Adeleke o si mọ oore ti Ọlọrun ṣe foun ni o

Spread the love

Nigba ti Ọlọrun ba n ṣe oore fun ẹda nigba mi-in, niṣe ni wọn yoo ro pe ibi lo n ṣe. Boya ni Adeleke Ademọla yii mọ oore ti Ọlọrun ṣe foun lori ọrọ ibo Ọṣun to kọja lọ yii. O pẹ ti a ti n sọ ọ nibi yii pe ipinlẹ Ọṣun ti bajẹ, ijọba to n lọ yii ba ọpọ nnkan jẹ, bi ẹni kan ba si debẹ ti ki i baa ṣe ẹni ti awọn funra wọn yan, ẹnu ati ariwo eke pẹlu irọ nla nla ni wọn yoo fi ti iru ijọba bẹẹ ṣubu. Ki i ṣe pe wọn yoo ti ijọba naa ṣubu nikan ni, wọn yoo ba orukọ Adeleke yii jẹ, ati ẹbi rẹ paapaa, debii pe wọn yoo di ọta awọn ara Ọṣun, koda, titi dori awọn ọmọ Ẹdẹ. Ẹni to bimọ ọran ni i pọn ọn, bi eeyan kan ba fori ara rẹ fa jọgọdi, oun naa ni ko gbe e, ki ẹlẹru gbẹru rẹ ni. Bi Oyetọla ba fi ọdun mẹrin ṣejọba Ọṣun, gbogbo ọmọ ibẹ yoo ri i bo ti ṣe ijọba naa si, ati bi iyatọ kan ba ba wọn yatọ si ijọba ti Arẹgbẹ n ṣe. Idunnu ẹni ni yoo jẹ ki nnkan dara nibẹ ki ayipada si ba gbogbo bi nnkan ti ṣe ri yii. Ki awọn oṣiṣẹ ṣiṣẹ ki wọn ri owo oṣu wọn gba, ki awọn iṣẹ oriṣiiriṣii to si wa lapati jẹ titunṣe. Yoo ṣoro fun ẹni ti ko mọ nnkan to n lọ, tabi ibi ti wọn ba kinni naa de rọ lu u, bo ba rọ lu u, yoo jẹka laipẹ rara. Owo ti wọn ya kaakiri nkọ, bawo ni wọn yoo ti ṣe san an, awọn ele to wa lori owo wọnyi nkọ, lọjọ wo ni ele naa yoo jẹ sisan, tabi ti wọn yoo san an tan. Ko si ohun ti wọn ṣe to ṣẹyin Oyetọla ni aye ijọba Arẹgbẹ, yoo si mọ ibi yoo ti gbe e gba. Eyi ti ko ba fẹẹ ye e nibẹ, yoo pe ọga rẹ ko ṣalaye fun un, nigba ti wọn ba si tan ọran naa debi kan, ẹni to ba pada de lẹyin tiwọn yoo le ṣe iṣẹ ti yoo jọ ilu loju. Bi Adeleke ba mọ inu i ro, ọpẹ ni yoo maa da bayii, ko si gbọdọ binu, nitori bi Ọlọrun ba sọ pe dandan ni yoo ṣe gomina ipinlẹ Ọṣun, ọjọ kan n bọ ti yoo pada waa ṣe e, ko si ohun ti ẹda le ṣe si i, afi ti Ọlọrun ko ba kọ ọ mọ ọn lo ku. Ẹni ti wọn ba rẹ jẹ bayii yoo maa binu, ṣugbọn afi ki eeyan ro iwaju ọrọ ko ro ẹyin rẹ, oloṣelu to ba mọ pe daadaa loun n bọ waa ṣe fun ipinlẹ Ọṣun, ti ki i ṣe ko waa ko owo jẹ nikan, yoo ro o lẹẹmeji ko too maa sa koloba koloba pe dandan ni ki oun ṣe gomina Ọṣun lasiko yii, nitori ibi ti wọn ti ba kinni naa de ni. Ọlọrun yoo fun Ọṣun ni ifọkanbalẹ, ohun gbogbo yoo si ṣee ṣe

(89)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.