Agbara! Agbara! Agbara! Agbara nla de sọwọ Akintọla – Ọmọ to ba ta felefele yoo parẹ ni.

Spread the love

 

 

Niṣe ni awọn ti wọn le rẹrin-in n rẹrin-in arintakiti, ti awọn ti wọn si le binu naa n binu bii ki wọn sẹri mọ ọta wọn laya nitori ọrọ naa, ọrọ buruku toun ẹrin ni. Rẹmi Fani-Kayọde ni o. Lẹyin ti wọn ti da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ ti ọrọ si ti di ariwo, ti awọn ẹgbẹ NCNC n bu u pe ọdalẹ oloju-meji-bii-ida ni, tawọn ọmọ ẹgbẹ ti Ladoke Akintọla naa, iyẹn UPP, n sọ pe Fani ki i ṣe ẹni to ṣee fọkan tẹ, pe bo ti ṣe fawọn to ba ṣe tẹlẹ naa ni yoo ṣe fun Akintọla bo ba ya, ọkunrin naa jade sita gbangba, o ni ko sohun ti oun koriira laye oun ju oṣelu ẹlẹyamẹya lọ. “I HATE TRIBAL POLITICS”, bo ti sọ ọ niyi, ti iwe iroyin Daily Times si ba a gbe e jade lọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹta, ọdun 1964. Ọkunrin oloṣelu to jẹ Igbakeji Prẹmia, to si tun jẹ Minisita ọrọ ijọba ibilẹ ni West sọ pe bi oṣelu kan ba wa to maa n bi oun ninu, oṣelu ẹlẹyamẹya ni:

 

“Nnkan buruku ni. Gbogbo ẹnu ni mo si fi sọ bẹẹ, nitori mo mọ pe ohun to le fọ orilẹ-ede wa to ṣẹṣẹ n dide yii si wẹwẹ ni. Oṣelu ẹlẹyamẹya yii pọ ninu ẹgbẹ ti mo wa tẹlẹ, iyẹn ẹgbẹ NCNC, gbogbo ipo pataki pataki to wa ninu ẹgbẹ naa, ati ipo to kan ẹgbẹ yii ninu ijọba apapọ, awọn ipo to jẹ ipo gidi ni, awọn ọmọ Ibo to wa ninu ẹgbẹ naa ni wọn maa n pin in fun, to ba si ya, wọn yoo sọ pe ẹgbẹ NCNC yii, ti gbogbo Naijiria ni. Bo ba jẹ ti gbogbo Naijiria, ki lo de to jẹ Ibo nikan lo n gba ipo pataki ninu iṣẹ ijọba. Bo ba si jẹ pẹlu ipa pataki ti Yoruba n ko ninu ẹgbẹ yii ni, ki lo de ti awọn ipo wọnyi ko tọ si awọn ọmọ Yoruba to wa ninu ẹgbẹ wọn. Mo mọ ohun ti mo n sọ daadaa, ọrọ oṣelu kọ lọrọ to delẹ yii, ọrọ bi wọn ko ṣe ni i fi ti Yoruba ṣe apinle ni, ọrọ nipa idagbasoke adugbo tiwa ni, ohun to jẹ mi logun niyẹn!”

Bi ọrọ ti Fani-Kayọde n sọ yii iba ti ṣe wulo daadaa to, awọn eeyan to n gbọ ọ ko ronu si apa ọdọ rẹ rara, ohun ti ọrọ naa si ṣe jẹ ẹrin fun awọn kan, to jẹ ibinu fawọn mi-in niyẹn. Awọn ti wọn n fi ọrọ naa ṣe ẹrin rin n fi Fani-Kayọde ṣe yẹyẹ ni, awọn ti wọn si n tori rẹ binu n fihan pe awọn koriira ọkunirin naa ni. Ohun ti ko jẹ ki ọrọ naa ta niyẹn. Awọn ti wọn n rẹrin-in n sọ pe o yẹ ẹni gbogbo ko dinwo alagbafọ ni, ko yẹ atọọle, bi ẹnikan yoo ba sọrọ oṣelu ẹlẹyamẹya, ki i ṣe Fani. Ohun tawọn yii ṣe n sọ bẹẹ ni pe nigba ti wọn yoo da ẹgbẹ Dẹmọ ti oun naa wa ninu rẹyii silẹ, ohun ti wọn sọ pe ẹgbẹ naa waa ṣe ni lati ja fun ọmọ Yoruba, wọn ni ẹgbẹ to yẹ ki gbogbo ọmọ Yoruba wa ninu rẹ ni, ki wọn ma si ninu ẹgbẹ mi-in mọ, ẹgbẹ naa ni ojulowo ọmọ Yoruba yoo wa, nitori ẹgbẹ wọn ni.

