Adiẹ ba lokun ni Western Region, ara ko rọ okun, ara ko rọ adiẹ

Spread the love

Ni bayii, awọn mọto nla meji ti awọn ọlọpaa kun inu wọn fọfọ ti bẹrẹ si i yi ilu Ijẹbu-Ode ati agbegbe rẹ po. Ṣebi ibẹ ni wọn ti pa Ọmọọba Adepọju Odufunade, to jẹ wọn ṣa a ladaa pa ni. Ibẹ naa ni wọn ti pa Ogunloye Fakunmolu ni Ipara, to jẹ wọn ṣa oun naa ladaa pa ni. Ọrọ iku Odufunade si milẹ titi nitori pe olori ẹgbẹ naa ni gbogbo agbegbe Ijẹbu yii ni. Loootọ lawọn ọlọpaa si ti kede pe awọn ti ri awọn kan mu, ṣugbọn wọn ni awọn ṣi n wa awọn mẹrin mi-in, pe awọn mẹrin yii lo ṣe pataki julọ, bi awọn ba ti ri awọn mẹrẹẹrin, awọn yoo mọ awọn ti wọn pa Ọmọọba yii, awọn yoo si le ṣeto ofin fun wọn, ki wọn le gba seria ohun ti wọn ṣe. Ṣugbọn awọn ko ti i ri awọn mẹrin yii mu, wọn ko si mọ ibi ti wahala mi-in ti tun le ṣẹlẹ, iyẹn ni wọn ṣe fọn ọlọpaa ti wọn n pe ni ‘Flying Squad’ si Ijẹbu-Ode, ti wọn ni ki wọn maa yipo ilu naa, ọmọ to ba si ta felefele, ko parẹ lẹsẹkẹsẹ.

Ṣugbọn apa Ijẹbu lawọn ọlọpaa yii wa, nibi ti wọn ti n gbe mọto kiri nigba ti gudugbẹ mi-in tun ja lagbegbe Ibadan, kia ni wọn ti tun ṣa ẹlomi-in pa. O ti waa da bii pe ọrọ ṣiṣara-ẹni-pa yii ti fẹẹ di kari aye aṣọ-oniṣuga, o kari aye. Eyi to tilẹ ṣẹlẹ ni Ibadan yii ki i ṣe ọrọ to yẹ ko da wahala silẹ pẹẹ, ọrọ laarin awọn araalu ati awọn oniṣẹ-ọna labule Agidi Ọmọ, lọna Iwo ni, n lawọn tọọgi ẹgbẹ oṣelu ba ba wọn da si i, nitori wọn ni awọn kan ni AG awọn kan ni Dẹmọ, wọn ni wọn fẹẹ rẹ awọn ti Dẹmọ jẹ ni, n lọrọ ba di wahala, ki oloju si too ṣẹ ẹ, wọn ti ṣa ẹni ti wọn fura si pe eeyan awọn Dẹmọ ni pa. Raji Adeitan lorukọ rẹ, ko si ju ọmọ ọdun mẹrindinlogoji lọ. Awọn mẹrindinlogun paapaa ni wọn fi ara pa, koda, meji ninu wọn wa lẹsẹ-kan-aye-ẹsẹ-kan-ọrun ni. Ile iwosan Adeọyọ ni wọn rọọṣi wọn lọ, Bọlagoye Amusa ati James Ọṣunbunmi.

Ọrọ o-ṣe-ilẹ ko-ṣe-ilẹ ni wọn ti n fa mọ ara wọn lọwọ tẹlẹ, ti wọn si ti n fi ọgbọn yanju ọrọ naa ki ija awọn oloṣelu too waa fẹ kinni ọhun loju, to fi di pe wọn yọ ada ti wọn si ṣa Raji pa. Iku to ba n pa ojugba ẹni, owe lo n pa fun ni; bi arun warapa ba si da oju oniṣegun dena, ẹni to waa ṣe iṣẹ iṣegun yoo fẹsẹ fẹ ẹ ni. Bi ọrọ ṣe ri fawọn agbaagba oloṣelu Western Region igba naa ree, nitori wọn ko to ẹni ti i gbe awọn mọto dẹndẹ-dẹndẹ ti wọn ti n gun tẹlẹ jade mọ, koda awọn mi-in ki i wọ agbada, aṣọ wuruwuru kan ni wọn yoo wọ jade nile, o di inu ọọfiisi wọn ki wọn too ko si agbada wọn. Wọn ki i fẹ ki awọn eeyan da wọn mọ ni, nitori ọrọ ti di ohun ti awọn tọọgi awọn oloṣelu yii n wo awọn ti wọn ba wọ agbada daadaa, ti wọn ba si ti fura sẹni kan pe oju ẹ jọ eyi ti wọn maa n ri ninu beba iroyin tabi nile-igbimọ aṣofin, tọhun yoo ba iku ojiji pade ṣaa ni.

