Agbara ọrọ ninu ajọṣe

Spread the love

Lati gbọ ọ, tẹ ami ▶️ to wa nisalẹ yii. 

Ipo pataki ni Yoruba to ọrọ si ninu ohun yoowu ti wọn ba fẹẹ ṣe. Yoruba lo ni ọrọ aa maa yọ obi lapo, ọrọ yii kan naa si tun le yọ ida lakọ. Bẹẹ ọrọ yii kan naa ni, o si tun wa lọwọ bi ẹni to ba n sọrọ ọhun ba ṣe mọ ọn sọ si ati bi ẹni to ba n gbọ ọ naa ba ṣe mọ ọn gbọ.

 

Ọrọ ti a n sọ loni-in ki i ṣe nipa sọrọsọrọ ori redio tabi tawọn akọroyin ti wọn n sọrọ lati fi ṣalaye nnkan to n lọ faraalu o, pataki ọrọ ajọsọ laarin mọlẹbi, ọrẹ sọrẹẹ, ọga sọmọọṣẹ, olukọ si akẹkọọ, tabi ajọṣepọ yoowu to le waye laarin eeyan meji tabi ju bẹẹ lọ.

 

Ọpọ eeyan ni ko ka ibara-ẹni-sọrọ kun nnkan to fi bẹẹ ṣe pataki ninu ajọṣe, bẹẹ oun lo ṣe pataki julọ. Eeyan ko le baayan ṣe lai jẹ pe o mọ onitọhun de ipele pe nnkan bayii ni lagbaja le ṣe, nnkan bayii lo le bi lagbaja ninu ti mi o gbọdọ ṣe tabi nnkan bayii lo le dun lagbaja ninu bi mo ba fẹ ko yọnu si mi. Eeyan ko si le mọ awọn nnkan wọnyi nipa alajọṣe rẹ lai jẹ pe ọrọ ajọsọ n waye laarin wọn loorekoore.

 

Ko si nnkan to ba ọrẹ jẹ to to ibara-ẹni-yandi. Bi ẹni meji ti wọn jọ n ṣe ba ti ni aawọ kan laarin wọn ti wọn ko si le ba ara wọn sọ ọ ki wọn yanju ẹ, to jẹ pe ki wọn bẹrẹ si i yan ara wọn lodi ni wọn mu laṣa lẹyin ija, ko si bi iru ajọṣe bẹẹ ṣe le tọjọ. Koda bi wọn ba fi tipa so awọn mejeeji pọ, igbẹyin ọrọ naa ki i bimọ ire, tori inu ti wọn n bi sira wọn ti wọn ko fi ọrọ yanju ẹ yii oo maa bimọ si i ninu wọn ni, ko ni i parẹ sibẹ laelae.

 

Nibi ibara-ẹni-sọrọ la a ti i mọ ara ẹni dunju, ibẹ la a ti i mọ bi a ba ti hu awọn iwa ti awa gan-an o jẹ gba si ọmọlakeji wa. Loootọ ibinu ati iwa igberaga a maa ru bo eniyan loju nigba mi-in ti ko ni i jẹ ka le fẹẹ kọkọ ba alajọṣe wa sọrọ bi aawọ ba ṣẹlẹ. Kinni kan aa maa sọ siwa lọkan pe awa la jare, onitọhun yẹn lo jẹbi. Ṣugbọn bi awa ṣe n ro o yii naa ni ọrẹ tabi ololufẹ wa ti a n ba yan odi yii naa oo maa ro o bẹẹ, ko ṣaa ni i si ẹni ti yoo gbagbọ pe ori oun ku tabi iwa oun ko ba awujọ eniyan mu.

 

Eyi lo ṣe daa ki eniyan gbiyanju lati kọ odi yiyan silẹ bayoowu ki alajọsọ wa fẹẹ mu un laṣa to, ki a si ri i daju pe ọrọ ajọsọ n waye laarin wa loorekoore lati mọ ohun to ba n dun wọn tabi dun mọ wọn.

 

Ko sẹni to pe tan o, gbogbo wa pata la ku sibi kan. Bi iyawo ṣe nibi to ku si naa lọkọ ni aleebu tirẹ, bi ọrẹ ṣe ni abawọn tirẹ naa ni awọn obi ẹni ni ọna ti wọn le fi mu inu bi ni. Ọrọ ajọsọ nikan lo le tan iṣoro aipe yii, to si le mu wa ṣatunṣe si awọn ibi to ku diẹ-diẹ si lara wa.

(11)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.