Awọn eeyan yii waa n sọ pe nigba to jẹ ẹgbẹ ti awọn Fani naa da silẹ, ẹgbẹ ẹlẹyamẹya ni wọn pe e lati ilẹ, wọn ni ẹgbẹ Yoruba ni, bo tilẹ jẹ pe orukọ Naijiria ni wọn sọ ọ, ki waa ni ọkunrin naa yoo maa bu awọn mi-in si, wọn ni isọkusọ lasan lọkunrin naa n sọ. Wọn ni ọrọ to n sọ naa ni lati tubọ fọ ẹgbẹ NCNC, ki oun ati Akintọla da ija gidi silẹ ninu ẹgbẹ naa, ti awọn Yoruba ti wọn wa nibẹ yoo fi kọyin si awọn Ibo, ti awọn Ibo naa yoo kọyin si Yoruba, ti ọrọ yoo si di yanpọn-yanrin, ti ko ni i si ẹni ti yoo gbọ ara wọn ye mọ. Bi eleyii ba si ṣẹlẹ, gbogbo eeyan lo mọ pe inu ẹgbẹ NNDP, Ẹgbẹ Dẹmọ, lawọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ NCNC tẹlẹ yoo rọ lọ, wọn ni ohun ti Fani fẹ ko ṣẹlẹ niyẹn. Ohun to si fa a ti awọn ẹgbẹ NCNC fi sare ṣepade ree, wọn ba awọn ọmọ ẹgbẹ wọn sọrọ, wọn ni ki wọn ma da Fani lohun.

Bẹẹ, “Bo ṣe n ṣe niyẹn” ki i jẹ ka mọ ọjọ iku abiku lọrọ ti Fani sọ. Ootọ wa ninu ọrọ naa, ṣugbọn ọna to gbe e gba ati asiko to sọ ọ lo fi da bii pe kinni naa ko mu eso rere jade. Awọn nnkan kan n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ NCNC to jẹ ko yẹ ko ṣẹlẹ, nitori awọn Ibo kan wa ti wọn n sọ pe ẹgbẹ naa, ẹgbẹ tawọn ni loootọ, ti wọn si n lo iyẹn lati fi ko ipo pataki inu ẹgbẹ naa sọdọ ara wọn. Bi ọrọ ṣe jẹ ni pe ẹgbẹ NCNC ati NPC ni wọn jọ n ṣejọba apapọ, nigba to si jẹ alajọṣe ni wọn bayii, wọn gbọdọ jọ pin awọn ipo bii minisita, ati alaga ileeṣẹ ijọba gbogbo. Wọn pin awọn ipo naa gẹgẹ bii adehun loootọ, ṣugbọn awọn Yoruba inu ẹgbẹ NCNC yii n sọ pe awọn ipo ti wọn n pin fawọn ki i ṣe ipo to tọ sawọn, awọn ipo ti ko sounjẹ nibẹ, ti ko si lagbara gidi kan, ni wọn maa n pin fun Yoruba, tawọn Ibo yoo si mu ipo gidi sọwọ ara wọn.

Bo ba ṣe pe ki ọrọ oṣelu too de ni Fani ti sọ eleyii sita ni, to jẹ ki wọn too da ẹgbẹ Dẹmọ silẹ lo ti kigbe eleyii, to si binu fi ẹgbẹ naa silẹ ati ipo ti wọn fun un, nitori orukọ ẹgbẹ naa lo sa fi wa nile igbimọ, to si jẹ igbakeji Akintọla, gbogbo eeyan ni yoo maa kan saara si i. Ṣugbọn bi nnkan ti le to, ti Fani ri i pe wọn n fiya jẹ awọn Yoruba inu ẹgbẹ naa gẹgẹ bo ti wi, ko fi ipo tirẹ silẹ, bẹẹ ni ko fi ọjọ kan ṣepade ko gbe ọrọ naa kalẹ pe ọrọ awọn eeyan oun loun waa sọ. O di ipo rẹ mu, oun n jẹ gbalamu rẹ lọ, igba ti ọrọ ṣẹṣẹ waa di pe ọwọ oun ati Akintọla wọ ọwọ, ti wọn fẹẹ da ẹgbẹ oṣelu tuntun tiwọn silẹ, igba naa ni Fani-Kayọde ṣẹṣẹ waa mọ pe ohun ti awọn aṣaaju NCNC kan ṣe fun Yoruba ko dara. Iyẹn lawọn eeyan ko ṣe ka ọrọ rẹ si babara kan, nigba to si sọ pe oun koriira oṣelu ẹlẹyamẹya, iyẹn ni wọn ṣe n fi i rẹrin-in gidi.