Bẹẹ ni wọn ko jẹ gbe mọto jade. Awọn mi-in, kẹkẹ ni wọn yoo gun de sẹkiteeria wọn, bẹẹ lawọn mi-in yoo wọ taksi, awọn mi-in yoo si ranṣẹ si ọrẹ wọn kan ko waa gbe wọn tabi ki wọn wọ mọto ero, nnkan ko dẹrun fawọn oloṣelu naa jare. Ijọba Akintọla funra wọn ko si mu kinni naa rọju rara, nitori awọn ọlọpaa lawọn naa n ko da sigboro, ati ẹni to si mọwọ ati ẹni ti ko mọwọ mẹsẹ lawọn n ṣa, wọn yoo si rọ wọn da si atimọle. Bi wọn ti n ko wọn de itimọle ni wọn yoo sare ṣeto ile-ẹjọ fun wọn, nitori niṣe lo da bii pe ijọba ti paṣẹ pe wọn o gbọdọ gba beeli awọn ti wọn ba ti mu, afi ti wọn ba ti dele-ẹjọ. Ko waa si eyi to de ile-ẹjọ ninu awọn eeyan yii, boya o mọ ohun to ṣẹlẹ, tabi ko mọ ohun to ṣẹlẹ, yoo lọ sẹwọn ṣaa ni. Awọn adajọ ati awọn ọlọpaa Western Region ni wọn n ṣe gbogbo eleyii, kinni naa ko si mu ọrọ naa rọ rara.

Ki ọrọ too tilẹ di ti itimọle ojoojumọ ati ti ẹlẹwọn-de yii, awọn ẹgbẹ Dẹmọ ti gbe iwe jade, wọn kọwe sawọn oniroyin, wọn ni ki wọn ba awọn tẹ ẹ jade fun gbogbo aye ri. Wọn kọwe naa bayii pe: “Si gbogboyin m gbẹ Dm, eyi ni lati pariwo fun yin pe ko gbd ba nikni ja, ko gbd ba nikni fa wahala, bo til j pe a ri i bi awnm gbẹ NCNC ati AG e n fin yin niran, ti wn n y yin lnu, ti wn si n f ki ba wn da si awn iwa bii ti digbolugi ti wn n hu kaakiri. Gbogbo aye lo ti m pe gbẹ NCNC ati AG ni wn br iwa wuligansi yii, awn ni wn n haaya awọn tọọgi lati maa e gbogbo aburu yii, nitori wọn ko f ka le eto idibo ni irw-rs ni. Wn fẹẹ maa fa wahala yii titi ti asiko idibo yoo fi de, ki wọn le s pe ko si aaye fun idibo, nitori ilu ko fi ara r, awn ko si le dibo.

“Ki i e iyn nikan ni o, wn tun n ṣe e ki wn le fi druba awn araalu ni. Wn n druba awn araalu, ki awọn yn le sa l, ki wn si ni awn ko ni i kopa ninu idibo kankan, tabi ki wn s fun wn pe afi ti wn ba dibo fun gb awn nikan. Gbogbo ohun ti wn n e yii, wn fẹẹ yi ipinnu awn araalu pada ni, wn fẹẹ yi ohun ti awọn araalu f pada, awn araalu to ti kyin si wn, wn fẹẹ s pe tiwn ni wọn n e. Ohun ti wn e n fi tọọgi druba wn niyn. e yin naa ri i pe laarin j meji pere ni wn tia awn olori Dm meji pa, ugbọn awọn ohun ti a fẹẹ s fun yin ni pe ki ma s pe n gbẹsan lara wn o, ajegbodo ni wn ti wn n wa ni kunra, bi ba ni n gbẹsan lara wn, awn eeyan ko ni i myat laarin yin, wn yoo maa ni awn Dm naa ni tọọgi ni o, bẹẹ awa m pe ko si tọọgi ninu awn ọmọ gbẹ wa. fi awọn AG sil ki wọn maa eranu wn

