Agbara ojo sọ awọn araalu sinu okunkun, bẹẹ lawọn mi-in ko nile lori mo ni Kwara

Spread the love

Lati ọsẹ meji sẹyin ni ojo to rọ niluu Ilọrin ti sọ awọn araalu di ẹni ti ko nile lori mọ bayii, ti ọpọ awọn eeyan si n gbe inu okunkun.
Lara awọn agbegbe ti ọrọ naa kan ni; Aduralere ati lsalẹ Koko, nijọba ibilẹ Guusu llọrin. Awọn araadugbo Ọsin, nitosi Ọffa Garage, naa fara gba ninu iṣẹlẹ ọhun. Lati bii ọsẹ meji sẹyin ni wọn ko ti ri ina mọnamọna lo.
Ọpọlọpọ mọṣalaṣi, sọọsị, ati awọn eeyan ti omiyale naa ko de ọdọ wọn lo n gbalejọ awọn eeyan ti omi naa ṣakoba fun.
Ojo to lagbara yii lo mu ki gbogbo gọta ni awọn agbegbe yii kun, to si fa omiyale. Awọn araadugbo yii sọ pe ki i ṣe igba akọkọ ree ti awọn yoo maa dojukọ iru iṣoro yii. Alaga Adugbo Aduralere, Alhaji Tunde Arẹmu, sọ pe ọpọlọpọ awọn eeyan to fara gba iṣẹlẹ naa ni wọn padanu dukia wọn sinu agbara yii. O ni ohun to fa ijamba naa ni ti awọn gọta to wa lagbegbe naa to ti di pa.

(22)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.