Adeniji Adele Ọba ilu Eko waja, o dagbere faye lọjọ isinmi

Spread the love

Bi ọba kan ba wa to ni irawọ, to si ni okiki, to si lo ipo agbara gẹgẹ bii Ọba ilu Eko, Musendiku Buraimoh Adeniji Adele ni. Ṣugbọn ọpọ awọn eeyan ki i ranti pe e ni Musendiku, bẹẹ ni awọn eeyan mi-in ko tiẹ mọ pe o n jẹ Buarimoh, Ọba Adeniji Adele ni gbogbo aye mọ ọn si, Elekoo ilu Eko, ọba nla to ṣejọba ilu Eko laarin ọdun 1949 titi di ọdun 1964 to tẹrigbaṣọ. Loootọ ara rẹ ko fi bẹẹ ya, ṣugbọn ni gbogbo asiko tawọn oṣiṣẹ fi n ba ijọba fa wahala, ti ọrọ naa si n di ariwo gee laarin ilu, Adele wa lara awọn agba ti o fẹ ki nnkan bajẹ, ti wọn n wo bi wọn yoo ṣe pari aawọ aarin ijọba atawọn oṣiṣẹ ẹ. Ija yii ni ko jẹ ki awọn ti wọn mọ ọn, ti wọn ko si ri i nigboro tete fura pe aiyaara naa n wọ kabiyesi lara. Afi bo ṣe di lọjọ isinmi o, Sannde kan bayii, lọjọ kejila, oṣu keje, ọdun 1964, tawọn eeyan gbọ pe Ọba Adeniji Adele ti tẹrigbaṣọ.

Yatọ si pe Eko ni olu-ilu Naijiria, nibi ti ohun gbogbo ti n ṣẹlẹ, to jẹ ile ijọba apapọ, to si mu ọba ibẹ jẹ nla, ọkan pataki ninu awọn ilu ilẹ Yoruba l’Eko n ṣe, ọrọ ọba ibẹ si kan awọn Akintọla gbọngbọn, paapaa nitori ọba naa fi sọdọ awọn Awolọwọ tẹlẹ, ojulowo ọmọ Ẹgbẹ Ọmọ Oduduwa ni, tawọn Akintọla si n wa ọna lati fa oju rẹ mọra lẹyin ti wahala ti bẹ ninu ẹgbẹ Ọlọpẹ, iyẹn Action Group. Loootọ awọn Akintọla ko lagbara lori ijọba Eko yii, nitori nigba naa, abẹ ijọba apapọ l’Eko wa, sibẹ, wọn maa n fẹ ko ba wọn da sọrọ to ba le, ati pe ibi yoowu to ba fi si, tabi oloṣelu yoowu to ba ti lẹyin, apọnle awọn araalu yoo wa fun un. Ohun tawọn oloṣelu ṣe n wa a niyi, nigba to si jẹ asiko iṣoro niyi fun ijọba Samuel Ladoke Akintọla, lasiko ti wọn n gbọ ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun ti Awolọwọ pe, ti baba naa si wa lọgba ẹwọn, iku Ọba Adele yii mu awọn oloṣelu naa lara.

Loootọ ija ti de, orin ti dowe. Adele ko fihan pe oun pada lẹyin Awolọwọ, ko si ba awọn Akintọla ṣe ninu ẹgbẹ Dẹmọ, koda, ọkan ninu wọn alatako ẹgbẹ Dẹmọ nilẹ Yoruba ni, nitori o ni oun ko le da Awolọwọ, ati pe oun ko ri ohun ti ko dara ti Awolọwọ ṣe, awọn ti wọn lagbara nile ijọba kan fẹẹ fi iya jẹ ẹ lasan ni. Eyi ko jẹ ki awọn ẹgbẹ NNDP, iyẹn ẹgbẹ Dẹmọ, yii fẹran rẹ, awọn ẹgbẹ Balewa naa ko si fẹ tirẹ rara. Ṣugbọn ko si ohun ti wọn le ṣe fun un, agbara ọba Eko pọ ju bẹẹ lọ. Nitori eyi, awọn Akintọla n wa ọna lati fa oju rẹ mọra ni, wọn fẹẹ wa ọna lati tan an, ki wọn fi gba ohun ti wọn ba fẹẹ gba lọwọ rẹ, ki wọn si ri i pe o sọ daadaa nipa ẹgbẹ awọn. Wọn mọ pe bo ba sọ daadaa nipa ẹgbẹ awọn, nnkan yoo yipada fawọn lagbegbe Eko.

