Afaimọ ki Shittu ma fori sọ Ajimọbi laya ni tiẹ

Spread the love

Nibi ti ọrọ de duro bayii, afaimọ ni Minisita Adebayọ Shittu ko ni i fori sọ Gomina Isiaka Ajimọbi laya. Arun to n ṣe Fayẹmi naa lo n ṣe oun naa, o kan jẹ iyatọ diẹ wa nibẹ ni. Gbogbo owo ti Shittu n ko jọ, bi yoo ṣe waa fi ṣe gomina ipinlẹ Ọyọ lo n wa, ipo minisita to wa yẹn ko to o, ko si ro pe oun le ri oore kan ṣe fawọn eeyan oun nibẹ. Bẹẹ, ẹgbẹ oṣelu rẹ, APC, naa lo n ṣejọba ni ipinlẹ Ọyọ o, to jẹ ko si si ohun to buru to ba lo anfaani ipo to wa lati fi ran gomina to wa nibẹ lọwọ, ko gba awọn nnkan nla wa si ipinlẹ Ọyọ, ko si jẹ kawọn eeyan mọ pe nigba ti oun n ṣe minisita ni Abuja, awọn ohun bayii loun n ṣe. Ṣugbọn ko ṣe bẹẹ, kaka ki oun ṣe iru iyẹn, niṣe loun naa n huwa bii Yahya Bello to loun yoo ko sina nitori Buhari, ti oun naa n tẹ fila, to n daṣọ Buhari sọrun awọn eeyan, to n sọ pe Buhari nikan loun mọ to le ṣe ijọba Naijiria ko dara, nigba ti ọkunrin naa ko tilẹ ṣe kinni kan gidi lati bii ọdun mẹta to ti de yii. Adebayọ Shittu ti gboju le e pe bi oun ba ti le maa ki oriki Buhari, ti oun n tẹle e lẹyin ṣoo ṣoo ṣoo, oun yoo ṣe gomina Ọyọ dandan. Amọ nibi ti awọn Ajimọbi ti duro de e ko daa, awọn yẹn ti n ṣeto laarin ara wọn pe ẹni kan ṣoṣo lawọn yoo fa kalẹ lati inu APC nibẹ, awọn ko ni i ṣopo maa dibo kiri. Nibi ti wọn ti fẹẹ bẹrẹ eto yii ni pe ibo ijọba ibilẹ to n bọ yii, niṣe lawọn Ajimọbi kọ orukọ awọn ti wọn fẹ jọ, wọn ni ko sẹni ti yoo ba wọn du u. Bi wọn ba ti ṣe eleyii ti wọn mu un jẹ, bi ti gomina naa yoo ṣe lọ ree, wọn le ma dibo kan lati fa ẹni ti yoo ṣe gomina kalẹ, ko jẹ wọn yoo kan ni awọn ti mu ẹni kan ni. Bi wọn ko ba si ti dibo abẹle, o daju pe ko si bi Shittu yoo ṣe dije, ko yaa jokoo si Abuja ko maa rin kiri ni. Iyẹn lo ṣe fa ibinu yọ lori ọrọ ti ko fi bẹẹ kan an, pe orukọ ti awọn Ajimọbi kọ kalẹ fun eto idibo ijọba ibilẹ yii, ko si ohun to jọ bẹẹ o, ki Ajimọbi ma dan an wo, ko ma ṣe katikati bẹẹ, nitori oun ko ni i gba ni toun. Bẹẹ ki i ṣe awọn to fẹẹ dupo alaga kansu ni Shittu n ja fun, ara rẹ ni. Ṣugbọn bawo ni baba ọgọta le pupọ ọdun to ti sọ ara rẹ di ọmọ Buhari yii yoo ṣe ṣe e ti yoo fi wọle, ọna wo ni yoo gba niwaju Ajimọbi, iyẹn lo ṣe jẹ bo ba pade ọkunrin naa ninu ookun, yoo fori sọ maanu gomina naa laya ni, afaimọ ki ọrọ ma si di tuu-faitin, ijaagboro rẹpẹtẹ. Awuusu-bi-Lahi!

 

(708)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.