Ohun to jẹ ki Oloye TOS Benson paapaa jade lati ṣalaye ọrọ naa fawọn Yoruba ti ko ba ye ree. Ṣe TOS Benson yii, ọkan ninu awọn igbakeji aarẹ ẹgbẹ NCNC ni, oun si lo da bii olori pata fun ẹgbẹ naa ni ilẹ Yoruba, bi ko ba si ija ti ko si ita, nitori oun ni oye rẹ ga julọ ninu ẹgbẹ naa lati West. Ohun ti Benson sọ ni pe oun ko si ninu ẹgbẹ Dẹmọ, oun ko si ni i si ninu ẹgbẹ naa laelae. O ni ọmọ ẹgbẹ NCNC loun, oun ko si ni i kuro nibẹ titi tawọn yoo fi yanju iṣoro yoowu ti awọn ba ni. “Nigba ti wọn fẹẹ da ẹgbẹ yii silẹ, wọn ko pe mi si i o, koda, mi o gbọ kinni kan nipa rẹ. Ṣugbọn nigba ti awuyewuye bẹrẹ, ti wọn n gbe e lọtun-un ti wọn n gbe e losi, ti awọn ti ọrọ kan si n sọ pe ki i ṣe bẹẹ, awọn ko da ẹgbẹ kankan silẹ, ohun ti mo sọ nigba naa ni pe emi o ni i fi ẹgbẹ NCNC silẹ o. Ọrọ ti mo sọ nigba naa wa titi doni, NCNC ni mi!”

TOS Benson ni oun faramọ ọn pe ki ẹgbẹ NCNC ati AG jọ maa ṣe aṣepọ, nigba ti ọrọ ti ri bo ti ri yii, ti awọn kan ti lọọ da ẹgbẹ Dẹmọ, silẹ ti wọn si ti yọwọ ẹgbẹ NCNC kuro ninu ijọba West. Benson ni ki i ṣe ootọ pe ọrọ ẹlẹyamẹya tabi ọrọ sẹnsọ lo da ija silẹ ninu ẹgbẹ, o ni ko si ohun to jọ bẹẹ. O ni ohun to fa a ti awọn ti wọn fi ẹgbẹ yii silẹ ṣe lọ ko ju etekete, wiwa agbara oṣelu ni gbogbo ọna, ati agidi ọkan lasan. “Gbogbo ariwo ti wọn n pa yẹn ki i ṣe ootọ, ete ati ọgbọn ẹwẹ ni wọn fi da ẹgbẹ ru. Wọn fẹẹ ni agbara oṣelu ni gbogbo ọna, wọn ko si kọ lati ba ohunkohun jẹ lati ri ohun ti wọn n wa yii. Ni temi, ọdun kẹrindinlogun niyi ti mo ti wa ninu NCNC, nitori mo nigbagbọ ninu eto ati agbekalẹ ẹgbẹ naa ni, ki i ṣe pe ẹnikẹni fi agidi mu mi, mo si wa ninu awọn aṣaaju diẹ ti wọn le fọwọsọya pe wọn ko ja ẹgbẹ naa kulẹ ri.

“Awọn ti ẹ ri ti wọn n pariwo kiri loni-in yii, ti wọn n ni awọn ni igba awọn ni awo, awọn lawọn ni ẹgbẹ tabi pe iya n jẹ awọn ninu ẹgbẹ, ọpọlọpọ wọn lo ti sa kuro ninu ẹgbẹ yii nigba kan, boya wọn lọọ ba wọn da ẹgbẹ silẹ, tabi ko jẹ awọn ni wọn da a silẹ, to jẹ nigba ti ohun gbogbo ba daru fun wọn, wọn yoo tun pada wa sinu NCNC. Iyẹn ko ṣẹlẹ si emi ri, mi o ṣe bẹẹ ri, mi o si ni i waa ṣe bẹẹ lasiko ti a wa yii. Ọmọ NCNC lemi. Ede-aiyede le waye o, bo ba ti n waye naa la maa maa yanju ẹ, nitori ko si inu ẹgbẹ ti iyẹn ki i ti i ṣẹlẹ. Amọ bi iru ẹ ba ti ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ, ninu ẹgbẹ naa leeyan yoo duro si lati yanju ẹ, ki i ṣe pe ki eeyan tori rẹ fi ẹgbẹ silẹ, ko ni awọn lọọ da ẹgbẹ mi-in silẹ, tabi ki wọn mura lati lu ẹgbẹ naa fọ pata. Ṣe inu ẹgbẹ tuntun ti wọn da silẹ tabi ẹgbẹ mi-in ti wọn n lọ, ṣe ede-aiyede ko ni i ṣẹlẹ nibẹ ni!