Ati pe niwọn igba to ti jẹ oun ni lanlọọdu ijọba apapọ, ilu ẹ ni awọn Tafawa Balewa, olori ijọba Naijiria, ati awọn ẹmẹwa rẹ ti n ṣejọba wọn, ko si kinni kan tijọba kan yoo ṣe lẹyin Adele, bi wọn ba si gbe eto kan wa ti ko tẹ ọba naa lọrun, yoo ṣoro fawọn naa lati maa ba eto ọhun lọ. Eyi fihan bi agbara Adele ti to nipo ọba. Ohun to si mu un niyi rẹpẹtẹ bayii ni pe asiko ti awọn oloṣelu ko ti i de, ti ijọba wa lọwọ awọn oyinbo, ti wọn ṣẹṣẹ n wo bi wọn yoo ti gbe kinni naa fawọn oloṣelu Naijiria loun ti gbajọba. Lọdun 1949 to jọba yii, awọn oyinbo ni alakooso, ṣugbọn nigba to di ọdun 1951, wọn dibo akọkọ nilẹ yii to jẹ awọn oloṣelu ilẹ wa funra wọn ni wọn du ipo, ninu oṣu kin-in-ni, ọdun 1952, ni wọn si gbajọba, nigba naa lawọn Awolọwọ de, ti awọn Azikiwe naa **si efet osleu** tiwọn. Loju Ọba Musendiku Adeniji Adele yii lo ṣe.

Awọn eto ominira Naijiria ti wọn waa ṣe laarin ọdun 1949 yii titi di 1960 ti Naijiria ri ominira ọhun gba lọwọ awọn oyinbo, ko si eyi to ṣẹyin Adele ninu ẹ, ọba to mọ igba ti ẹẹẹdọgun dogun, to mọ igba ti ẹẹẹdọgbọn dọgbọn ni. Oju ẹ lo ṣe. Ọpọlọpọ ipade loun naa si ba wọn kopa nibẹ, asiko ti awọn oloṣelu si waa ro pe awọn yoo gbadun rẹ julọ, asiko naa ni nnkan ṣe e yii, ti iku mu un lọ lojiji. Bẹẹ nigba naa, ko mọ awọn eeyan lara ki ọba tete maa ku bẹẹ, asiko ti ọba to ba kere ju n ku ni ọmọ ọgọrin ọdun, ọba ti ko ba pẹ bẹẹ to fi ku, wọn yoo ni ọjọ kekere lo lo laye ni. Bo si jẹ nipo ọba ẹwẹ, awọn mi-in n lo ọgbọn ọdun, tawọn mi-in n lo ogoji tabi ju bẹẹ lọ. Oun ṣẹṣẹ jọba ni 1949 ni, o ṣẹṣẹ di ọdun mẹẹẹdogun nipo lọdun 1964, ọmọ aadọrin ọdun (70), si tun ni, ko sẹni ti yoo ro iku ro o rara. Afi bi bata ṣe ja tuẹ, n lọrọ ba dikalẹ, ko sihun tẹnikan ri ṣe si i.

