Adeyẹye kede erongba lati dupo sẹnetọ l’Ekiti

Spread the love

Minisita tẹlẹ fun iṣẹ ode, Ọmọọba Adedayọ Adeyẹye, ti kede erongba rẹ lati lọ sile igbimọ aṣofin agba ilẹ yii labẹ asia All Progressives Congress (APC). Oloṣelu naa lo fẹẹ dupo lọdun to n bọ lati ṣoju ẹkun Guusu Ekiti l’Abuja.

Adeyẹye to darapọ mọ APC lati People’s Democratic Party (PDP), ṣaaju ibo gomina Ekiti to waye loṣu keje, ọdun yii, lo kede erongba rẹ lọsẹ to kọja pẹlu bo ṣe ni gbogbo awọn toun nilo atilẹyin wọn ni wọn fọwọ si igbesẹ naa.

O bẹnu atẹ lu ẹsun ti wọn fi kan Gomina Ayọdele Fayoṣe pe o fẹẹ ra mọto olowo nla, ko si fun ara rẹ ati igbakeji rẹ ni owo ajẹmọnu, o ni ẹni to jẹ owo oṣu mẹjọ ko gbọdọ ṣe bẹẹ.

‘’Mo ti mọ Fayoṣe tẹlẹ bii kẹni-ma-ni ati ọkanjua, ṣugbọn mo nigbagbọ ninu Ọmọwe Kayọde Fayẹmi nitori gbogbo ilu mẹtalelaaadoje to wa nipinlẹ yii ni yoo janfaani rẹ.’’

Lori idi to fi lọ APC, Adeyẹye ni, ‘’ Mo pinnu lati pada si APC nitori ara awọn to da Alliance for Democracy silẹ ni mi. Mo fẹẹ fi da awọn eeyan loju pe ti wọn ba fun mi laaye, ma a wu awọn eeyan mi ni Guusu Ekiti lori.

‘’Mo fẹẹ fi da yin loju pe APC lo maa pada sipo aarẹ lọdun to n bọ, a tun maa gba gbogbo ipo sẹnetọ mẹta, aṣoju-ṣofin mẹfa ati aṣofin ipinlẹ mẹrindinlọgbọn ipinlẹ yii nitori iṣọkan wa laarin wa.’’

O waa dupẹ lọwọ awọn to kuro ninu idije naa fun un bii Ọnarebu Bamidele Faparusi, o ni eyi fi bi wọn ṣe tẹwọ gba oun ni APC han.

 

(14)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.