“Igba ti eeyan ba wa ninu ẹgbẹ kan, afi ti ede-aiyede naa ba ti le debi ti ko ṣee jokoo sọ mọ leeyan too le sọ pe oun yoo kuro nibẹ, boya to ti di pe gbogbo aapọn ti pin lati yanju ọrọ naa laarin awọn aṣaaju ẹgbẹ gbogbo. Amọ ni ti ẹgbẹ wa yii, ọrọ tiwa ko ti i debẹ yẹn, ṣebi awọn aṣaaju ẹgbẹ wa, wọn ṣi n ṣepade, ko si si ohun to de ti wọn ko le sọ laarin ara wọn. Iyẹn lo ṣe jẹ pe gbogbo ariwo pe ẹgbẹ NCNC ti daru, wọn ko gbọ ọrọ sira wọn lẹnu, awọn kan n fiya jẹ awọn kan ati bẹẹ bẹẹ lọ ki i ṣe ootọ, ọrọ oṣelu lasan niyẹn. Loootọ ni ọrọ ẹlẹyamẹya, ọrọ ojuṣaaju, ati awọn iwa to fihan pe awọn kan n jẹ anfaani ẹgbẹ ju awọn mi-in lọ wa ninu ẹgbẹ wa. Nipari ọdun to kọja yii, emi ati awọn aṣaaju kan lati ọdọ wa nibi kọwe lori ọrọ yii, a si sọ pe ki awọn aṣaaju ẹgbẹ jokoo, ki wọn tete wa nnkan ṣe si i.

“Ọrọ eleyii ki i ṣe nnkan tuntun, iru ija bẹẹ le waye, ka jokoo, ka si ba ara wa sọ ọ ni. Iwe ti mo ni a kọ yii, ki ẹgbẹ le jokoo sọ ọrọ naa ni, iwe fun ẹgbẹ wa, ati ọrọ laarin ẹgbẹ wa lasan ni, ki i ṣe fun araata, bẹẹ ni ki i ṣe ohun ti ẹnikẹni le sọ pe oun n tori rẹ fi ẹgbẹ silẹ, nitori lati igba ti iwe naa ti tẹ awọn aṣaaju ẹgbẹ lọwọ la ti jọ n jokoo lati ri i pe gbogbo awọn ohun ti a sọ pe o n dun wa yii ko waye mọ. Gbogbo igba la n sọ ọ, bẹẹ ni ariwo si n lọ rẹpẹtẹ lori iṣọkan Yoruba, pe ki gbogbo awa ti a jẹ aṣaaju Yoruba wa niṣọkan. Ṣugbọn eleyii ṣee ṣe daadaa lai jẹ pe gbogbo wa di ọmọ ẹgbẹ oṣelu kan naa, ṣebi ẹnu ki a mọ pe iṣọkan ati ilọsiwaju Yoruba ni a oo maa wa nibi yoowu ti a ba wa ni, bi ọrọ ba si ti di ibi iṣọkan ati ilọsiwaju adugbo wa, ka gbe ọrọ oṣelu ti sẹgbẹẹ kan. Iyẹn ni mi o ṣe gba pe ẹgbẹ oṣelu kan tabi eeyan kan ṣoṣo ni yoo mu iṣọkan wa silẹ Yoruba.

“Lẹyin lẹyin ni ilẹ Yoruba wa bayii, bi a ba fẹẹ tan ara wa ni a oo sọ pe ki i ṣe bẹẹ. Igbagbọ temi, gẹgẹ bii ọrọ ti mo n sọ bọ tẹlẹ, naa ni pe bi a ba fẹẹ ni idagbasoke nilẹ wa, gbogbo awa oloṣelu ti a wa ninu ẹgbẹ NCNC, awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ AG, ati awọn ti wọn wa ninu ẹgbẹ NNDP tuntun ti wọn ṣẹṣẹ da silẹ, gbogbo wa la gbọdọ jọ mọ pe ojuṣe wa ni lati wa ilọsiwaju agbegbe tiwa. Iyẹn ko di igba ti a ba too di ọmọ ẹgbẹ kan naa, tabi ti a ba too sọ pe ẹgbẹ kan lo dara ju ọkan lọ. Ohun ti ko jẹ ki n maa ba awọn eeyan bu awọn ọrẹ wa kan ti wọn sa kuro ninu ẹgbẹ wa lati lọọ da ẹgbẹ mi-in silẹ niyẹn. Mi o jẹ ba wọn bu wọn nitori oṣelu la n ṣe, o le di ọjọ iwaju ki a nilo ara wa, koda awọn ti wọn sa lọ loni-in tun le sa pada wa sọdọ wa lọla, oṣelu ni gbogbo ẹ, ka ma kan ṣe oṣelu ti a oo fi di ọta ara wa titi aye ni!”