Ọba ọmọwe ni, iriri rẹ si pọ to bẹẹ gẹẹ, afi bii ẹni pe o ti mọ pe oun yoo jọba nijọ kan. Ọmọ Adele Ajosun, ọba to jẹ lẹẹmeji l’Ekoo, to si fi ẹsẹ ẹsin Islaamu rinlẹ nibẹ ni baba rẹ, iyẹn Buraimoh Adeniji Adele. Ọba yii lo bi Musendiku yii ni ọjọ kẹtala, oṣu kọkanla, ọdun 1893. Lati ọmọ ọdun marun-un ni baba rẹ ti fa a fun awọn aafaa, ile-kewu lo n lọ, o si ti wa nile fun bii ọdun mẹfa ko too wọ ileewe Holy Trinity School, Ebute Ero, nibi to ti bẹrẹ iwe alakọọbẹrẹ rẹ, ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni nigba ti yoo si fi jade iwe mẹfa yii, o ti dagba daadaa. O ti di ọmọ ọdun mejidinlogun nigba ti yoo fi wọ ileewe CMS Grammar School, nibi to ti kawe girama jade. Anfaani ti ọjọ-ori rẹ ati ẹkọ to ti ni tẹlẹ mu ba a naa ni pe iwe ti yoo fi ọdun mẹfa ka, ọdun mẹta pere lo fi ka a, o si jade nileewe naa nigba to wa ni ọmọ ogun ọdun.

Beeyan ba kawe girama jade niru asiko yii, bii ẹni to jade yunifasiti ni, ko si ohun to fẹẹ ṣe tabi iṣẹ to fẹẹ ṣe ti kinni naa yoo tun da a duro mọ, nitori ọpọ awọn oyinbo ti wọn n ṣejọba Naijiria nigba naa paapaa ko ka ju iwe mẹwaa yii lọ, iriri lo ku ti wọn n lo fun ohun gbogbo, bẹẹ ni wọn si n dọga lẹnu iṣẹ ọba niyẹn. Ohun to ṣẹlẹ si Musẹndiku Adele naa ree, nitori bo ti jade ni 1913, wọn gba a ṣiṣẹ ọba gẹgẹ bii awọn wọnlẹwọnlẹ, iyẹn awọn sọfiyọ (Surveyor) nigba to ti ni iṣẹ naa loun fẹẹ maa ṣe. Ọdun naa ni wọn si ti gbe e lọ silẹ Ibo, to ṣiṣẹ nibẹ, ti wọn tun gbe e lati ibẹ lọ si ilẹ Hausa, to tun lọọ ba wọn wọnlẹ nibẹ, awọn eeyan si fẹran rẹ nito agbara to fi n ṣiṣẹ yii, nigba to jẹ ọmọ ogun ọdun ni. Iṣẹ yii lo n ṣe lọwọ ti ogun agbaye ẹlẹẹkin-in-ni fi bẹ silẹ, ti ijọba oyinbo si sọ pe awọn n wa awọn ti yoo fa ara wọn kalẹ lati wọ iṣẹ ologun lati Naijiria.

Adele fa ara rẹ kalẹ, o loun yoo ṣe ṣọja, ko si ohun to fi n ṣe ni. Bẹẹ ni Musẹndiku kekere yii wọ iṣẹ ṣọja, wọn si gbe e lọ si Cameroon, wọn ni nibẹ ni yoo ti maa ba wọn jagun, ṣe awọn oyinbo Jamani lo gba ilẹ gbogbo ibẹ nigba naa, awọn lawọn oyinbo agbaye to ku si n ba jagun. Ninu iṣẹ ologun yii, iṣẹ awọn ẹnijinnia ni wọn gbe fun un, awọn ti wọn n tun biriiji ṣe, ti wọn n ṣe biriiji tuntun ati titi tawọn ọlọtẹ ba bajẹ, bo ba si di pe awọn ọta kọju ibọn si wọn, ki awọn naa tete fibọn da wọn lohun, bi ọkunrin ọmọọba yii ti ṣe lati ọdun 1914 titi di ọdun 1916 ree, ọdun meji gbako lo lo ninu iṣẹ awọn jagunjagun. Nigba ti ogun lọ silẹ ni apa Cameroon, o pada si idi iṣẹ rẹ tẹlẹ, iṣẹ sọfiyọ, ṣugbọn wọn ko jẹ ko pẹ nibẹ ti wọn fi gbe e lọ si ẹka eto inawo ijọba awọn oyinbo, ti wọn si fi i ṣe akọwe kekere, Third Class Clerk ni wọn n pe wọn.