“Awa gg bii gb Dm, a fẹẹ fkan gbogbo yin ọmọ gbẹ bal ni o, ati gbogboyin araalu lapap, pe awa nigbagb ninu ijọba to wa lori oye bayii, a nigbagb ninu wn gidi. Bakan naa la ni igbagb ninu awn agbofinro Naijiria, ati ti Western Region, a m pe awọn lọpaa yoo e iṣẹ wn bii iṣẹ, a m pe ko le pẹ rara ti wọn yoo fi fopin si iwa ipaayan ati rogbodiyan ti wn da silẹ ni agbegbe IjbuOde ati ni agbegbe mi-in ni West, gbogbo awn wuligansi tigbẹ AG si n lo yii ni wọn yoo mu. Awn agbofinro yoo mu wn, iya to ba si le koko ni yoo j wn, ko ma di pe wn yoo e iru r m, ki araalu le maa rin, ki wn maa yan falala, ki kaluku si le maa gba ibi iṣẹ-aje, ati iṣẹ-ooj r l lai si ni ti yoo da a duro, tabi di i lw, ti ko si ni i bru  pe boya nikan wa nibi kan ti yoo y ada soun. Ki gbogbom gbẹ Dm fkanbal, ko sewu loko.

Ohun to waa ṣẹlẹ ni pe ọjọ ti ẹgbẹ Dẹmọ n gbe lẹta tiwọn jade yii, ọjọ naa gan-an naa lawọn apapọ AG ati NCNC n gbe iwe tiwọn naa jade. Awọn ajọṣepọ ẹgbẹ AG ati NCNC ti wọn wa ni agbegbe Ijẹṣa ni wọn sọ bayii pe: “Si gbogboyin m ẹgbẹ AG ati NCNC, gbogbo iya ti awn gbẹ Dm ti wọn n ṣejba Western Region yii fi n j yin pata ni a n ri o. ugbọn a f ki fikan yin bal, ki ma e ba wn ja tabi gbẹsan lara wn, rin jinna si wn paapaa, ki airi wọn le tu si gbogbo aye lw pe awn ti wn pe ara wn ni Dm ni oniṣẹ-ibi to n fi iya j araalu gbogbo. Awa naa ri i, a ri i bigbẹ Dm e n lo gbogbo agbara to wa lw wn, agbara ijba, lati fi fiya j awọn araalu, ki wn si t ori gbogbo alatako to ba n s ododo ba, ko ma si alatako kan tabi ni naa ti yoo s pe lebe wn o pnmn re. Bẹẹ ohun ti wn ne ko dara, ko si si bi araalu ko e ni i sr, iyn lo n bi wn ninu ti wne n fiya j wn.

“Bi a ko til ri, ti a ko si m, gbogbo iwa ibaj tawn Dm n hu ni agbegbe Ijẹṣa oju wa, a si f ki gbogbom gbẹ m nile, loko, ati nibi gbogbo ni West yii pe awngb Dm ko f daadaa fnikan o, wn ko f daadaa faraalu tabi fun awn m gbẹ alatako yoowu, ni ba ti beere r tabi to ko wọn loju, pipa ni wn fẹẹ pa a, tabi ki wọn ju u swọn lj gbgbr. Bi wn ba si ti ju u swọn bẹẹ tan, wn yoo maa par fawn araale r, ati awọn araalu pe wuligansi, tabi ki wn ti ni apaayan ni. Nigba to si j tọọgi lo ku ti awngbẹ Dm fi n elu bayii, wn ti fi aye awn eeyan gbogbo sinu ewu, bẹẹ ni dukia ati mi nikni ko ni idaabobo kan bayii m, ninu ewu ni kaluku wa kaakiri. Bẹẹ ijọba yii lo ko araalu sinu ewu, wn fẹẹ maa fi tipatipa ejba l, ki wọn si fi tipatipa t ori gbogbo eeyan pata ba, ki nikni ma le ta ko wn nibikibi.

