Adeleke, ṣe bi wọn ti n di gomina naa nu-un?

Spread the love

Kaakiri ipinlẹ Ọṣun bayii ni posita, iwe ti wọn maa n lẹ kaakiri, ti kun, fọto ọkunrin aṣofin onijo-ara nni, Ademọla Adeleke, lo si kun ibẹ fọfọ to n rẹrin-in sawọn eeyan, to si n sọ pe oun fẹẹ di gomina wọn tuntun. Ọkunrin naa ti kọwe si ẹgbẹ rẹ paapaa, ẹgbẹ PDP, o ni ki wọn tete gba ọrọ oun ro, oun ti ṣetan lati di gomina, oun si ti n mura silẹ bayii. Ọjọ diẹ bayii ni ibo ipinlẹ Ọṣun ku, kinni ọhun ko ju bii oṣu mẹfa lọ. Ko si ohun to buru ninu ki eeyan sọ pe oun yoo ṣe gomina, tabi ki ipo naa wu eeyan lati de, amọ ohun to buru ni ki eeyan ma mura silẹ fun ipo kan, ko sa ti mọ pe ipo naa loore, owo ati ọla ninu, ko si ni oun yoo debẹ ṣaa. Ka tilẹ sọ pe wọn ni ki wọn ma ṣeto idibo rara, ki wọn kan ni ki Adeleke maa bọ, ko waa ṣe gomina, eto wo loun ti ṣe tẹlẹ, ki lo mọ nipa ipinlẹ Ọṣun, eto ọrọ-aje ati idagbasoke ibẹ, ati ohun to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ bayii ti yoo fi ṣe gomina naa. Tabi Adeleke yii ro pe orukọ oun lo gbe oun wọle ni, ṣebi nitori iku ẹgbọn rẹ, ati ọna ti awọn Arẹgbẹ gba lati sọ Ṣẹrubawọn di eeyan yẹpẹrẹ lo jẹ ki wọn dibo foun. Wọn si ti dibo fun un, o ti wọ ile igbimọ aṣofin naa to ọjọ diẹ kan bayii. Ṣugbọn yatọ si ijo ajolaagun tawọn eeyan mọ ọn si, ofin wo, tabi eto wo, tabi agbekalẹ wo ni Adeleke yii ti ṣe fun awọn ti wọn dibo fun un, ati ipinlẹ rẹ lapapọ. Tabi ijo nikan leeyan yoo fi ṣejọba ni! Ẹni to ba fẹẹ ṣejọba, to fẹẹ ṣe akoso agbegbe diẹ, ka ma tiẹ ti i sọ odidi ipinlẹ kan, tọhun yoo ti maa mura silẹ lọjọ to ti pẹ, yoo ti mọ gbogbo eto ati awọn ohun ti yoo ṣe bo ba debẹ, oriṣiiriṣii faili ni yoo ti ni nibi to ti n kọ awọn ohun to n ṣẹlẹ ni ipinlẹ tabi agbegbe naa si, bi wọn ba si ji i loju oorun bayii, yoo le ṣe alaye ohun to fẹẹ ṣe fun ipinlẹ wọn. Yatọ si ọrọ atẹnudẹnu tabi gbọyii-sọyii, kin ni Adeleke yii mọ toun yoo ṣe lori ọrọ Ọṣun ati wahala to ba wọn! Ohun to yẹ ki awọn araalu bẹrẹ si i kọ fun awọn oloṣelu yii ree, oloṣelu ti wọn ba ti mọ pe ko ni eto, ko ni imọ, ko ni kinni kan nipa agbegbe wọn, ki wọn tete yọwọ rẹ kuro lawo, ki wọn ma maa lọ sile rẹ lọọ gbowo, ki wọn sọ fun un pe ko ti i ni imọ ati ọgbọn to ti yoo fi ṣejọba. Ṣe ki i ṣe iwọnba owo ti Adeleke gba nile igbimọ aṣofin lo fẹẹ na danu yii? Ẹ jẹ yaa tete ba a sọrọ!

(102)

Leave a Reply

This site uses Akismet to reduce spam. Learn how your comment data is processed.