Afurasi ọmọ ẹgbẹ okunkun marun-un dero ọgba ẹwọn l’Akurẹ

Spread the love

Ile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, l’Akurẹ, ti paṣẹ pe ki wọn ṣi fi awọn afurasi marun-un kan,Tọpẹ Ọlawọle, Abiọla Oseni, Tọpẹ Ọlagundoye, Nasiru Sherif ati Precious Adams, pamọ sọgba ẹwọn lori ẹsun jijẹ ọmọ ẹgbẹ okunkun.

 

Ẹsun akọkọ ti wọn fi kan awọn olujẹjọ naa lasiko ti wọn n farahan niwaju Abilekọ Victoria Bob-Manuel, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, ni lilọwọ ninu ẹgbẹ okunkun ṣiṣe niluu Ọwọ, nijọba ibilẹ Ọwọ, laarin ọdun 2015 si 2019.

 

Awọn afurasi ọhun ni wọn tun fẹsun kan pe wọn ka awọn nnkan ija oloro bii aake, ada atawọn ohun ija oloro mi-in mọ lọwọ lọjọ kejila, oṣu ta a wa yii, eyi to lodi labẹ abala kin-in-ni, ninu iwe ofin ipinlẹ Ondo to tako ẹgbẹ okunkun ṣiṣe.

 

Ọgbẹni John Dada, to jẹ agbefọba ninu ẹbẹ rẹ rọ adajọ lati paṣẹ pe ki awọn fi awọn olujẹjọ naa pamọ sọgba ẹwọn Olokuta, titi asiko ti ile-ẹjọ yoo fi ri imọran gba lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

 

Amofin P.C. Odimegwu to n gbẹnusọ fawọn afurasi ọhun sọ pe oun fara mọ ẹbẹ ti agbefọba fi siwaju ile-ẹjọ.

 

Nigba to n gbe ipinnu rẹ kalẹ, Adajọ Bob-Manuel ni ki awọn maraarun ṣi wa lọgba ẹwọn titi ti imọran yoo fi wa lati ọdọ ajọ to n gba adajọ nimọran.

 

Ọjọ kọkandinlogun, oṣu keji, lo sun igbẹjọ mi-in si.

 

(36)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.