yin naaa ri i pe bi wọn ba mu nikẹni bayii, to ba ti j m gbẹ AG tabi NCNC, wn yoo ni awọn ko le gba beeli r, nitori wn ti ko m gbẹ Dm kun awn ilej yii bamu, Dm lplọpọ awọn adaj yii si n e. yin naaaa m pe bi a e n wi yii, ọmọ ẹgbẹ wa mrin ni wn ṣẹṣẹ ju swn ou mfa, ti wn ni wn fa posita gb Dm ya, bẹẹ ni wn ti kk s awn mẹta mi-in swn ou mejila, ti wn ni wn n ba ara wn ja. Bi eeyan meji ba n ba ara wn ja, ki lo waa kan onlaja lati s ati onija atini to n ba ja swn dun kan, bẹẹ m ile kan naa ni wn, wn mọ pe m gbẹ kan naa ni wn i ṣe. Wn ko ba Dmja, wọn ko dele Dm, awn ti wn n s yii ko si tilba ara wọn ja, wn kan lọọ ko wọn loju titi ti wn n l jẹẹj wn, wn si s fun wọn pe m gb lp ni wn, igba ti wọn si dele-ẹjlati fsun kan wn ni wn too gbe ti onija-de si i.

ugbọn latid tiwa nibi, awa r gbogbo m gb lp ati NCNC, pe ki wọn mọ pegbẹ Dm ko ro daadaa ro wn o, wn kan fẹẹ fa wọn jade ki wọn le maa ju wọn swn ni o, nitori ni wn koe gbd ba wọn ja, wn o si gbd ni awn fẹẹ gbẹsan lara wn. Bo ba ya, lrun yoo gbeja gbogbo wa!”

Bẹẹ ni apapọ Ẹgbẹ Ọlọpẹ ati ẹgbẹ NCNC ni agbegbe Ijẹṣa wi, bii ẹni pe wọn si ti sọ fun ara wọn tẹlẹ ni nigba ti lẹta awọn t’Ekiti naa jade. Ọga ọlọpaa Western Region lawọn tilẹ pe, wọn ni awọn pe e nitori bi ko ba mọ ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii, ki awọn le sọ fun un ni. Awọn ẹgbẹ naa ni ohun ti ọpọlọpọ awọn eeyan n sọ ni pe awọn Dẹmọ lawọn ọlọpaa n ṣiṣẹ fun, iyẹn ni wọn ṣe yiju wọn sẹgbẹẹ kan si gbogbo ohun to n lọ. Wọn ni awọn nigbagbọ pe ọlọpaa ko ṣiṣẹ fun Dẹmọ, iyẹn lawọn ṣe fẹẹ sọ ohun ti wọn yoo ṣe fun wọn. Wọn ni ki kọmiṣanna ọlọpaa West ran awọn ọmọ rẹ jade, ko sọ fun wọn ki wọn wa awọn ọmọ Dẹmọ lọ, ki wọn si mu gbogbo awọn ọmọ Dẹmọ ti wọn n paayan kaakiri yii, nitori awọn ni wọn n lo ada ati kumọ, awọn ni wọn n ko wahala ba araalu nipa iwa wuligansi ti wọn n hu kaakiri. Wọn ni bi ọga ọlọpaa naa ba ti mu wọn, ilu yoo sinmi.

Asiko yii kan naa ni tiṣa kan lati Yunifasiti Ifẹ, Ọmọwe Ọpẹyẹmi Ọla, kọwe si Oloye Samuel Ladoke Akintọla ti i ṣe olori ijọba Western Region. O ni ọmọ Ekiti loun, oun ko si jinna si ile rara, oun si ri ohun to n ṣẹlẹ nibẹ, oun si gbọdọ sọ fun Akintọla pe ohun ti awọn eeyan rẹ n ṣe lagbegbe naa ko dara. Ọpẹyẹmi Ọla ni awọn ọmọ Dẹmọ lo n kọlu awọn eeyan kiri, ti awọn tọọgi wọn si ti gbooro pata, ti ko sẹnikan ti wọn n wo loju, tabi ẹnikan ti wọn tilẹ ni ibẹru fun, wọn n ṣe bo ti wu wọn ni. O ni ohun to waa jẹ ki oun maa kọwe si Akintọla ni pe ti ijọba rẹ ko ba tete wa nnkan ṣe si ọrọ to wa nilẹ yii, ki wọn tete pe awọn ọmọ Ẹgbẹ Dẹmọ lati ba wọn sọrọ ki wọn ṣe mẹdọ, bo ba fi di pe awọn ọmọ ẹgbẹ AG ati NCNC agbegbe naa yiju pada si wọn, tawọn naa ba bẹrẹ si i gbẹsan awọn ohun ti wọn n ṣe fun wọn yii, nnkan yoo le koko gan-an ni o, o si ṣee ṣe ki apa ijọba ma ka a.

