fun wa lori Music House ti wọn wo. Ohun to ṣẹlẹ ni pe a ko gbogbo iwe ti ijọba lu lontẹ fun wa lati kọ ileeṣẹ yẹn silẹ, wọn si fidi ẹ mulẹ pe ojulowo ni gbogbo ẹ. Lẹyin iyẹn ni Ajimọbi gbe igbimọ ẹlẹni marun-un kan kalẹ, o ni ka ṣepade pẹlu awọn igbimọ yẹn, ka ko gbogbo iwe ti igbimọ yẹn ba ni ka ko wa fun wọn ki oun le mọ nnkan ti oun maa ṣe lori ẹ.

“Yato si ile ti wọn wo, nnkan ti wọn bajẹ nibẹ le ni miliọnu lọna igba Naira (N200M). Awọn irinṣẹ ta a fẹẹ ko lọ si ẹka ileeṣẹ redio wa ta a da silẹ ni Abẹokuta, inu ọfiisi wa ti wọn wo n’Ibadan yii lo wa, gbogbo ẹ ni wọn bajẹ, nnkan bii ọgọfa miliọnu Naira (N120M) lowo to pari awọn irinṣẹ yẹn. Wọn ba mọto emi ati ẹnikan naa ninu awọn oṣiṣẹ wa jẹ pẹlu ọpọlọpọ dukia nileeṣẹ wa. Nitori naa, ọrọ ti kọja owo gba-ma-biinu lasan, bi iyẹn ba tiẹ maa waye, nnkan ta a maa jọ jokoo sọ ni. Akọsilẹ iṣiro gbogbo dukia ti ijọba bajẹ ni Music House wa lọwọ wa.”

Ninu ipade ti Ayefẹlẹ funra ẹ ṣe pẹlu awọn oniroyin nirọlẹ ọjọ keji ti ijọba ipinlẹ Ọyọ wo ileeṣẹ ẹ, eyi to ni ileeṣẹ redio rẹ ti wọn n pe ni Fresh FM 109.5 ninu lọkunrin olorin naa ti sọ pe niṣe ni Ajimọbi purọ tan oun jẹ lori ọrọ yii. O ni bo tilẹ jẹ pe gbogbo iwe aṣẹ ijọba to yẹ ki oun ni lati kọ Music House loun ni, sibẹ, nigba ti oun gbọ pe ijọba ṣi pinnu lati wo ile naa, iyawo oun lọọ ba Ajimọbi nile ijọba lọjọ Satide to lọ lọhun-un; ọpọlọpọ wakati lobinrin naa si fi wa lori ikunlẹ to n bẹ Ajimọbi lati jọwọ ma ṣe wo ileeṣẹ oun.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Emi ati iyawo mi la ba jọ lọ si ọdọ gomina lọjọ yẹn, ṣugbọn ileewosan lemi wa, nitori ara mi ko ya. Gomina fun iyawo mi ni ẹgbẹrun kan owo dọla, o si fi i lọkan balẹ pe oun ko ni i wo Music House, ṣugbọn o dun mi pe ko ju wakati diẹ sigba yẹn lọ ni wọn papa wo ile yẹn, ileeṣẹ ti mo fi oogun oju ara mi kọ, dukia ti mo fi bii ogun ọdun jiya fun.”

Lati ọsẹ to kọja, nigba ti ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ akoso Gomina Abiọla Ajimọbi, sin awọn oludari ileeṣẹ ọhun ni gbẹ́rẹ́ ìpàkọ́ lawọn eeyan ti n bu ẹnu atẹ lu ipinnu ijọba naa lọtun-un losi. Nibi ti ariwo ọhun si pọ de, niṣe lo fẹẹ jọ pe gbogbo ara ipinlẹ Ọyọ ati kaakiri ibi ti wọn ti gbọ iroyin naa ni wọn tako ipinnu ijọba, wọn ni bii igba ti ijọba ba fẹẹ mọ-ọn-mọ da Ayefẹlẹ loro, to si fẹẹ gba ounjẹ lẹnu omi lẹgbẹ eeyan to n ṣiṣẹ labẹ ẹ lọrọ wiwo ti wọn fẹẹ wo ile olowo nla naa yoo jẹ.

Ọpọ eeyan ti ro pe Ajimọbi ko ni i jẹ ki wọn wole naa, paapaa nigba ti awọn oloṣelu ti sọ ọrọ naa di isọnu mọ ọn lọwọ. sibẹsibẹ, awọn ọmọran kan wa ti wọn ti sọ asọtẹlẹ pe wiwo ni yoo gbẹyin ile nla to ni ileeṣẹ redio ati gbọngan ayẹyẹ igbalode nla kan ninu ọhun ko too di pe ijọba papa fi katakata wole naa laaarọ kutu ọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2018, yii ti i ṣe Sannde ijẹta.

Gomina Ajimọbi funra ẹ ti fi ọbẹ ba ara ẹ nidii lori ọrọ yii. Lọjọ to ba wọn lalejo nileeṣẹ redio ọhun lo ti ṣeleri pe oun ko ni i wo ileeṣẹ naa mọ nitori wọn kọle ọhun daadaa to bẹẹ ti ko ni aleebu kankan. Eyi lo jẹ ki gbogbo aye mọ pe bo ti wu ki aiṣedeede wa ninu ọna ti Yinka Ayefẹlẹ gba kọ Music House to, ijọba le fi oju fo o, ko pọn dandan ki wọn wó o rara ni.