Si iyalẹnu oun paapaa, ibi yii ni Adeniji Adele wa fun bii ogun ọdun, ko si si ohun ti ko mọ nipa eto inawo orilẹ-ede Naijiria laarin awọn ọdun yii, nigba to jẹ lojoojumọ lo n lọ si awọn ile-ẹkọ ti wọn ti n kọ ni nimọ nipa eto inawo, to si n kopa ninu awọn idanilẹkọọ gbogbo ti ijọba n ṣe. Assistant Chief Clerk, igbakeji olori awọn akọwe pata ni ipo rẹ lọdun 1937, nibẹ ni wọn si ti gbe e lọ si olu-ileeṣẹ ijọba to n ṣeto inawo, ti wọn si sọ ọ di akọwe-agba nibẹ, Chief Clerk. Iṣẹ rẹ jọ awọn oyinbo yii loju ti wọn fi tun gbe e jade kuro nibẹ, wọn ni ibi ti owo-ori ti n wọle, iyẹn ẹka owo-ori lawọn n gbe e lọ, ni wọn ba tun fi i ṣe ọga nibẹ. Ibi yii lo wa di ọdun 1947, nigba ti wọn fi oye nla kun oye rẹ, ti wọn sọ ọ di Accountant, iyẹn aṣiro owo agba fun ijọba. Nibi lo si wa titi di ọdun 1949, nigba to fẹyinti lẹnu iṣẹ ijọba.

Ki i ṣe pe o deede fẹyinti bẹẹ naa, loootọ o ti lo ju ọdun marundinlogoji lọ lẹnu iṣe ọba, ṣugbọn awọn oyinbo naa ko ti i fẹ ko lọ, iṣe rẹ wu wọn pupọ. Ṣugbọn nigba ti Ọba Falolu waja lọjọ keji, oṣu kẹsan-an, ọdun 1949, ko tun si ẹni to wu ijọba oyinbo ati awọn afọbajẹ Eko lati jẹ ọba wọn ju Musendiku Adeniji Adele lọ. N ni wọn ba pari eto gbogbo, bo si ti fẹyinti ni ọgbọnjọ, oṣu kẹsan-an, 1949, bẹẹ ni wọn fi i jọba lọjọ keji rẹ, iyẹn ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹwaa, ọdun 1949. Bi a ba si fẹẹ sọ ọ ni asọye, ko tun si ẹni ti ọba tọ si lasiko naa to ju ọkunrin yii lọ, iyẹn to ba jẹ ti iṣẹ ti kaluku ti ṣe fun ilu Eko, tabi ipo ti kaluku ti di mu, tabi kikopa ninu ijọba ti kaluku ti ṣe. Nigba naa, ko si meji Musendiku, nitori gbogbo agbara to ni, gbogbo imọ to mọ, gbogbo gbajumọ rẹ lo fi ṣiṣẹ sin Eko lai mọ pe Ọba Falolu yoo ku nigba to ku.

