Ademọla Lookman le darapọ mọ Super Eagles laipẹ

Spread the love

Agbabọọlu ilẹ England, Ademọla Lookman, lo ṣee ṣe ko bẹrẹ si i gba bọọlu fun ikọ Super Eagles laipẹ.

Ọsẹ to kọja niroyin yii jẹyọ lẹyin ọdun meji tẹni ọdun mọkanlelogun naa ti kọkọ sọ pe oun ko kopa fun Naijiria, iyẹn lasiko ti Gernot Rohr to jẹ kooṣi Eagles lọọ ba a sọrọ.

Lookman lanfaani lati gba bọọlu fun England nitori ibẹ ni wọn bi i si, bẹẹ lo le gba bọọlu Naijiria, nitori ibẹ lawọn obi rẹ ti lọ sọhun-un.

Ti nnkan ba ri bi ajọ ere bọọlu ilẹ yii ṣe fẹ, ọrọ Lookman yoo da bii ti Victor Moses ati Alex Iwobi ti wọn gba bọọlu fun ikọ ọjẹ-wẹwẹ England ki wọn too wa si Eagles.

Lati bii ọdun ọdun 2008 ni Lookman ti n gba bọọlu fun kilọọbu, o si ti ṣe bẹbẹ ni kilọọbu ilẹ England mẹta ko too lọ si RB Leipzig, ilẹ Germany.

O ti gba bọọlu nipele ‘U19’ ati ‘U20’ ilẹ England, ko too wọ ‘U21’ to ti n ṣe bẹbẹ lọwọlọwọ.

(2)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.