Agunbaniro to fi moto paayan l’Oaogbo ti dero atimole

Spread the love

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti wọ Ọdẹdele Fẹranmi, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, to n sinru ilu niluu Oṣogbo lọ sile-ẹjọ lori ẹsun pe o wa ọkọ niwakuwa, eleyii to yọri si iku ọmọdekunrin kan.

 

Ọjọ kẹrin, oṣu kin-in-ni, ọdun yii, la gbọ pe olujẹjọ wa mọtọ niwakuwa niwaju sẹkiteriati ijọba, loju-ọna Gbọngan si Oṣogbo, nibi to ti ṣeku pa Ọlasunkanmi Pẹlumi, ọmọ ọdun mẹrindinlogun, to n taja loju ọna.

 

Agbefọba to n gbọ ẹjọ naa, Ọgbẹni Ọladoye Joshua, ṣalaye pe ni nnkan bii aago mọkanla aabọ aarọ niṣẹlẹ naa ṣẹlẹ pẹlu mọto Honda to jẹ ti olujẹjọ, to si ni nọmba Lagos MUN 187 CU.

 

Ọladoye ni olujẹjọ ti ṣe lodi si ofin, ijiya rẹ si wa lakọsilẹ ninu abala kẹfa iwe ofin kọkanlelọgọrin irinna ojuupopo tipinlẹ Ọṣun n lo lati ọdun 2003.

 

Ninu ọrọ tirẹ, agbẹjọro fun olujẹjọ, Bọla Abimbọla-Ige, rọ ile-ẹjọ lati ṣiju aanu wo o, ki adajọ faaye beeli silẹ fun un lọna irọrun pẹlu ileri pe ko ni i sa lọ fun igbẹjọ.

 

O ni gẹgẹ bii ipele karun-un abala kẹrindinlogoji iwe ofin orileede yii ti ọdun 1999 labala iwa ọdanran, olujẹjọ ko ti i jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, ayafi ti ile-ẹjọ ba too sọ bẹẹ.

 

Nigba ti Onidajọ Oluṣẹgun Ayilara n lu olujẹjọ lẹnu gbọrọ, Fẹranmi ni lati Ibadan, nibi ti oun n gbe loun ti n bọ laaarọ ọjọ iṣẹlẹ naa lati tẹ siwaju ninu isinru ilu oun ti yoo bẹrẹ lọjọ keje, oṣu kin-in-ni, ọdun.

 

Lẹyin atotonu agbefọba ati agbẹjọro olujẹjọ, Ayilara faaye beeli silẹ fun un pẹlu ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta Naira ati oniduuro meji ni iye kan naa.

 

Ayilara ni awọn oniduuro naa gbọdọ maa gbe ninu ipinlẹ Ọṣun, bẹẹ ni ki wọn si gbe mọto olujẹjọ yii wa si ayika ile-ẹjọ ko ma baa sa lọ fun igbẹjọ.

 

Ko too di pe o sun igbẹjọ siwaju di ọgbọnjọ, oṣu ti a wa yii, Ayilara ni ki baba to bi olujẹjọ tọwọ bọwe nile-ẹjọ, ko si fi fọto pelebe mẹta silẹ.

 

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.