Aisan iba lassa pa tọkọ-taya nipinlẹ Kwara

Spread the love

Awọn tọkọ-taya kan labule Taberu, nijọba ibilẹ Baruten, nipinlẹ Kwara, ni wọn ti dero ọrun bayii nitori bi aisan iba ọrẹrẹ (Lassa fever) ṣe tun ṣẹ yọ nipinlẹ Kwara.

Kọmiṣanna feto ilera, Alhaji Usman Rifun-Kolo, lo sọ bẹẹ lọsẹ to kọja.

O ni awọn oloogbe naa ni wọn jẹ ọmọ orilẹ-ede Benin Republic, to paala pẹlu ipinlẹ Kwara; iṣẹ agbẹ lo ni wọn n ṣe ni Baruten, ati pe orilẹ-ede Benin Republic lawọn eeyan ọhun ti ko aisan naa wa sibi ti wọn tẹdo si ni Kwara.

Kọmiṣanna ọhun ni ileewosan kan ni ayẹwo ti fi han pe iba lassa lo kọlu tọkọ-taya naa. O ni ijọba ti ran awọn akọṣẹ-mọṣẹ nipa ajakalẹ arun lati jade lati mọ awọn ti awọn oloogbe naa ba ti ni nnkan i ṣe pọ ri.

O ni ikọ naa ṣawari eeyan mẹrin to ti figba kan ni aisan iba lagbegbe naa sẹyin, tawọn fura si pe o jẹ lassa. O ni ijọba ti bẹrẹ itọju awọn mẹrẹẹrin.

Bakan naa ni ijọba tun fi idi aisan rọmọ-lapa-rọmọ-lẹsẹ to pa ọmọ ọdun meji kan ati aisan iba pọnju-pọntọ (Yellow Fever), to kọlu agbẹ kan mulẹ.

Aisan to pa ọmọ ọdun meji naa to pe ni ‘Derived Polio Virus’, lo ṣẹlẹ ni agọ Fulani Kiiparu, to wa ni wọọdu Okuta, nijọba ibilẹ Baruten.

O ni ijọba ti gba ẹjẹ lara awọn ọmọde to wa lagbegbe naa lati le ṣe ayẹwo fun wọn, lọna ati dena aisan ọhun. Bakan naa ni gomina ti buwọ lu owo kan ti wọn yoo fi gbogun ti awọn aisan naa.

Dokita Abimbọla Fọlọrunṣọ, ẹni to jẹ akọwe ileeṣẹ ijọba to n ri si ileewosan alabọọde, Kwara State Primary Health Care Development Agency, ni awọn akọṣẹmọṣẹ lagbaaye lati ẹka World Health Organisation (WHO), ti wa nikalẹ lati ran ijọba lọwọ lọna ati gbogun ti awọn aisan naa.

 

 

 

 

(7)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.