Ọkunrin olukọ nla ni Yunifasiti Ifẹ yii ni nibi tọrọ naa le de awọn eeyan adugbo awọn l’Ekiti ko fẹẹ maa rin kiri mọ nitori ibẹru awọn tọọgi Dẹmọ. O ni pabambari waa ni ti awọn ile-ẹjọ ibilẹ ti awọn Dẹmọ ti sọ di tiwọn, to jẹ niṣe ni wọn ko awọn adajọ ibilẹ kan ti wọn jẹ ọmọ Dẹmọ kun ibẹ, ti awọn n dajọ nidaakuda, ti wọn n sọ awọn eeyan sẹwọn, ti wọn si n ko wahala ba awọn mi-in ti wọn ba ti gbe dewaju wọn. Ọpẹyẹmi Ọla ni awọn eeyan ti mọ bayii pe awọn ile-ẹjọ yii ki i ṣe ile-ẹjọ mọ, wọn ti di ileeṣẹ ẹgbẹ oṣelu, nibi ti ẹgbẹ Dẹmọ ti n fiya jẹ awọn ti wọn ba korira. Ọpẹyẹmi Ọla ni ọrọ yii yoo lẹyin, iyẹn loun ṣe n pe Akintọla lati ba a sọrọ.

Gbogbo eleyii ko jẹ ki ọrọ naa rọlẹ rara, niṣe ni kinni naa n ran bii oṣupa,to n fojoojumọ le. Bi wọn ti n ṣaayan pa ni agbegbe Ibadan ni wọn n ṣaayan pa ni agbegbe Ijẹbu, ti wọn si n ṣe bẹẹ lọna Ileṣa, Ondo ati Abẹokuta. Ijọba apapọ labẹ Balewa naa ri i pe ọrọ yii ti di nnkan mi-in, ṣugbọn ko mọ bi yoo ti ṣe e ti ọrọ yoo fi yanju. Ni Balewa funra rẹ ba gbera, o di ọna Nzuka, nitori Azikiwe wa ni isinmi, Nzuka lo si jokoo si to ti n sinmi. Balewa lọọ ri i pe ki wọn le mọ bi wọn yoo ti yanju ọrọ naa, ki wọn le mọ ohun ti wọn yoo ṣe si ọrọ Western Region, nitori arun to n ṣe wọn nibẹ yii, bi awọn ko ba tete ba wọn da si i, o le pada waa koba gbogbo awọn o. Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹjọ, 1964 ni ẹronpileeni Balewa gunlẹ si ilu Enugu, o n gbabẹ kọja lọ si Nzuka. Bi awọn oniroyin ti ri i ni wọn sare si i, ibeere akọkọ ti wọn si bi i naa ni ọrọ wahala to n ṣẹlẹ ni Western Region.

O loun waa ri baba oun ni. Ni wọn ba tun beere pe ani ṣe nitori ọrọ West, nibi ti wọn ti n pa ara wọn lojoojumọ yii lo ṣe wa ni. O ni kawọn eeyan ma ko ọrọ soun lẹnu, ọrọ pọ ju ohun ti wọn n beere yẹn lọ. Wọn tun bi i pe ṣe lara ọrọ to pọ yẹn naa ni ti Western Region wa. Nigba naa loun naa waa wo wọn loju, o ni ki wọn wo oju oun daadaa, gbogbo ọna to ba gba lawọn yoo fun un, oun yoo ri i pe oun fopin si iwa wuligansi nidii oṣelu, oun yoo ri i pe nibi gbogbo ti wuligansi ba wa lawọn ti kọlu wọn ti awọn si pa wọn rẹ, bo jẹ West ni o, bo si jẹ ibikibi ni Naijiria, tọọgi tabi wuligansi kan ko ni i raaye duro, awọn yoo le wọn ẹsẹ wọn ko ni i balẹ ni. Bo ti sọ bẹẹ lo ko si mọto ti yoo gbe e lọ si Nzuka, nile Azikiwe, awọn oniroyin to ba sọrọ si ti foye gbe kinni ọhun, wọn ni ọrọ tọọgi, ka maa ṣara-ẹni-ladaa-pa yii ni Balewa tori ẹ wa, ohun to n ṣẹlẹ nilẹ Yoruba lo tori rẹ wa sọna Enugu.

Bẹẹ ni Balewa lọọ ri Azikiwe. Bẹẹ ni awọn ọlọpaa ati adajọ ti Dẹmọ n lo n rọ awọn eeyan sẹwọn ati sitimọle. Bẹẹ ni adiẹ ba lokun ni West, ara ko rọ okun, ara ko rọ adiẹ.

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.