Ọdun 1927, nigba to ṣẹṣẹ le lọmọ ọgbọn ọdun lawọn oyinbo ti fun un ni ẹbun nla gẹgẹ bii onkọwe itan-arosọ to dangajia ju ni West Africa lasiko tirẹ, bẹẹ ni iwe to n kọ naa ko si di iṣẹ rẹ lọwọ rara. Ọmọọba yii wa ninu awọn ti wọn gbe ijọ Ahmadiyyah de ibi to de nilẹ Yoruba loni-in yii, nitori musulumi ododo gbaa ni. Oun ni akọwe agba pata fun ijọ naa ni gbogbo Naijiria ko too jọba rara, oun si ni maneja ileewe ti awọn ijọ naa ni ni ilu Eko gbogbo. Igba to ya ni wọn fi i ṣe igbakeji olori ẹgbẹ naa jakejado Naijiria, to jẹ oun gan-an lo da bii alaṣẹ ẹgbẹ Ahmadiyyah yii, bẹẹ ko ti i jọba ni gbogbo igba naa. Oun lo da ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni Lagos Area silẹ, lati fi ṣeto idagbasoke fawọn ọmọ Eko ni, ẹgbẹ naa lo si jẹ ọkan ninu awọn ti wọn jọ da Ẹgbẹ Ilu silẹ, igbelarugẹ ọmọ Eko naa si ni ẹgbẹ ọhun wa fun.

Aṣoju Eko ni ninu ijọba oyinbo nigba ti Eko wa labẹ Western Region, ki wọn too tun ja a kuro labẹ wọn. Ko si sibi ti wọn ti n sọrọ ofin, paapaa ohun to ba jẹ mọ ti ọrọ Eko ti ko ni i si Musendiku Adeniji Adele nibẹ, eleyii si ti sọ ọ di gbajumọ laarin awọn ọmọ Eko, awọn agbaagba Eko, ati awọn oloye Eko pata. Ohun ti wọn mọ ọn si naa ni pe ọkunrin ti ko ni ohun meji to n fi aye rẹ ṣe ju ilọsiwaju Eko ati ti awọn ọmọ ilu naa lọ ni. Awọn oyinbo naa mọ ọn, bẹẹ si lawọn oṣiṣẹ ọba gbogbo. Nitori eyi ni ko ṣe si ẹnikẹni to n reti pe wahala kan yoo ṣẹlẹ lati fi Musendiku jọba. Ko si si wahala loootọ, nitori awọn afọbajẹ ko mu ẹni meji ju ọmọ Adele yii lọ, bẹẹ ni ko si si ija, paapaa laarin awọn afọbajẹ yii, wọn ni gbogbo awọn lawọn faramọ ọn ki ọkunrin naa di ọba Eko, ṣe aṣesilẹ labọ waa ba.

Amọ bo ti jọba bayii ni wahala de, wahala to de yii lo si tubọ sọ Adele di olokiki nipo ọba. Ọkan pataki ninu awọn ọmọ Ẹgbẹ Oduduwa ni, awọn oloṣelu NCNC igba naa ko si fẹ ko jọba Eko, bo tilẹ jẹ pe oun lawọn oyinbo fẹ. N lo ṣe jẹ nigba to jọba tan, awọn ọmọ Dosunmu dide, wọn ni awọn ko fẹ Musendiku Adeniji Adele laafin awọn. Ibi ti wọn mu ọrọ naa gba gan-an niyi, ẹni ti ko ba si mọ ko le mọ pe ọrọ naa ti wa nilẹ tipẹ, tabi lati mọ ibi ti awọn eeyan to gbe ọrọ yii dide n lọ. Ọtọ lẹni ti awọn ọmọ Dosunmu fẹ ko jọba ni tiwọn, Adeyinka Oyekan, ọkunrin oniṣegun eebo kan ni wọn fẹ, ṣugbọn ko lẹni ninu igbimọ, awọn afọbajẹ ko wo oju rẹ, ko si si ọna to le gba to fi le koju Musendiku Adeniji Adele, iyẹn ni wọn ṣe gba ọna mi-in yọ, wọn ni Adele ko gbọdọ de aafin awọn, nitori aafin awọn ọmọ Dosunmu ni.

Nibi yii ni ija ti bẹrẹ, ija ti ẹnikan ko ri iru rẹ ri ninu eto ọba jijẹ ni ilẹ Yoruba, nitori ọdun mẹwaa gbako ni wọn fi ja ija naa nile-ẹjọ, lati Naijiria titi wọ ilu oyinbo, ija laarin Ọba Adeniji Adele ati Adeyinka Oyekan ni.

 

 

 

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.