Afi ti owo dọla ti wọn n fọnka soju ọrun yii o

Spread the love

Awọn ti wọn wa ni Pọta royin, wọn ni awọn ti wọn fẹẹ du ipo aarẹ ninu PDP ko mu kinni naa ni kekere, bẹẹ ni wọn ko nawo Naira, owo dọla ni wọn ko wa ti wọn n fọn ọn. Wọn royin pe ko sẹni ti ko fọn kinni naa ninu wọn o, bi Atiku ti n ha a ni Saraki n ha a, bẹẹ ni Tabuwal naa n ha tirẹ, awọn aṣoju to si wa ti ri ọjọ naa bii ọjọ ilabẹ, bi wọn ti n gba a lọtun-un ni wọn n gba a losi, ẹni ti tirẹ ba si pọ ju lo da bii pe awọn eeyan naa mura lati ba lọ. Nnkan meji lo buru nibẹ, akọkọ ni pe awọn eeyan yii gba pe owo Naria tiwa ti bajẹ debii pe ko ṣee fi tọrẹ fawọn eeyan mọ, nitori bi o ba fẹẹ fun ẹnikan ni miliọnu kan bayii, gbẹndu ni apo yoo wu, bẹẹ bi o fun eeyan ni miliọnu kan dọla, pẹlẹbẹ bayii ni, iyẹn yoo si ti maa lọ si ọtalelọọọdunrun miliọnu Naira (N360 million). Ṣugbọn ta lo ba owo Naijiria naa jẹ bayii, ṣebi awọn oloṣelu ti wọn n du u yii naa ni. Ọrọ ṣi n bọ lori iru awọn eeyan yii lọjọ iwaju. Ọna keji to buru nibẹ ni pe ki lo de ti wọn n nawo, ki lo de ti wọn n fi owo ra ibo awọn eeyan, nitori kin ni wọn ṣe n fun wọn lowo nigba ti wọn mọ pe wọn waa dibo ni. Bi ogun ẹni ba da ni loju, a a fi i gbari ni, bi awọn eeyan yii ba da ara wọn loju pe loootọ lawọn gbajumọ, ko si idi lati maa fọn owo bii ẹlẹdaa fawọn to waa dibo ninu ẹgbẹ wọn. Igba ti wọn n ṣe bayii, ti wọn n fọn owo kiri yii, nibo ni wọn ti fẹẹ ri owo naa gba pada, ṣebi wọn yoo kan ji owo araalu ko bi wọn ba debẹ ni. Itumọ eyi ni pe okoowo ni wọn n ṣe, iṣẹ okoowo ni wọn da silẹ, wọn kan fẹẹ maa fi Naijiria pawo ni. Eleyii ko daa, iwa ika lo jẹ, iwa ti Ọlọrun lodi si ni. Ẹnikẹni to ba fẹẹ ṣe eyi, to ba jẹ ohun to mura rẹ wa niyi, Ọlọrun ko ni i gba fun un, gbogbo owo to ba si na, nigbẹyin ko ni i ri ere kankan jẹ, koda, ko jẹ oun ni ẹgbẹ rẹ fa kalẹ lati du ipo aarẹ. Ẹni ti yoo tun ilu ṣe la n wa, ẹni ti yoo yi oju Naijiria pada sibi apọnle, ibi to dara, ti yoo gbe Naijiria dide nibi to ṣubu si, iru ẹni bẹẹ la n wa, ki i ṣe ole ati oniṣowo ti yoo kan maa ko owo wa jẹ. Ki Ọlọrun gba wa lọwọ awọn ole, ẹni ti yoo ba wa ṣe Naijiria daadaa ni ko fun wa.

(13)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.