Ileeṣẹ Redio Fresh FM gba Ajimọbi lalejo lọjọ naa, ṣugbọn awọn atọkun eto naa ko ti i bi i leere ọrọ kankan to fi fi wọn lọkan balẹ pe loootọ loun ti n gbero lati wo ileeṣẹ wọn, ṣugbọn oun ti yi ipinnu oun pada bayii, ọrọ ile naa ti di àjẹgbé tígún-ún-jẹbọ, nitori oun ko ni i wo o mọ laelae.

Gẹgẹ bo ṣe wa ninu fọnran ti awọn alaṣẹ ileeṣẹ Fresh FM ka silẹ lọjọ naa, eyi ti ẹda ẹ si tẹ akọroyin wa lọwọ, Ajimọbi sọ pe, “n ba ti wo ileeṣẹ yii tipẹ, ṣugbọn mo dupẹ pe mi o wo o nijọ naa lọhun-un, Ọlọrun tun waa ni ka wa sibi. Ṣebi Ayefẹlẹ naa lo jokoo lẹgbẹẹ mi yii, to ti n fi àdàbà we tolotolo bayii, ati adaba ati tolotolo wọn jọ n jẹun papọ ni. Awa (Ayefẹlẹ) tiẹ tun ti waa di igun, àjẹgbé nigún-ún-jẹbọ. Inu mi dun pe mo wa sibi. O tun waa dun mọ mi ninu nigba ti mo debi ti mo ri i pe wọn ṣe e daadaa, nitori emi jẹ ẹnikan to maa n fẹ ki wọn ṣe nnkan daadaa.

“Bi mo ṣe wọle, gbogbo yara igbohunsafẹfẹ yin… Ki i ṣe tàsọdùn, lo daa ju ninu awọn ileeṣẹ redio ti mo ti n ri. Mi o sọ gbogbo eleyii lati fa yin loju mọra o, gbogbo ibeere tẹẹ ba fẹẹ beere ni kẹ ẹ beere o. Ibi yii rẹwa, inu mi dẹ̀ dùn.”

 

O ṣee ṣe ki fọnran (fidio) yii wa lara awọn ẹri ti Yinka Ayefẹlẹ gboju le lati fi ba Ajimọbi ṣẹjọ. O fẹ ki ile-ẹjọ gba pe ika lasan l’Ajimọbi fi ileeṣẹ oun to wo ṣe nitori bo ba ṣe pe ọna ti ko bofin mu loun gba kọle ọhun ni, ko ni i sọ pe oun fẹẹ wo o tan ko tun ya, ko sọ pe oun ko ni i wo o mọ.

ALAROYE gbọ pe Ayefẹlẹ ti gba aṣẹ nile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ ninu eyi ti Onidaajọ I. Yerima ti sọ pe ijọba ipinlẹ Ọyọ ko gbọdọ ti i gbe igbesẹ kankan lori ọrọ ile to fẹẹ wo yii titi ti oun yoo fi gbe idajọ oun kalẹ lori ẹjọ naa.

Ṣugbọn ni nnkan bii aago mẹrin aabọ oru mọju aarọ Sannde, lọjọ ti igbẹjọ ku ọla, nijọba gbe katakata ranṣẹ sileeṣẹ naa, ti wọn si wo o lulẹ, bo tilẹ jẹ pe ibi ọwọ iwaju ile ọhun ni wọn wo lulẹ, mọ gbogbo ferese ati ilẹkun abawọle naa ni wọn wo. Awọn oṣiṣẹ to wa lẹnu iṣẹ oru mọju ni wọn sare pe ọga wọn lori ẹrọ ibanisọrọ. Ṣugbọn nigba ti Ayẹfẹlẹ yoo fi debẹ laaarọ kutu, awọn oniṣẹ ọba ti ṣe ohun ti wọn fẹẹ ṣe tan, wọn ti ba tiwọn lọ.

 

Amọ ṣa, iṣẹlẹ yii ko di iṣẹ ileeṣẹ Fresh FM lọwọ, lati nnkan bii aago meje aarọ ọjọ naa ni wọn ti tun bẹrẹ igbohunsafẹfẹ wọn pada. Lori redio ọhun ni Ayefẹlẹ funra ẹ ti sọ fawọn ololufẹ rẹ pe ki wọn fọkan balẹ, igbesẹ ti ijọba gbe yii ko di awọn lọwọ lati gbohun safẹfẹ. Bẹẹ lo rọ awọn ololufẹ ẹ lati ma ṣe ba ijọba fa wahala nitori oun, ati pe, iṣẹlẹ yii ko le da omi tutu si oun lọkan nitori ibi lile la a ba ọmọkunrin.

 

Titi di ba a ṣe n wi yii lawọn eeyan ṣi n bu ẹnu atẹ lu bi ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe ba dukia Ayefẹlẹ jẹ. Ẹgbẹ awọn oniroyin (NUJ), ipinlẹ Ọyọ ati kaakiri orileede yii; ẹgbẹ awọn atọkun eto lori redio ati tẹlifiṣan; ẹgbẹ awọn agbẹjọro; ajọ to n ri si eto igbohunsafẹfẹ nilẹ yii; ẹgbẹ awọn ọdọ Yoruba atawọn ẹgbẹ ajafẹtọọ gbogbo ni wọn n naka aleebu si Ajimọbi.

(145)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.