Ọrọ ti TOS Benson sọ daa gan-an ni, ko si sẹni tiko gba a lọgaa, wọn ni agbalagba oloṣelu ni, ati pe agba kan ki i ṣoro bii ewe. Ṣugbọn nigba to fi n sọrọ yii, ina ti jo de ori koko, omi si ti kun kọja afara. Agbara oṣelu to wa lọwọ Akintọla ati Fani-Kayọde ni Western Region ti pọ ju bẹẹ lọ, agbara naa si n pa wọn bii ọti ni. O fẹrẹ jẹ gbogbo eeyan lo ku to n sare lọ sinu ẹgbẹ Dẹmọ, ẹni ti ko ba si lọ, iya ti yoo jẹ ẹ ko ni i ṣee fẹnusọ. Ẹgbẹ NPC, labẹ alaṣẹ Sardauna Ahmadu Bello, ti sọ pe bi ina n jo bi ole n ja, ẹyin Akintọla lawọn yoo wa ni tawọn, nitori ẹni kan ṣoṣo to fẹẹ ṣe bii tawọn lati mu iṣọkan ba Naijiria niyẹn. Ẹgbẹ NPC ni awọn ko ṣetan lati jẹ gaba le awọn ẹya to ku lori, wọn ni ẹni to ba si ni laakaye yoo ri i pe ki i ṣe ohun ti awọn fẹẹ ṣe niyẹn. Wọn ni ohun ti awọn fẹẹ ṣe ni lati wa iṣọkan Naijiria, iyẹn lọrẹẹ awọn ati Akintọla ṣe ba ara wọn mu.

Pẹlu iru awọn atilẹyin nla bayii, nigba to si jẹ ọwọ Sardauna ati ẹgbẹ rẹ ni gbogbo agbara Naijiria wa, ko si ara ti Akintọla ati awọn ti wọn ba n fẹ tirẹ ko le da nilẹ Yoruba ni tiwọn naa. Awọn ọba alaye gbogbo ti mọ eyi, kaluku lo n sare ki Akintọla ku oriire, bẹẹ ni awọn ijọba ibilẹ gbogbo naa mọ, kaluku lo n ko awọn eeyan rẹ wọnu ẹgbẹ Dẹmọ. Awọn ti wọn ba wa n ṣe agidi, ti wọn fa ti wọn ko nírù, oju-ẹsẹ ni wọn n kangi mọ wọn nimu. Ohun to ṣẹlẹ si Kọla Balogun, ọkan ninu awọn aṣaaju NCNC niyẹn. Ọmọ ile igbimọ awọn lọbalọba ni Kọla Balogun, ṣugbọn agbara awọn Akintọla naa lo fi jẹ ọmọ ile igbimọ yii. Bo si ṣe jẹ ni pe Ọba ilu Ọtan Ayegbaju, iyẹn Ọlọtan, lo fi Kọla Balogun joye Jagun ilu Ọtan Ayegbaju. Nitori pe wọn fi i joye yii naa lo ṣe le di ọmọ ile igbimọ awọn lọbalọba.

Ṣugbọn nigba ti wọn fa Kọla Balogun ti ko nírù, ti wọn ni ko waa wọ ẹgbẹ Dẹmọ ti ko tete dahun, kia ni wọn ni ki ẹni to n dele Ọlọtan yọ Balogun kuro nipo Jagun, bi wọn si ti yọ ọ kuro nipo ẹ bayii, bẹẹ ni wọn yọ ọ kuro ninu igbimọ awọn lọbalọba. Ọjọ kan si ikeji ni wọn ṣe gbogbo eleyii, ni wọn ba sọ ọkunrin naa di korofo.

Eleyii ko daa lawọn eeyan n pariwo, afi nigba ti wọn gbọ ohun to ṣẹlẹ si Hubert Ogunde to n ṣere tiata nigba naa, ni kaluku ba sinmi agbaja. Ṣugbọn ọrọ ti Ogunde yii le diẹ, koda o da wahala gidi sọrun Akintọla ati ijọba rẹ. Kekere kọ ni kinni ọhun jare. O dọsẹ to n bọ.

 

 

(90)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.