Afi kẹ ẹ yiwa yin pada, ijọba ọrun ku si dẹdẹ

Spread the love

Boya Buhari lo n ṣe awọn nnkan wọnyi ni, boya awọn ọmọlẹyin rẹ ni, ẹni yoowu to ba n ṣe wọn, afi ki wọn yi iwa wọn pada, ki wọn ṣe eto oṣelu bo ti yẹ ki wọn ṣe e, ki aye le maa fi tiwọn ṣe arikọṣe, ki gbogbo ọmọ Naijiria naa si nigbagbọ ninu ijọba yii bi wọn ba tun wọle pada. Ohun to n lọ lọwọ nilẹ yii ko daa rara, afi bii igba pe aye ologun la wa. Ni bayii, bi ẹnikẹni ba ti sọ pe ijọba Buhari ko dara, tabi to ba ti sọ pe Buhari ko le wọle lẹẹkeji, kia ni awọn digbolugi agbofinro kan yoo ti jade, nigba ti ilẹ yoo ba si fi ṣu, wọn yoo ti wa tọhun kan, wọn yoo rọ ọ sitimọle, tabi ki wọn bẹrẹ si i gbo mọ, wọn yoo ni o hu iwa kan ti ko dara, iwa ti ko ba ofin mu, afi ki awọn jẹ ẹ niya daadaa. Ariwo pe wọn fi aburo Buhari funra rẹ ṣe olori awọn ti wọn yoo ka ibo ti a fẹẹ di yii ni wọn pa lọsẹ to kọja, ṣugbọn titi di asiko yii, ko si ẹni to le ṣe kinni kan si i, INEC si sọ pe awọn ko le yọ ọ kuro, awọn ọmọ Naijiria fẹ o, wọn kọ o, Amina Zakari, aburo Buhari yii ni yoo ṣe alaga awọn ti wọn ba fẹẹ ka ibo naa, awọn o le yọ ọ kuro nibẹ rara. Doyin Okupe to n pariwo lẹyin Atiku Abubakar tẹlẹ, wọn ti ko tiẹ ba a; Bukọla Saraki ni wọn n lepa ẹmi oun kiri, Dino Melaye naa ti ha, bẹẹ lawọn mi-in wa nitimọle nitori pe wọn sọ kinni kan nipa Buhari, ọkan awọn eeyan to le sọrọ ko si balẹ mọ, kaluku lo panumọ, wọn n wo ohun ti yoo ṣẹlẹ laipẹ rara. Ṣugbọn ki i ṣe bi wọn ti n ṣejọba niyi, bayii kọ ni wọn ti n ṣejọba lawọn orilẹ-ede to ba fẹ idagbasoke lọdọ wọn. Eto idibo ki i ṣe ko maa ja si iku ko maa ja si ẹwọn fawọn eeyan, idi ni pe eto kan ṣoṣo ti awọn araalu ni lati fi yan ẹni ti wọn ba fẹ sori aga ijọba ni. Ojuṣe awọn eeyan ni, ẹtọ wọn si ni. Ijọba to ba ṣe daadaa, inu rẹ yoo maa dun pe awọn eeyan yoo tun yan oun ni, ijọba ti ko ba ṣe daadaa nikan ni yoo maa jaya, ti yoo si maa lo awọn ṣọja, awọn oloṣelu ole, awọn ọlọpaa ati awọn agbofinro to ku lati fi dẹruba awọn eeyan, ki wọn le fi tipatipa ṣe tiwọn, tabi ki wọn ma le sọ aburu ti wọn ba ṣe. Iru ẹ lawọn Buhari n ṣe yii, o si daju pe ohun ti yoo lẹyin ni. Bi a ba fẹ ilọsiwaju, afi ka ṣe awọn kinni wọnyi bi awọn orilẹ-ede agbaye to ku ti n ṣe e. Araalu ni yoo funra wọn dibo yan ẹni to ba wu wọn, ki i ṣe ka maa fi ojooro ati eru ṣe ohunkohun, ka waa pada ko ibo ayederu jọ, ka ni awọn eeyan lo dibo fun ni. Iru nnkan bẹẹ ko le bi ọmọ rere, ko si le mu ilọsiwaju wa. Ki Buhari yi iwa rẹ pada, bo ba si jẹ awọn ọmọlẹyin rẹ lo n ṣe awọn were to buru to bayii, ki wọn yi iwa wọn pada, ki wọn ma sọ baba wọn lẹnu, nitori gbogbo aye lo n wo wọn, nigba to ba si ya, awọn naa yoo gbẹsan gbogbo aburu wọn. Bi wọn ṣe n ṣe e kọ leleyii o, ẹ ṣe ayee-re, ki aye le ṣe yin-in-re.

 

(5)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.